Joṣ 2:8-11
Joṣ 2:8-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki nwọn ki o tó dubulẹ, o gòke tọ̀ wọn lọ loke àja; O si wi fun awọn ọkunrin na pe, Emi mọ̀ pe OLUWA ti fun nyin ni ilẹ yi, ati pe ẹ̀ru nyin bà ni, ati pe ọkàn gbogbo awọn ara ilẹ yi di omi nitori nyin. Nitoripe awa ti gbọ́ bi OLUWA ti mu omi Okun Pupa gbẹ niwaju nyin, nigbati ẹnyin jade ni Egipti; ati ohun ti ẹnyin ṣe si awọn ọba meji ti awọn Amori, ti mbẹ ni ìha keji Jordani, Sihoni ati Ogu, ti ẹnyin parun tútu. Lọgán bi awa ti gbọ́ nkan wọnyi, àiya wa já, bẹ̃ni kò si sí agbara kan ninu ọkunrin kan mọ́ nitori nyin; nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin, on li Ọlọrun loke ọrun, ati nisalẹ aiye.
Joṣ 2:8-11 Yoruba Bible (YCE)
Kí àwọn amí meji náà tó sùn, Rahabu gun òrùlé lọ bá wọn, ó ní, “Mo mọ̀ pé OLUWA ti fi ilẹ̀ yìí lé e yín lọ́wọ́, jìnnìjìnnì yín ti bò wá, ẹ̀rù yín sì ti ń ba gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí. Nítorí a ti gbọ́ bí OLUWA ti mú kí Òkun Pupa gbẹ níwájú yín nígbà tí ẹ jáde ní Ijipti, a sì ti gbọ́ ohun tí ẹ ṣe sí Sihoni ati Ogu, àwọn ọba ará Amori mejeeji tí wọ́n wà ní òkè odò Jọdani, bí ẹ ṣe pa wọ́n run patapata. Bí a ti gbọ́ ni jìnnìjìnnì ti bò wá, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn sì ti bá gbogbo eniyan nítorí yín, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun ọ̀run ati ayé.
Joṣ 2:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí àwọn ayọ́lẹ̀wò náà tó sùn ní alẹ́, ó gòkè tọ̀ wọ́n lọ lókè àjà. Ó sì sọ fún wọn, “Èmi mọ̀ pé OLúWA ti fún un yín ní ilẹ̀ yìí àti pé ẹ̀rù u yín ti sọ wá di ojo dé ibi pé ìdí gbogbo àwọn tí ó n gbé ilẹ̀ yìí ti di omi nítorí i yín. Àwa ti gbọ́ bí OLúWA ti mú omi Òkun Pupa gbẹ níwájú u yín nígbà tí ẹ̀yin jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, àti ohun tí ẹ̀yin ṣe sí Sihoni àti Ogu, àwọn ọba méjèèjì ti Amori ti ìlà-oòrùn Jordani, tí ẹ̀yin parun pátápátá. Bí a ti gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ọkàn wa pami kò sì sí okun kankan fún wa mọ́ nítorí i yín, nítorí pé OLúWA Ọlọ́run yín ni Ọlọ́run ní òkè ọ̀run àti ní ayé.