Joṣ 19:49-51
Joṣ 19:49-51 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si pari pipín ilẹ na fun ilẹ-iní gẹgẹ bi àla rẹ̀; awọn ọmọ Israeli si fi ilẹ-iní kan fun Joṣua ọmọ Nuni lãrin wọn: Gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA, nwọn fun u ni ilu ti o bère, ani Timnati-sera li òke Efraimu: o si kọ ilu na, o si ngbé inu rẹ̀. Wọnyi ni ilẹ-iní ti Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli fi keké pín ni ilẹ-iní ni Ṣilo niwaju OLUWA li ẹnu-ọ̀na agọ ajọ. Bẹ̃ni nwọn pari pipín ilẹ na.
Joṣ 19:49-51 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli pín gbogbo agbègbè tí ó wà ninu ilẹ̀ náà ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tán, wọ́n pín ilẹ̀ fún Joṣua ọmọ Nuni pẹlu. Wọ́n fún un ní ilẹ̀ tí ó bèèrè fún gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA. Ìlú tí ó bèèrè fún ni Timnati Sera ní agbègbè olókè ti Efuraimu, ó tún ìlú náà kọ́, ó sì ń gbé ibẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Eleasari alufaa ati Joṣua ọmọ Nuni ati àwọn àgbààgbà ninu ẹ̀yà àwọn eniyan Israẹli ṣe ṣẹ́ gègé láti pín ilẹ̀ náà ní Ṣilo níwájú OLUWA, ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé; wọ́n sì parí pípín ilẹ̀ náà.
Joṣ 19:49-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí wọ́n ti parí pínpín ilẹ̀ náà ní ìpín ti olúkúlùkù, àwọn ará Israẹli fún Joṣua ọmọ Nuni ní ìní ní àárín wọn Bí OLúWA ti pàṣẹ, wọ́n fún un ni ìlú tí ó béèrè fún—Timnati Serah ní ìlú òkè Efraimu. Ó sì kọ́ ìlú náà, ó sì ń gbé ibẹ̀. Wọ̀nyí ni àwọn ilẹ̀ tí Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni àti àwọn olórí ẹ̀yà agbo ilé Israẹli fi ìbò pín ní Ṣilo ní iwájú OLúWA ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. Báyìí ni wọ́n parí pínpín ilẹ̀ náà.