Joṣ 13:1-32
Joṣ 13:1-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
JOṢUA si gbó o si pọ̀ li ọjọ́; OLUWA si wi fun u pe, Iwọ gbó, iwọ si pọ̀ li ọjọ́, ilẹ pipọ̀pipọ si kù lati gbà. Eyi ni ilẹ ti o kù; gbogbo ilẹ awọn Filistini, ati gbogbo Geṣuri; Lati Ṣihori, ti mbẹ niwaju Egipti, ani titi dé àgbegbe Ekroni ni ìha ariwa, ti a kà kún awọn ara Kenaani: awọn ijoye Filistia marun; awọn ara Gasa, ati awọn ara Aṣdodi, awọn ara Aṣkeloni, awọn Gitti, ati awọn ara Ekroni; awọn Affimu pẹlu ni gusù: Gbogbo ilẹ awọn ara Kenaani, ati Meara ti awọn ara Sidoni, dé Afeki, titi dé àgbegbe awọn Amori: Ati ilẹ awọn Gebali, ati gbogbo Lebanoni ni ìha ìla-õrùn, lati Baali-gadi nisalẹ òke Hermoni titi o fi dé atiwọ̀ Hamati: Gbogbo awọn ara ilẹ òke lati Lebanoni titi dé Misrefoti-maimu, ani gbogbo awọn ara Sidoni; awọn li emi o lé jade kuro niwaju awọn ọmọ Israeli: kìki ki iwọ ki o fi keké pín i fun Israeli ni ilẹ-iní, gẹgẹ bi mo ti paṣẹ fun ọ. Njẹ nitorina pín ilẹ yi ni ilẹ-iní fun awọn ẹ̀ya mẹsan, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse. Pẹlu rẹ̀ awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi ti gbà ilẹ-iní wọn, ti Mose fi fun wọn ni ìha keji Jordani ni ìha ìla õrùn, bi Mose iranṣẹ OLUWA ti fi fun wọn; Lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ati ilu ti mbẹ lãrin afonifoji na, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ Medeba titi dé Diboni; Ati gbogbo ilu Sihoni ọba awọn Amori, ti o jọba ni Heṣboni, titi dé àgbegbe awọn ọmọ Ammoni: Ati Gileadi, ati àgbegbe awọn Geṣuri ati awọn Maakati, ati gbogbo òke Hermoni, ati gbogbo Baṣani dé Saleka; Gbogbo ilẹ ọba Ogu ni Baṣani, ti o jọba ni Aṣtarotu ati ni Edrei, ẹniti o kù ninu awọn Refaimu iyokù: nitori awọn wọnyi ni Mose kọlù, ti o si lé jade. Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli kò lé awọn Geṣuri, tabi awọn Maakati jade: ṣugbọn awọn Geṣuri ati awọn Maakati ngbé ãrin awọn ọmọ Israeli titi di oni. Kìki ẹ̀ya Lefi ni on kò fi ilẹ-iní fun; ẹbọ OLUWA, Ọlọrun Israeli, ti a fi iná ṣe ni iní wọn, gẹgẹ bi o ti wi fun wọn. Mose si fi fun ẹ̀ya awọn ọmọ Reubeni, gẹgẹ bi idile wọn. Àla wọn bẹ̀rẹ lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ati ilu ti mbẹ lãrin afonifoji nì, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ ti mbẹ ni ìha Medeba; Heṣboni, ati gbogbo ilu rẹ̀ ti mbẹ ni pẹtẹlẹ̀; Diboni, ati Bamoti-baali, ati Beti-baali-meoni; Ati Jahasa, ati Kedemoti, ati Mefaati; Ati Kiriataimu, ati Sibma, ati Sareti-ṣahari ni òke afonifoji na; Ati Beti-peori, ati orisun Pisga, ati Beti-jeṣimotu; Ati gbogbo ilu pẹtẹlẹ̀ na, ati gbogbo ilẹ-ọba Sihoni ọba awọn Amori, ti o jọba ni Heṣboni, ti Mose kọlù pẹlu awọn ọmọ alade Midiani, Efi, ati Rekemu, ati Suri, ati Huri, ati Reba, awọn ọmọ alade Sihoni, ti ngbé ilẹ na. Ati Balaamu ọmọ Beori, alafọṣẹ, ni awọn ọmọ Israeli fi idà pa pẹlu awọn ti nwọn pa. Ati àla awọn ọmọ Reubeni ni Jordani, ati àgbegbe rẹ̀. Eyi ni ilẹ iní awọn ọmọ Reubeni gẹgẹ bi idile wọn, awọn ilu ati ileto wọn. Mose si fi ilẹ fun ẹ̀ya Gadi, ani fun awọn ọmọ Gadi, gẹgẹ bi idile wọn. Àla wọn bẹ̀rẹ ni Jaseri, ati gbogbo ilu Gileadi, ati àbọ ilẹ awọn ọmọ Ammoni, titi dé Aroeri ti mbẹ niwaju Rabba; Ati lati Heṣboni titi dé Ramatu-mispe, ati Betonimu; ati lati Mahanaimu titi dé àgbegbe Debiri; Ati ni afonifoji, Beti-haramu, ati Beti-nimra, ati Sukkotu, ati Safoni, iyokù ilẹ-ọba Sihoni ọba Heṣboni, Jordani ati àgbegbe rẹ̀, titi dé ìha opín okun Kinnereti ni ìha keji Jordani ni ìha ìla-õrùn. Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Gadi gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọn ati ileto wọn. Mose si fi ilẹ-iní fun àbọ ẹ̀ya Manasse: o si jẹ́ ti àbọ ẹ̀ya awọn ọmọ Manasse gẹgẹ bi idile wọn. Àla wọn si bẹ̀rẹ lati Mahanaimu lọ, gbogbo Baṣani, gbogbo ilẹ-ọba Ogu ọba Baṣani, ati gbogbo ilu Jairi, ti mbẹ ni Baṣani, ọgọta ilu: Ati àbọ Gileadi, ati Aṣtarotu, ati Edrei, ilu ilẹ-ọba Ogu ni Baṣani, jẹ́ ti awọn ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, ani ti àbọ awọn ọmọ Makiri, gẹgẹ bi idile wọn. Wọnyi li awọn ilẹ-iní na ti Mose pín ni iní ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, li apa keji Jordani, lẹba Jeriko ni ìha ìla-õrùn.
Joṣ 13:1-32 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkókò yìí, Joṣua ti di àgbàlagbà, ogbó sì ti dé sí i. OLUWA bá sọ fún un pé, “Ogbó ti dé sí ọ, ṣugbọn ilẹ̀ pupọ ni ó kù láti gbà. Ilẹ̀ tí ó kù nìwọ̀nyí: gbogbo agbègbè àwọn ará Filistia ati ti Geṣuri; láti odò Ṣihori, ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ Ijipti, títí lọ sí apá àríwá ní ààlà Ekironi tí ó jẹ́ ti àwọn ará Kenaani, (Marun-un ni ọba àwọn ará Filistia, àwọn nìwọ̀nyí: ọba Gasa, ti Aṣidodu, ti Aṣikeloni, ti Gati, ati ti Ekironi) ati ilẹ̀ àwọn Afimu ní ìhà gúsù. Lẹ́yìn náà, gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati Meara, tíí ṣe ilẹ̀ àwọn ará Sidoni, títí dé Afeki ní ààlà ilẹ̀ àwọn ará Amori, ati ilẹ̀ àwọn ará Gebali, gbogbo Lẹbanoni ní apá ìlà oòrùn, láti Baaligadi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni títí dé ibodè Hamati. Gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, láti Lẹbanoni, títí dé Misirefoti Maimu, ati gbogbo àwọn ará Sidoni ni n óo lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Ṣugbọn, ẹ pín ilẹ̀ náà láàrin àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, bí mo ti pàṣẹ fun yín. Ẹ pín ilẹ̀ náà fún àwọn ẹ̀yà mẹsan-an yòókù ati ìdajì ẹ̀yà Manase.” Ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase gba ilẹ̀ tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fún wọn, tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani; láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni ati ìlú tí ó wà ní ààrin gbùngbùn àfonífojì náà, ati ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ní Medeba títí dé Diboni; ati gbogbo ìlú Sihoni ọba àwọn ará Amori, tí ó jọba ní Heṣiboni, títí kan ààlà àwọn ará Amoni; ati Gileadi ati agbègbè Geṣuri ti Maakati, ati gbogbo òkè Herimoni ati gbogbo Baṣani títí dé Saleka; gbogbo ilẹ̀ ọba Ogu ti Baṣani, tí ó jọba ní Aṣitarotu ati Edirei. Ogu yìí nìkan ṣoṣo ni ó ṣẹ́kù ninu ìran Refaimu yòókù. Mose ti ṣẹgun gbogbo wọn, ó sì ti lé wọn jáde. Sibẹ àwọn ọmọ Israẹli kò lé àwọn ará Geṣuri ati àwọn ará Maakati jáde; wọ́n ń gbé ààrin àwọn ọmọ Israẹli títí di òní olónìí. Ẹ̀yà Lefi nìkan ni Mose kò pín ilẹ̀ fún, ẹbọ tí àwọn ọmọ Israẹli bá rú sí OLUWA ni ìpín tiwọn. Bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Mose fún àwọn ẹ̀yà Reubẹni ní ilẹ̀, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni, ati ìlú tí ó wà ní ààrin gbùngbùn àfonífojì náà, ati gbogbo ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ní Medeba. Pẹlu Heṣiboni ati