Joṣ 21:1-26
Joṣ 21:1-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni awọn olori awọn baba awọn ọmọ Lefi sunmọ Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli; Nwọn si wi fun wọn ni Ṣilo ni ilẹ Kenaani pe, OLUWA palaṣẹ lati ọwọ́ Mose wá lati fun wa ni ilu lati ma gbé, ati àgbegbe wọn fun ohun-ọ̀sin wa. Awọn ọmọ Israeli si fi ilu wọnyi pẹlu àgbegbe wọn fun awọn ọmọ Lefi ninu ilẹ-iní wọn, nipa aṣẹ OLUWA. Ipín si yọ fun idile awọn ọmọ Kohati: ati awọn ọmọ Aaroni alufa, ti mbẹ ninu awọn ọmọ Lefi, fi keké gbà ilu mẹtala, lati inu ẹ̀ya Juda, ati lati inu ẹ̀ya Simeoni, ati lati inu ẹ̀ya Benjamini. Awọn ti o kù ninu awọn ọmọ Kohati, fi keké gbà ilu mẹwa lati inu idile ẹ̀ya Efraimu, ati lati inu ẹ̀ya Dani, ati lati inu àbọ ẹ̀ya Manasse. Awọn ọmọ Gerṣoni si fi keké gbà ilu mẹtala, lati inu idile ẹ̀ya Issakari, ati ninu ẹ̀ya Aṣeri, ati lati inu ẹ̀ya Naftali, ati inu àbọ ẹ̀ya Manasse ni Baṣani. Awọn ọmọ Merari gẹgẹ bi idile wọn, ní ilu mejila, lati inu ẹ̀ya Reubeni, ati inu ẹ̀ya Gadi, ati lati inu ẹ̀ya Sebuluni. Awọn ọmọ Israeli fi keké fun awọn ọmọ Lefi ni ilu wọnyi pẹlu àgbegbe wọn, gẹgẹ bi OLUWA ti palaṣẹ lati ọwọ́ Mose wá. Nwọn si fi ilu ti a darukọ wọnyi fun wọn, lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Juda, ati lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni wá: Nwọn si jẹ́ ti awọn ọmọ Aaroni, ni idile awọn ọmọ Kohati, ti mbẹ ninu awọn ọmọ Lefi, nitoriti nwọn ní ipín ikini. Nwọn si fi Kiriati-arba, ti iṣe Hebroni fun wọn, (Arba ni baba Anaki ni ilẹ òke Juda,) pẹlu àgbegbe rẹ̀ yi i kakiri. Ṣugbọn pápa ilu na, ati ileto rẹ̀, ni nwọn fi fun Kalebu ọmọ Jefunne ni ilẹ-iní rẹ̀. Nwọn si fi Hebroni ilu àbo fun apania pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Libna pẹlu àgbegbe rẹ̀, fun awọn ọmọ Aaroni alufa; Ati Jatiri pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Eṣtemoa pẹlu àgbegbe rẹ̀; Ati Holoni pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Debiri pẹlu àgbegbe rẹ̀; Ati Aini pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Jutta pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Beti-ṣemeṣi pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹsan ninu awọn ẹ̀ya meji wọnni. Ati lati inu ẹ̀ya Benjamini, Gibeoni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Geba pẹlu àgbegbe rẹ̀; Anatotu pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Almoni pelu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. Gbogbo ilu awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa, jẹ́ ilu mẹtala pẹlu àgbegbe wọn. Ati idile awọn ọmọ Kohati, awọn ọmọ Lefi, ani awọn ọmọ Kohati ti o kù, nwọn ní ilu ti iṣe ipín ti wọn lati inu ẹ̀ya Efraimu. Nwọn si fi Ṣekemu fun wọn pẹlu àgbegbe rẹ̀, ni ilẹ òke Efraimu, ilu àbo fun apania, ati Geseri pẹlu àgbegbe rẹ̀; Ati Kibsaimu pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Beti-horoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. Ati ninu ẹ̀ya Dani, Elteke pẹlu àgbegbe rẹ̀, Gibbetoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; Aijaloni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Gati-rimmoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. Ati ninu àbọ ẹ̀ya Manasse, Taanaki pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Gati-rimmoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu meji. Gbogbo ilu na jasi mẹwa pẹlu àgbegbe wọn fun idile awọn ọmọ Kohati ti o kù.
