Joṣ 2:17-21
Joṣ 2:17-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn ọkunrin na wi fun u pe, Ara wa o dá niti ibura rẹ yi, ti iwọ mu wa bú. Kiyesi i, nigbati awa ba dé inu ilẹ na, iwọ o so okùn owú ododó yi si oju-ferese ti iwọ fi sọ̀ wa kalẹ: iwọ o si mú baba rẹ, ati iya rẹ, ati awọn arakunrin rẹ, ati gbogbo ara ile baba rẹ, wá ile sọdọ rẹ. Yio si ṣe, ẹnikẹni ti o ba jade lati inu ilẹkun ile rẹ lọ si ode, ẹ̀jẹ rẹ̀ yio wà li ori ara rẹ̀, awa o si wà li aijẹbi: ati ẹnikẹni ti o ba wà pẹlu rẹ ni ile, ẹ̀jẹ rẹ̀ yio wà li ori wa, bi ẹnikẹni ba fọwọkàn a. Bi o ba si sọ ọ̀ran wa yi, nigbana ni ara wa o dá niti ibura rẹ ti iwọ mu wa bú yi. O si wipe, Gẹgẹ bi ọ̀rọ nyin, bẹ̃ni ki o ri. O si rán wọn lọ, nwọn si lọ: o si so okùn ododó na si oju-ferese.
Joṣ 2:17-21 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọkunrin náà sọ fún Rahabu pé, “A óo mú ìlérí tí o mú kí á fi ìbúra ṣe fún ọ ṣẹ. Nígbà tí a bá wọ ilẹ̀ yìí, mú okùn pupa yìí, kí o so ó mọ́ ibi fèrèsé tí o ti sọ̀ wá kalẹ̀. Kó baba, ati ìyá rẹ, ati àwọn arakunrin rẹ, ati gbogbo àwọn ará ilé baba rẹ sí inú ilé rẹ. Bí ẹnikẹ́ni bá jáde kúrò ninu ilé rẹ lọ sí ààrin ìlú, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà lórí ara rẹ̀, kò sì ní sí ẹ̀bi lọ́rùn wa. Ṣugbọn bí wọn bá pa ẹnikẹ́ni ninu àwọn tí wọ́n wà ninu ilé pẹlu rẹ, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà lórí wa. Ṣugbọn bí o bá sọ ohun tí a wá ṣe fún ẹnikẹ́ni, ẹ̀bi ìlérí tí a fi ìbúra ṣe yìí kò ní sí lórí wa mọ́.” Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ ti wí gan-an, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí.” Ó ní kí wọ́n máa lọ, wọ́n sì lọ; ó bá so okùn pupa náà mọ́ fèrèsé rẹ̀.
Joṣ 2:17-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn arákùnrin náà sì sọ fún un pé, “Kí ọrùn un wa ba à lè mọ́ kúrò nínú ìbúra tí ìwọ mú wa bú yìí. Nígbà tí àwa bá wọ ilé è rẹ, ìwọ yóò so okùn aláwọ̀ aró yìí sí ojú fèrèsé èyí tí ìwọ fi sọ̀ wá kalẹ̀, kí ìwọ kí ó mú baba rẹ, ìyá rẹ, àwọn arákùnrin in rẹ àti gbogbo ìdílé è rẹ kí wọ́n wá sí inú ilé è rẹ. Bí ẹnikẹ́ni bá jáde sí ìta láti inú ilé è rẹ sí inú ìgboro ìlú, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò sì wà ní orí ara rẹ̀; ẹ̀bi rẹ̀ yóò sì wà lórí i rẹ̀. Fún ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nínú ilé pẹ̀lú rẹ, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní orí i wa bí ẹnikẹ́ni bá fi ọwọ́ kàn án. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá sọ ohun tí àwa ń ṣe, àwa yóò bọ́ nínú ìbúra tí ìwọ mú wa bú.” Ó dáhùn pé, “Ó dára bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí sọ.” Ó sì rán wọn lọ wọ́n sì lọ. Ó sì so okùn òdòdó náà sí ojú fèrèsé.