Joṣ 14:6,9,14
Joṣ 14:6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni awọn ọmọ Juda wá sọdọ Joṣua ni Gilgali: Kalebu ọmọ Jefunne ti Kenissi si wi fun u pe, Iwọ mọ̀ ohun ti OLUWA wi fun Mose enia Ọlọrun nipa temi tirẹ ni Kadeṣi-barnea.
Joṣ 14:9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mose si bura li ọjọ́ na wipe, Nitõtọ ilẹ ti ẹsẹ̀ rẹ ti tẹ̀ nì, ilẹ-iní rẹ ni yio jẹ́, ati ti awọn ọmọ rẹ lailai, nitoriti iwọ tọ̀ OLUWA Ọlọrun mi lẹhin patapata.
Joṣ 14:14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina Hebroni di ilẹ-iní Kalebu ọmọ Jefunne ti Kenissi titi di oni-oloni; nitoriti o tọ̀ OLUWA Ọlọrun Israeli lẹhin patapata.
Joṣ 14:6 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kan àwọn ẹ̀yà Juda wá sí ọ̀dọ̀ Joṣua ní Giligali. Ọkunrin kan ninu wọn tí ń jẹ́ Kalebu, ọmọ Jefune, ará Kenisi bá sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ o mọ ohun tí OLUWA sọ fún Mose eniyan Ọlọrun ní Kadeṣi Banea nípa àwa mejeeji?
JOṢUA 14:9 Yoruba Bible (YCE)
Mose bá búra ní ọjọ́ náà pé, ‘Dájúdájú, gbogbo ibi tí ẹsẹ̀ rẹ ti tẹ̀ ni yóo jẹ́ ìpín fún ọ ati fún àwọn ọmọ rẹ títí lae, nítorí pé o ti fi tọkàntọkàn tẹ̀lé OLUWA Ọlọrun mi.’
JOṢUA 14:14 Yoruba Bible (YCE)
Bẹ́ẹ̀ ni Heburoni di ilẹ̀ ìní Kalebu, ọmọ Jefune, ará Kenisi títí di òní olónìí, nítorí pé ó fi tọkàntọkàn tẹ̀lé OLUWA Ọlọrun Israẹli.
Joṣ 14:6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ọkùnrin Juda wá sí ọ̀dọ̀ Joṣua ní Gilgali. Kalebu ọmọ Jefunne ti Kenissiti wí fún un pé, “Ìwọ rántí ohun tí OLúWA sọ fún Mose ènìyàn Ọlọ́run ní Kadeṣi-Barnea nípa ìwọ àti èmi.