àwọn ìlú agbègbè rẹ̀ ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú. Àwọn ìlú bíi Diboni, Bamoti Baali, ati Beti Baalimeoni; Jahasi, Kedemotu, ati Mefaati; Kiriataimu, Sibima, ati Sereti Ṣahari, tí ó wà ní orí òkè àfonífojì náà; Betipeori, gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Pisiga, ati Beti Jeṣimotu; àní, àwọn ìlú tí ó wà ní orí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ati gbogbo ìjọba Sihoni ọba àwọn ará Amori, tí ó jọba ní Heṣiboni, tí Mose ṣẹgun, pẹlu gbogbo àwọn olórí ilẹ̀ Midiani. Àwọn bíi: Efi, Rekemu, Ṣuri, Huru, ati Reba, ọmọ ọba Sihoni, tí ń gbé ilẹ̀ náà. Ọ̀kan ninu àwọn tí àwọn ọmọ Israẹli fi idà pa lójú ogun ni Balaamu, aláfọ̀ṣẹ, ọmọ Beori. Odò Jọdani ni ààlà ilẹ̀ àwọn ẹ̀yà Reubẹni. Àwọn ìlú ńláńlá ati àwọn ìlú kéékèèké tí ó wà ninu ilẹ̀ náà jẹ́ ìpín ẹ̀yà Reubẹni gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Mose fún ẹ̀yà Gadi ní ìpín tiwọn, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ilẹ̀ tiwọn ni Jaseri ati gbogbo ìlú Gileadi, ati ìdajì ilẹ̀ àwọn ará Amoni, títí dé Aroeri tí ó wà ní ìlà oòrùn Raba; láti Heṣiboni, títí dé Ramati Misipe ati Betonimu; ati láti Mahanaimu títí dé agbègbè Debiri; àfonífojì Beti Nimra, Sukotu, ati Safoni, ìyókù ilẹ̀ ìjọba Sihoni, ọba Heṣiboni. Odò Jọdani ni ààlà ilẹ̀ wọn, ní apá ìsàlẹ̀ òkun Kinereti, lọ sí apá ìlà oòrùn, níkọjá odò Jọdani. Àwọn ìlú ńláńlá ati ìlú kéékèèké tí ó wà ninu ilẹ̀ yìí jẹ́ ìpín ẹ̀yà Gadi gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Mose fún ìdajì ẹ̀yà Manase ní ìpín tiwọn gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ilẹ̀ tiwọn bẹ̀rẹ̀ láti Mahanaimu, títí dé gbogbo ilẹ̀ Baṣani, gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo àwọn ìlú Jairi tí ó wà ní Baṣani, gbogbo ìlú wọn jẹ́ ọgọta. Ninu ilẹ̀ wọn ni ìdajì Gileadi wà ati Aṣitarotu ati Edirei, àwọn ìlú ńláńlá ilẹ̀ ìjọba Ogu, ọba Baṣani; Mose pín wọn fún àwọn ìdajì ìdílé Makiri, ọmọ Manase, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Àkọsílẹ̀ bí Mose ṣe pín ilẹ̀ tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní òdìkejì Jọdani ní apá ìlà oòrùn Jẹriko nìyí.
Joṣ 13:1-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Joṣua sì darúgbó tí ọjọ́ orí rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ, OLúWA sọ fún un pé, “Ìwọ ti darúgbó púpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ sì kù lọ́pọ̀lọpọ̀ fún yín láti gbà. “Èyí ni ilẹ̀ tí ó kù: “gbogbo àwọn agbègbè àwọn Filistini, àti ti ara Geṣuri: láti odò Ṣihori ní ìlà-oòrùn Ejibiti sí agbègbè Ekroni ìhà àríwá, gbogbo rẹ̀ ni a kà kún Kenaani (agbègbè ìjòyè Filistini márùn-ún ní Gasa, Aṣdodu, Aṣkeloni, Gitti àti Ekroni; ti àwọn ará Affimu); láti gúúsù; gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, láti Arah ti àwọn ará Sidoni títí ó fi dé Afeki, agbègbè àwọn ará Amori; Àti ilẹ̀ àwọn ará Gebali; àti gbogbo àwọn Lebanoni dé ìlà-oòrùn, láti Baali-Gadi ní ìsàlẹ̀ Òkè Hermoni dé Lebo-Hamati. “Ní ti gbogbo àwọn olùgbé agbègbè òkè, láti Lebanoni sí Misrefoti-Maimu, àní, gbogbo àwọn ará Sidoni, èmi fúnra mi ní yóò lé wọn jáde ní iwájú àwọn ará Israẹli. Kí o ri dájú pé o pín ilẹ̀ yí fún Israẹli ní ilẹ̀ ìní, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi àṣẹ fún ọ, pín ilẹ̀ yìí ní ilẹ̀ ìní fún àwọn ẹ̀yà mẹ́sàn-án àti ìdajì ẹ̀yà Manase.” Àwọn ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó