Joṣ 11:16-23

Joṣ 11:16-23 Yoruba Bible (YCE)

Gbogbo ilẹ̀ náà ni Joṣua gbà: ó gba àwọn agbègbè olókè, àwọn tí wọ́n wà ní Nẹgẹbu, gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ Goṣeni, àwọn ìlú tí ó wà ní ẹsẹ̀ òkè, àwọn tí ó wà ní Araba, ati gbogbo àwọn ìlú tí ó wà lórí àwọn òkè Israẹli ati ẹsẹ̀ òkè rẹ̀. Láti òkè Halaki títí lọ sí Seiri, títí dé Baaligadi ní àfonífojì Lẹbanoni ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni. Ó mú gbogbo àwọn ọba wọn, ó pa wọ́n. Joṣua bá àwọn ọba wọnyi jagun fún ìgbà pípẹ́. Kò sí ìlú tí ó bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia àfi àwọn ará Hifi tí wọn ń gbé ìlú Gibeoni. Gbogbo àwọn yòókù patapata ni wọ́n kó lójú ogun. Nítorí pé, OLUWA fúnra rẹ̀ ni ó mú kí ọkàn wọn le, kí wọ́n sì gbógun ti Israẹli, kí àwọn ọmọ Israẹli lè pa wọ́n run, kí wọ́n má baà ṣàánú wọn, ṣugbọn kí wọ́n pa wọ́n run gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Ní àkókò yìí ni Joṣua pa ìran àwọn Anakimu run patapata ní gbogbo àwọn ìlú tí ó wà lórí òkè, àwọn ìlú bíi: Heburoni, Debiri, Anabu, ati àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí òkè Juda, ati àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí òkè Israẹli, gbogbo wọn patapata ni Joṣua parun, ati gbogbo ìlú wọn. Àwọn ìran Anakimu yìí kò kù sí ibikíbi ninu ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, àfi ní ìlú Gasa, ìlú Gati, ati ìlú Aṣidodu ni àwọn díẹ̀ kù sí. Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ṣe gba gbogbo ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ fún Mose, ó sì pín in fún àwọn ọmọ Israẹli; ní ẹlẹ́yà-mẹ̀yà. Lẹ́yìn náà, wọ́n sinmi ogun jíjà.

Joṣ 11:16-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua gba gbogbo ilẹ̀ náà: ilẹ̀ òkè, gbogbo gúúsù, gbogbo agbègbè Goṣeni, ẹsẹ̀ òkè ti ìwọ̀-oòrùn, aginjù àti àwọn òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Israẹli, láti òkè Halaki títí dé òkè Seiri, sí Baali-Gadi ní Àfonífojì Lebanoni ní ìsàlẹ̀ òkè Hermoni. Ó sì mú gbogbo ọba wọn, ó sì kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n. Joṣua sì bá gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí jagun ní ọjọ́ pípẹ́. Kò sí ìlú kan tí ó bá àwọn ará Israẹli ṣe àdéhùn àlàáfíà, àyàfi àwọn ará Hifi tí wọ́n ń gbé ní Gibeoni, gbogbo wọn ló bá a jagun. Nítorí OLúWA fúnrarẹ̀ ní ó sé ọkàn wọn le, kí wọn kí ó lè bá Israẹli jagun, kí òun lè pa wọ́n run pátápátá, kí wọn má sì ṣe rí ojúrere, ṣùgbọ́n kí ó lè pa wọ́n, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ fún Mose. Ní àkókò náà ni Joṣua lọ tí ó sì run àwọn ará Anaki kúrò ní ilẹ̀ òkè, láti Hebroni, Debiri, àti ní Anabu, àti gbogbo ilẹ̀ Juda, àti kúrò ní gbogbo ilẹ̀ òkè Israẹli. Joṣua sì run gbogbo wọn pátápátá àti ìlú wọn. Kò sí ará Anaki kankan tí ó ṣẹ́kù ní ilẹ̀ Israẹli: bí kò ṣe ní Gasa, Gati àti Aṣdodu. Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua sì gba gbogbo ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ fún Mose, ó sì fi fún Israẹli ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn nípa ẹ̀yà wọn. Ilẹ̀ náà sì sinmi ogun.