Joṣ 21:1-26 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà àwọn olórí ìdílé ninu ẹ̀yà Lefi wá sí ọ̀dọ̀ Eleasari alufaa, ati sí ọ̀dọ̀ Joṣua ọmọ Nuni, ati àwọn olórí ìdílé ní gbogbo ẹ̀yà Israẹli, ní Ṣilo ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sọ fún wọn pé, “OLUWA ti pàṣẹ láti ẹnu Mose pé kí wọ́n fún wa ní ìlú tí a óo máa gbé ati pápá oko fún àwọn ẹran ọ̀sìn wa.” Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA, àwọn ọmọ Israẹli fún àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú ati pápá tí ó yí wọn ká, ninu ilẹ̀ ìní wọn. Ilẹ̀ kinni tí wọ́n kọ́kọ́ ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọmọ Kohati. Nítorí náà, gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ ìran Aaroni alufaa gba ìlú mẹtala lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Juda, ẹ̀yà Simeoni, ati ẹ̀yà Bẹnjamini. Àwọn ọmọ Kohati yòókù sì gba ìlú mẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Efuraimu, ẹ̀yà Dani, ati ìdajì ẹ̀yà Manase. Àwọn ọmọ Geriṣoni gba ìlú mẹtala lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Isakari, ẹ̀yà Aṣeri, ẹ̀yà Nafutali, ati ìdajì ẹ̀yà Manase tí wọ́n wà ní Baṣani. Àwọn ọmọ Merari gba ìlú mejila lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ẹ̀yà Sebuluni. Àwọn ìlú náà ati pápá oko wọn ni àwọn ọmọ Israẹli fún àwọn ọmọ Lefi, lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣẹ́ gègé lé wọn lórí, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ láti ẹnu Mose. Àwọn ẹ̀yà Juda ati ẹ̀yà Simeoni fi àwọn ìlú náà sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Lefi, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Kohati, tíí ṣe ìran Aaroni, nítorí pé àwọn ni gègé kọ́kọ́ mú. Àwọn ni wọ́n fún ní Kiriati Ariba tí wọ́n ń pè ní ìlú Heburoni lónìí, (Ariba yìí ni baba Anaki), ati àwọn pápá ìdaran tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀ ní agbègbè olókè ti Juda. Ṣugbọn àwọn oko tí wọ́n yí ìlú náà ká ati àwọn ìletò rẹ̀ ni wọ́n fi fún Kalebu ọmọ Jefune gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀. Àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, ni wọ́n fún ní ìlú Heburoni, tíí ṣe ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan, pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká rẹ̀, ati ìlú Libina pẹlu àwọn pápá ìdaran tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀. Ati àwọn ìlú wọnyi pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn: Jatiri, Eṣitemoa, Holoni, Debiri; Aini, Juta, ati Beti Ṣemeṣi, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹsan-an ní ààrin ilẹ̀ àwọn ẹ̀yà mejeeji. Láàrin ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini, wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú wọnyi pẹlu pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn: Gibeoni, Geba, Anatoti ati Alimoni, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin. Àwọn ìlú tí wọ́n fún àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, jẹ́ mẹtala pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn. Láti inú ilẹ̀ ẹ̀yà Efuraimu ni wọ́n ti gba ìlú fún àwọn ọmọ Kohati yòókù, tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà Lefi. Àwọn ni wọ́n fún ní ìlú Ṣekemu, tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan, ati àwọn pápá ìdaran rẹ̀ tí ó wà ní agbègbè olókè ti Efuraimu. Wọ́n tún fún wọn ní àwọn ìlú wọnyi, pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn: Geseri, Kibusaimu ati Beti Horoni, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Dani, wọ́n fún wọn ní àwọn ìlú wọnyi pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn: Eliteke, Gibetoni. Aijaloni ati Gati Rimoni, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin. Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase, wọ́n fún wọn ní àwọn ìlú wọnyi pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn: Taanaki, ati Gati Rimoni, wọ́n jẹ́ ìlú meji. Ìlú àwọn ọmọ Kohati yòókù jẹ́ mẹ́wàá pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn.
