Joṣ 18:1-28

Joṣ 18:1-28 Bibeli Mimọ (YBCV)

GBOGBO ijọ awọn ọmọ Israeli si pejọ ni Ṣilo, nwọn si gbé agọ́ ajọ ró nibẹ̀: a si ṣẹgun ilẹ na niwaju wọn. Ẹ̀ya meje si kù ninu awọn ọmọ Israeli, ti kò ti igbà ilẹ-iní wọn. Joṣua si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin o ti lọra pẹ to lati lọ igbà ilẹ na, ti OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, ti fi fun nyin? Ẹ yàn ọkunrin mẹta fun ẹ̀ya kọkan: emi o si rán wọn, nwọn o si dide, nwọn o si là ilẹ na já, nwọn o si ṣe apejuwe rẹ̀ gẹgẹ bi ilẹ-iní wọn; ki nwọn ki o si pada tọ̀ mi wá. Nwọn o si pín i si ọ̀na meje: Juda yio ma gbé ilẹ rẹ̀ ni gusù, ile Josefu yio si ma gbé ilẹ wọn ni ariwa. Ẹnyin o si ṣe apejuwe ilẹ na li ọ̀na meje, ẹnyin o si mú apejuwe tọ̀ mi wá nihin, ki emi ki o le ṣẹ́ keké rẹ̀ fun nyin nihin niwaju OLUWA Ọlọrun wa. Nitoriti awọn ọmọ Lefi kò ní ipín lãrin nyin; nitori iṣẹ-alufa OLUWA ni iní wọn: ati Gadi, ati Reubeni, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, ti gbà ilẹ-iní wọn na ni ìha keji Jordani ni ìha ìla-õrùn, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun wọn. Awọn ọkunrin na si dide, nwọn si lọ: Joṣua si paṣẹ fun awọn ti o lọ ṣe apejuwe ilẹ na, wipe, Ẹ lọ, ki ẹ si rìn ilẹ na já, ki ẹ si ṣe apejuwe rẹ̀, ki ẹ si pada tọ̀ mi wá, ki emi ki o le ṣẹ́ keké fun nyin niwaju OLUWA ni Ṣilo. Awọn ọkunrin na si lọ, nwọn si là ilẹ na já, nwọn si ṣe apejuwe rẹ̀ sinu iwé ni ilu ilu li ọ̀na meje, nwọn si pada tọ̀ Joṣua wá, si ibudó ni Ṣilo. Joṣua si ṣẹ́ keké fun wọn ni Ṣilo niwaju OLUWA: nibẹ̀ ni Joṣua si pín ilẹ na fun awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ipín wọn. Ilẹ ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini yọ jade, gẹgẹ bi idile wọn: àla ipín wọn si yọ si agbedemeji awọn ọmọ Juda ati awọn ọmọ Josefu. Àla wọn ni ìha ariwa si ti Jordani lọ; àla na si gòke lọ si ìha Jeriko ni ìha ariwa, o si là ilẹ òke lọ ni iwọ-õrùn; o si yọ si aginjù Beti-afeni. Àla na si ti ibẹ̀ lọ si Lusi, si ìha Lusi (ti ṣe Beti-eli), ni ìha gusù; àla na si sọkale lọ si Atarotu-adari, lẹba òke ti mbẹ ni gusù Beti-horoni isalẹ. A si fà àla na lọ, o si yi si ìha ìwọ-õrùn lọ si gusù, lati òke ti mbẹ niwaju Beti-horoni ni ìha gusù; o si yọ si Kiriati-baali (ti ṣe Kiriati-jearimu), ilu awọn ọmọ Juda kan: eyi ni apa ìwọ-õrùn. Ati apa gusù ni lati ipẹkun Kiriati-jearimu, àla na si yọ ìwọ-õrùn, o si yọ si isun omi Neftoa: Àla na si sọkalẹ lọ si ipẹkun òke ti mbẹ niwaju afonifoji ọmọ Hinnomu, ti o si mbẹ ni afonifoji Refaimu ni ìha ariwa; o si sọkalẹ lọ si afonifoji Hinnomu, si apa Jebusi ni ìha gusù, o si sọkalẹ lọ si Eni-rogeli; A si fà a lati ariwa lọ, o si yọ si Eni-ṣemeṣi, o si yọ si Gelilotu, ti o kọjusi òke Adummimu; o si sọkalẹ lọ si okuta Bohani ọmọ Reubeni; O si kọja lọ si apa ibi ti o kọjusi Araba ni ìha ariwa, o si sọkalẹ lọ si Araba: Àla na si kọja lọ dé apa Beti-hogla ni ìha ariwa: àla na si yọ ni ìha ariwa si kọ̀rọ Okun Iyọ̀, ni ipẹkun gusù ti Jordani: eyi ni àla gusù. Jordani si ni àla rẹ̀ ni ìha ìla-õrùn. Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Benjamini, li àgbegbe rẹ̀ kakiri, gẹgẹ bi idile wọn. Njẹ ilu ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn, ni Jeriko, ati Beti-hogla, ati Emekikesisi; Ati Beti-araba, ati Semaraimu, ati Beti-eli; Ati Affimu, ati Para, ati Ofra; Ati Kefari-ammoni, ati Ofni, ati Geba; ilu mejila pẹlu ileto wọn: Gibeoni, ati Rama, ati Beerotu; Ati Mispe, ati Kefira, ati Mosa; Ati Rekemu, ati Irpeeli, ati Tarala; Ati Sela, Elefu, ati Jebusi (ti iṣe Jerusalemu), Gibeati, ati Kitiria; ilu mẹrinla pẹlu ileto wọn. Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn.