kù, àti àwọn Reubeni àti àwọn Gadi ti gba ilẹ̀ ìní, tí Mose ti fún wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani bí Mose ìránṣẹ́ OLúWA ti fi fún wọn. Ó sì lọ títí láti Aroeri tí ń bẹ létí Àfonífojì Arnoni, àti láti ìlú náà tí ń bẹ ní àárín Àfonífojì náà, àti pẹ̀lú gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Medeba títí dé Diboni. Gbogbo ìlú Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó ṣe àkóso ní Heṣboni, títí dé ààlà àwọn ará Ammoni. Àti Gileadi, ní agbègbè àwọn ènìyàn Geṣuri àti Maakati, gbogbo Òkè Hermoni àti gbogbo Baṣani títí dé Saleka, Ìyẹn, gbogbo ilẹ̀ ọba Ogu ní Baṣani, tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu àti Edrei, ẹni tí ó kù nínú àwọn Refaimu ìyókù. Mose ti ṣẹ́gun wọn, ó sì ti gba ilẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli kò lé àwọn ará Geṣuri àti Maakati jáde, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé ní àárín àwọn ará Israẹli títí di òní yìí. Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Lefi ni kò fi ogún kankan fún, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé ọrẹ àfinásun sí OLúWA Ọlọ́run Israẹli ni ogún tiwọn, gẹ́gẹ́ bí o ti ṣèlérí fún wọn. Èyí ni Mose fi fún ẹ̀yà Reubeni ni agbo ilé sí agbo ilé: Láti agbègbè Aroeri ní etí Arnoni Jọ́ọ́jì àti láti ìlú tí ń bẹ láàrín Jọ́ọ́jì, àti gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọjá Medeba sí Heṣboni àti gbogbo ìlú rẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Diboni, Bamoti Baali, Beti-Baali-Mioni, Jahisa, Kedemoti, Mefaati, Kiriataimu, Sibma, Sereti Ṣahari lórí òkè ní àfonífojì. Beti-Peori, gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Pisga, àti Beti-Jeṣimoti gbogbo ìlú tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti gbogbo agbègbè Sihoni ọba Amori, tí ó ṣe àkóso Heṣboni. Mose sì ti ṣẹ́gun rẹ̀ àti àwọn ọmọ ìjòyè Midiani, Efi, Rekemu, Suri, Huri àti Reba, àwọn ọmọ ọba pawọ́pọ̀ pẹ̀lú Sihoni tí ó gbé ilẹ̀ náà. Ní àfikún àwọn tí a pa ní ogun, àwọn ọmọ Israẹli fi idà pa Balaamu ọmọ Beori alásọtẹ́lẹ̀. Ààlà àwọn ọmọ Reubeni ni etí odò Jordani. Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ ni ilẹ̀ ìní àwọn ọmọ Reubeni ní agbo ilé ní agbo ilé. Èyí ni ohun tí Mose ti fi fún ẹ̀yà Gadi, ní agbo ilé ní agbo ilé: Agbègbè ìlú Jaseri, gbogbo ìlú Gileadi àti ìdajì orílẹ̀-èdè àwọn ọmọ ará Ammoni títí dé Aroeri, ní ẹ̀bá Rabba; àti láti Heṣboni lọ sí Ramati-Mispa àti Betonimu, àti láti Mahanaimu sí agbègbè ìlú Debiri, àti ní Àfonífojì Beti-Haramu, Beti-Nimra, Sukkoti àti Safoni pẹ̀lú ìyókù agbègbè ilẹ̀ Sihoni ọba Heṣboni (ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani, agbègbè rẹ̀ títí dé òpin Òkun Kinnereti). Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ jẹ́ ogún àwọn ọmọ Gadi, ní agbo ilé ní agbo ilé. Èyí ni ohun tí Mose ti fi fún ìdajì ẹ̀yà Manase, èyí ni pé, fún ìdajì ìdílé irú-ọmọ Manase, ní agbo ilé ní agbo ilé: Ilẹ̀ náà fẹ̀ dé Mahanaimu àti gbogbo Baṣani, gbogbo agbègbè ilẹ̀ Ogu ọba Baṣani, èyí tí í ṣe ibùgbé Jairi ní Baṣani, ọgọ́ta ìlú, ìdajì Gileadi, àti Aṣtarotu àti Edrei (àwọn ìlú ọba Ogu ní Baṣani). Èyí ni fún irú àwọn ọmọ Makiri ọmọ Manase fún ààbọ̀ àwọn ọmọ Makiri, ní agbo ilé ní agbo ilé. Èyí ni ogún tí Mose fi fún wọn nígbà tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ìhà kejì Jordani ní ìlà-oòrùn Jeriko.