Joṣ 21:1-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báyìí ni olórí ìdílé àwọn ọmọ Lefi lọ bá Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni àti olórí ẹ̀yà àwọn ìdílé ẹ̀yà Israẹli Ní Ṣilo, ní Kenaani, wọn sọ fún wọn pé, “OLúWA pàṣẹ nípasẹ̀ Mose pé kí wọn fún wa ní ìlú láti máa gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn wa.” Àwọn ọmọ Israẹli sì fún àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú wọ̀nyí, àti ilẹ̀ pápá oko tútù lára ilẹ̀ ìní tiwọn gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ fún Mose. Ìpín kìn-ín-ní wà fún àwọn ọmọ Kohati, ní agbo ilé, agbo ilé. Àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ ọmọ Aaroni àlùfáà ni a pín ìlú mẹ́tàlá fún láti ara ẹ̀yà Juda, Simeoni àti Benjamini. Ìyókù àwọn ọmọ Kohati ni a pín ìlú mẹ́wàá fún láti ara ẹ̀yà Efraimu, Dani àti ìdajì Manase. Àwọn ẹ̀yà Gerṣoni ni a pín ìlú mẹ́tàlá fún láti ara ẹ̀yà Isakari, Aṣeri, Naftali àti ìdajì ẹ̀yà Manase ní Baṣani. Àwọn ọmọ Merari ní agbo ilé, agbo ilé ni wọ́n fún ní ìlú méjìlá láti ara ẹ̀yà Reubeni, Gadi àti Sebuluni. Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli pín ìlú wọ̀nyí àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ láti ẹnu Mose. Láti ara ẹ̀yà Juda àti ẹ̀yà Simeoni ni wọ́n ti pín àwọn ìlú tí a dárúkọ wọ̀nyí, (Ìlú wọ̀nyí ni a fún àwọn ọmọ Aaroni tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú ìdílé Kohati tí í ṣe ọmọ Lefi, nítorí tí ìpín àkọ́kọ́ jẹ́ tiwọn). Wọ́n fún wọn ní Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni), pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù tí ó yí wọn ká, ní ilẹ̀ òkè Juda. (Arba ni baba ńlá Anaki.) Ṣùgbọ́n àwọn oko àti àwọn abúlé ní agbègbè ìlú náà ni wọ́n ti fi fún Kalebu ọmọ Jefunne gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ̀. Ní àfikún wọ́n sì fún àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ní Hebroni (ọ̀kan nínú ìlú ààbò fún àwọn apànìyàn) pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù rẹ̀, Libina, Jattiri, Eṣitemoa, Holoni àti Debiri, Aini, Jutta àti Beti-Ṣemeṣi, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn. Ìlú mẹ́sàn-án láti ara ẹ̀yà méjì wọ̀nyí. Láti ara ẹ̀yà Benjamini ni wọ́n ti fún wọn ní: Gibeoni, Geba, Anatoti àti Almoni, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn, wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin. Gbogbo ìlú àwọn àlùfáà, ìran Aaroni jẹ́ mẹ́tàlá pẹ̀lú ilẹ̀ pápá wọn. Ìyókù ìdílé Kohati tí ó jẹ́ ọmọ Lefi ní a pín ìlú fún láti ara ẹ̀yà Efraimu. Ní ilẹ̀ òkè Efraimu wọ́n fún wọn ní: Ṣekemu (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn) àti Geseri, Kibasaimu àti Beti-Horoni, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú mẹ́rin. Láti ara ẹ̀yà Dani ni wọ́n ti fún wọn ní: Elteke, Gibetoni, Aijaloni àti Gati-Rimoni, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn jẹ́ ìlú mẹ́rin. Láti ara ìdajì ẹ̀yà Manase ni wọ́n ti fún wọn ní: Taanaki àti Gati-Rimoni pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú méjì. Gbogbo ìlú mẹ́wẹ̀ẹ̀wá yìí àti ilẹ̀ pápá wọn ni a fi fún ìyókù ìdílé Kohati.