Joṣ 18:1-28 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli ti ṣẹgun ilẹ̀ náà, gbogbo wọn péjọ sí Ṣilo, wọ́n sì pa àgọ́ àjọ níbẹ̀. Ó ku ẹ̀yà meje, ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli, tí wọn kò tíì pín ilẹ̀ fún. Joṣua bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ìgbà wo ni ẹ fẹ́ dúró dà kí ẹ tó lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti fun yín. Ẹ yan eniyan mẹta mẹta wá láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, n óo sì rán wọn jáde lọ láti rin ilẹ̀ náà jákèjádò, kí wọ́n lè ṣe àkọsílẹ̀ ibi tí wọ́n bá fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwọn, lẹ́yìn náà, kí wọ́n pada wá jíyìn fún mi. Ọ̀nà meje ni wọn yóo pín ilẹ̀ náà sí, àwọn ẹ̀yà Juda kò ní kúrò ní àyè tiwọn ní apá ìhà gúsù, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹ̀yà Josẹfu tí wọ́n wà ní agbègbè tiwọn ní apá ìhà àríwá. Ẹ óo ṣe àkọsílẹ̀ ìpín mejeeje, ẹ óo sì mú un tọ̀ mí wá. N óo ba yín ṣẹ́ gègé lórí wọn níhìn-ín, níwájú OLUWA Ọlọrun wa. Àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní ba yín pín ilẹ̀ nítorí iṣẹ́ alufaa OLUWA ni ìpín tiwọn. Ẹ̀yà Gadi ati ti Reubẹni ati ìdajì ẹ̀yà Manase ti gba ìpín tiwọn tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fún wọn ní apá ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani.” Àwọn ọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn, Joṣua sì kìlọ̀ fún wọn, pé, “Ẹ rin ilẹ̀ náà jákèjádò, kí ẹ sì kọ àpèjúwe rẹ̀ sílẹ̀ wá fún mi. N óo sì ba yín ṣẹ́ gègé níhìn-ín níwájú OLUWA ní Ṣilo.” Àwọn ọkunrin náà bá lọ, wọ́n rin ilẹ̀ náà jákèjádò, wọ́n sì ṣe àkọsílẹ̀ àpèjúwe àwọn ìlú tí wọ́n wà ninu rẹ̀ ní ìsọ̀rí meje sinu ìwé kan, wọ́n pada wá sí ọ̀dọ̀ Joṣua ninu àgọ́ ní Ṣilo. Joṣua bá bá wọn ṣẹ́ gègé ní Ṣilo, níwájú OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ṣe pín ilẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Ó fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní ìpín tirẹ̀. Ìpín ti ẹ̀yà Bẹnjamini gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn wà ní ààrin ilẹ̀ ẹ̀yà Juda ati ti ẹ̀yà Josẹfu. Ní apá ìhà àríwá, ààlà ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ ní etí odò Jọdani, lọ sí ara òkè ní ìhà àríwá Jẹriko. Ó gba ààrin àwọn ìlú tí wọ́n wà ní orí òkè lọ ní apá ìwọ̀ oòrùn, ó sì pin sí aṣálẹ̀ Betafeni. Láti ibẹ̀ ààlà ilẹ̀ náà gba apá ìhà gúsù, ní ọ̀nà Lusi, kọjá lọ sí ara òkè, (Lusi ni wọ́n ń pè ní Bẹtẹli tẹ́lẹ̀) ààlà náà tún yípo lọ sí apá ìsàlẹ̀, sí ọ̀nà Atarotu Adari, sí orí òkè tí ó wà ní apá ìhà gúsù, ni ìsàlẹ̀ Beti Horoni. Ó tún yípo lọ ní apá ìwọ̀ oòrùn, sí apá ìhà gúsù lọ sí ara àwọn òkè tí ó wà ní apá ìhà gúsù tí ó dojú kọ Beti Horoni, ó sì pin sí Kiriati Baali (tí wọ́n tún ń pè ní Kiriati Jearimu), ọ̀kan ninu àwọn ìlú ẹ̀yà Juda. Èyí ni apá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ náà. Ààlà ti apá ìhà gúsù ilẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ ní àtiwọ ìlú Kiriati Jearimu lọ títí dé Efuroni, títí dé odò Nefitoa, kí ó tó yípo lọ sí ìsàlẹ̀, sí ẹsẹ̀ òkè tí ó dojú kọ àfonífojì ọmọ Hinomu, níbi tí àfonífojì Refaimu pin sí ní ìhà àríwá. Ààlà náà la àfonífojì Hinomu kọjá lọ sí apá ìhà gúsù ní etí Jebusi, ó tún lọ sí ìsàlẹ̀ títí dé Enrogeli. Lẹ́yìn náà, ó yípo lọ sí apá àríwá, kí ó tó wa lọ sí Enṣemeṣi títí lọ dé Gelilotu tí ó dojú kọ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Adumimu, lẹ́yìn náà ó wá sí ìsàlẹ̀ ní ibi tí òkúta Bohani ọmọ Reubẹni wà. Ààlà náà kọjá lọ sí apá ìhà àríwá òkè Betaraba; láti ibẹ̀ ó lọ sí Araba. Ó tún lọ sí apá ìhà àríwá òkè Beti Hogila, kí ó tó wá lọ sí apá etí Òkun Iyọ̀, níbi tí ó ti lọ fi orí sọ òpin odò Jọdani, ní ìhà gúsù. Ó jẹ́ ààlà ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini ní apá ìhà gúsù. Odò Jọdani ni ààlà rẹ̀ ní apá ìlà oòrùn. Èyí ni ilẹ̀ tí a pín fún ẹ̀yà Bẹnjamini ní ìdílé-ìdílé, pẹlu àwọn ààlà ilẹ̀ ìdílé kọ̀ọ̀kan. Àwọn ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ náà ni: Jẹriko, Beti Hogila, Emeki Kesisi; Betaraba, Semaraimu, Bẹtẹli; Afimu, Para, Ofira; Kefariamoni, Ofini, ati Geba; gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mejila. Gibeoni, Rama, Beeroti Misipa, Kefira, Mosa; Rekemu, Iripeeli, Tarala; Sela, Haelefi, Jebusi (tí à ń pè ní Jerusalẹmu) Gibea, ati Kiriati Jearimu, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹrinla. Ilẹ̀ náà jẹ́ ìpín ti ẹ̀yà Bẹnjamini, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

Joṣ 18:1-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli péjọ ní Ṣilo, wọ́n si kọ́ àgọ́ ìpàdé ní ibẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ náà sì wà ní abẹ́ àkóso wọn, ṣùgbọ́n ó ku ẹ̀yà méje nínú àwọn ọmọ Israẹli tí kò tí ì gba ogún ìní wọn. Báyìí ni Joṣua sọ fún àwọn ọmọ Israẹli: “Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe dúró pẹ́ tó, kí ẹ tó gba ilẹ̀ ìní tí OLúWA Ọlọ́run àwọn baba yín ti fi fún yín? Ẹ yan àwọn ọkùnrin mẹ́ta nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Èmi yóò rán wọn jáde láti lọ bojú wo ilẹ̀ náà káàkiri, wọn yóò sì ṣe àpèjúwe rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìní ẹni kọ̀ọ̀kan. Nígbà náà ni wọn yóò padà tọ̀ mí wá. Ẹ̀yin yóò sì pín ilẹ̀ náà sí ọ̀nà méje kí Juda dúró sí ilẹ̀ rẹ̀ ni ìhà gúúsù àti ilé Josẹfu ní ilẹ̀ rẹ̀ ní ìhà àríwá. Lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá kọ àpèjúwe ọ̀nà méjèèje ilẹ̀ náà, ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi ní ibí, èmi ó sì ṣẹ́ kèké fún yín ní iwájú OLúWA Ọlọ́run wa. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Lefi kò ní ìpín ní àárín yín, nítorí iṣẹ́ àlùfáà. OLúWA ni ìní wọ́n. Gadi, Reubeni àti ìdajì ẹ̀yà Manase, ti gba ìní wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani. Mose ìránṣẹ́ OLúWA ti fi fún wọn.” Bí àwọn ọkùnrin náà ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn láti fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà, Joṣua pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà káàkiri, kí ẹ sì kọ àpèjúwe rẹ̀. Lẹ́yìn náà kí ẹ padà tọ̀ mí wá, kí èmi kí ò lè ṣẹ́ kèké fún yin ní ibí ní Ṣilo ní iwájú OLúWA.” Báyìí ni àwọn ọkùnrin náà lọ, wọ́n sì la ilẹ̀ náà já. Wọ́n sì kọ àpèjúwe rẹ̀ sí orí ìwé kíká ní ìlú, ní ọ̀nà méje, wọ́n sì padà tọ Joṣua lọ ní ibùdó ní Ṣilo. Joṣua sì ṣẹ́ gègé fún wọn ní Ṣilo ní iwájú OLúWA, Joṣua sì pín ilẹ̀ náà fún àwọn Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn ní ibẹ̀. Ìbò náà sì wá sórí ẹ̀yà Benjamini, ní agbo ilé, agbo ilé. Ilẹ̀ ìpín wọn sì wà láàrín ti ẹ̀yà Juda àti Josẹfu: Ní ìhà àríwá ààlà wọn bẹ̀rẹ̀ ní Jordani, ó kọjá lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Jeriko ní ìhà àríwá, ó sì forí lé ìwọ̀-oòrùn sí ìlú òkè, jáde sí aginjù Beti-Afeni. Láti ibẹ̀ ààlà náà tún kọjá lọ sí ìhà gúúsù ní ọ̀nà Lusi, (èyí ni Beteli) ó sì dé Atarotu-Addari, ní orí òkè tí ó wà ní gúúsù Beti-Horoni Láti òkè tí ó kọjú sí Beti-Horoni ní gúúsù ààlà náà yà sí gúúsù ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, ó sì jáde sí Kiriati-Baali (tí í ṣe Kiriati-Jearimu), ìlú àwọn ènìyàn Juda. Èyí ni ìhà ìwọ̀-oòrùn. Ìhà gúúsù bẹ̀rẹ̀ ní ìpẹ̀kun Kiriati-Jearimu ní ìwọ̀-oòrùn, ààlà náà wà ní ibi ìsun omi Nefitoa. Ààlà náà lọ sí ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè tí ó kọjú sí Àfonífojì Beni-Hinnomu, àríwá Àfonífojì Refaimu O sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Àfonífojì Hinnomu sí apá gúúsù gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ìlú Jebusi, ó sì lọ bẹ́ẹ̀ títí dé En-Rogeli. Nígbà náà ni ó yípo sí ìhà àríwá, ó sì lọ sí Ẹni-Ṣemeṣi, ó tẹ̀síwájú dé Geliloti tí ó kọjú sí òkè Adummimu, ó sì sọ̀kalẹ̀ sí ibi Òkúta Bohani ọmọ Reubeni. Ó tẹ̀síwájú títí dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Beti-Araba, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí aginjù. Nígbà náà ni ó lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Beti-Hogla, ó sì jáde ní àríwá etí bèbè Òkun Iyọ̀, ní ẹnu odò Jordani ní gúúsù. Èyí ni ààlà ti gúúsù. Odò Jordani sí jẹ́ ààlà ní ìhà ìlà-oòrùn. Ìwọ̀nyí ní àwọn ààlà ti ó sààmì sí ìní àwọn ìdílé Benjamini ní gbogbo àwọn àyíká wọn. Ẹ̀yà Benjamini ní agbo ilé, agbo ilé ni àwọn ìlú wọ̀nyí: Jeriko, Beti-Hogla, Emeki-Keṣiṣi, Beti-Araba, Ṣemaraimu, Beteli, Affimu, Para, Ofira Kefari, Ammoni, Ofini àti Geba; àwọn ìlú méjìlá àti ìletò wọn. Gibeoni, Rama, Beeroti, Mispa, Kefira, Mosa, Rekemu, Irpeeli, Tarala, Ṣela, Haelefi, ìlú Jebusi (tí í ṣe Jerusalẹmu), Gibeah àti Kiriati, àwọn ìlú mẹ́rìnlá àti ìletò wọn. Èyí ni ìní Benjamini fún ìdílé rẹ̀.