Joṣ 18:1-3
Joṣ 18:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
GBOGBO ijọ awọn ọmọ Israeli si pejọ ni Ṣilo, nwọn si gbé agọ́ ajọ ró nibẹ̀: a si ṣẹgun ilẹ na niwaju wọn. Ẹ̀ya meje si kù ninu awọn ọmọ Israeli, ti kò ti igbà ilẹ-iní wọn. Joṣua si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin o ti lọra pẹ to lati lọ igbà ilẹ na, ti OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, ti fi fun nyin?
Joṣ 18:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli ti ṣẹgun ilẹ̀ náà, gbogbo wọn péjọ sí Ṣilo, wọ́n sì pa àgọ́ àjọ níbẹ̀. Ó ku ẹ̀yà meje, ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli, tí wọn kò tíì pín ilẹ̀ fún. Joṣua bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ìgbà wo ni ẹ fẹ́ dúró dà kí ẹ tó lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti fun yín.
Joṣ 18:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli péjọ ní Ṣilo, wọ́n si kọ́ àgọ́ ìpàdé ní ibẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ náà sì wà ní abẹ́ àkóso wọn, ṣùgbọ́n ó ku ẹ̀yà méje nínú àwọn ọmọ Israẹli tí kò tí ì gba ogún ìní wọn. Báyìí ni Joṣua sọ fún àwọn ọmọ Israẹli: “Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe dúró pẹ́ tó, kí ẹ tó gba ilẹ̀ ìní tí OLúWA Ọlọ́run àwọn baba yín ti fi fún yín?