Joṣ 10:16-28
Joṣ 10:16-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn awọn ọba marun nì sá, nwọn si fara wọn pamọ́ ni ihò kan ni Makkeda. A si sọ fun Joṣua pe, A ri awọn ọba marun ni ifarapamọ́ ni ihò ni Makkeda. Joṣua si wipe, Ẹ yí okuta nla di ẹnu ihò na, ki ẹ si yàn enia sibẹ̀ lati ṣọ́ wọn: Ṣugbọn ẹnyin, ẹ má ṣe duro, ẹ lepa awọn ọtá nyin, ki ẹ si kọlù wọn lẹhin; ẹ máṣe jẹ ki nwọn ki o wọ̀ ilu wọn lọ: nitoriti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi wọn lé nyin lọwọ. O si ṣe, nigbati Joṣua ati awọn ọmọ Israeli pa wọn ni ipakupa tán, titi a fi run wọn, ti awọn ti o kù ninu wọn wọ̀ inu ilu olodi lọ, Gbogbo enia si pada si ibudó sọdọ Joṣua ni Makkeda li alafia: kò sí ẹni kan ti o yọ ahọn rẹ̀ si awọn ọmọ Israeli. Nigbana ni Joṣua wipe, Ẹ ṣi ẹnu ihò na, ki ẹ si mú awọn ọba mararun na jade kuro ninu ihò tọ̀ mi wá. Nwọn si ṣe bẹ̃, nwọn si mú awọn ọba mararun nì jade lati inu ihò na tọ̀ ọ wá, ọba Jerusalemu, ọba Hebroni, ọba Jarmutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egloni. O si ṣe, nigbati nwọn mú awọn ọba na tọ̀ Joṣua wá, ni Joṣua pè gbogbo awọn ọkunrin Israeli, o si wi fun awọn olori awọn ọmọ-ogun ti o bá a lọ pe, Ẹ sunmọ ihin, ẹ si fi ẹsẹ̀ nyin lé ọrùn awọn ọba wọnyi. Nwọn si sunmọ wọn, nwọn si gbé ẹsẹ̀ wọn lé wọn li ọrùn. Joṣua si wi fun wọn pe, Ẹ má ṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe fòya; ẹ ṣe giri, ki ẹ si mu àiya le: nitoripe bayi li OLUWA yio ṣe si awọn ọtá nyin gbogbo ti ẹnyin mbájà. Lẹhin na ni Joṣua si kọlù wọn, o si pa wọn, o si so wọn rọ̀ lori igi marun: nwọn si sorọ̀ lori igi titi di aṣalẹ. O si ṣe li akokò ìwọ-õrùn, Joṣua paṣẹ, nwọn si sọ̀ wọn kalẹ kuro lori igi, nwọn si gbé wọn sọ sinu ihò na ninu eyiti nwọn ti sapamọ́ si, nwọn si fi okuta nla di ẹnu ihò na, ti o wà titi di oni-oloni. Li ọjọ́ na ni Joṣua kó Makkeda, o si fi oju idà kọlù u, ati ọba rẹ̀; o pa wọn run patapata, ati gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀, kò kù ẹnikan silẹ: o si ṣe si ọba Makkeda gẹgẹ bi o ti ṣe si ọba Jeriko.
Joṣ 10:16-28 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọba maraarun sá, wọ́n sì fi ara pamọ́ sinu ihò tí ó wà ní Makeda. Àwọn kan wá sọ fún Joṣua pé wọ́n ti rí àwọn ọba maraarun ní ibi tí wọ́n fi ara pamọ́ sí ní Makeda. Joṣua dá wọn lóhùn pé, “Ẹ yí òkúta ńláńlá dí ẹnu ihò náà kí ẹ sì fi àwọn eniyan sibẹ, láti máa ṣọ́ wọn. Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ dúró níbẹ̀, ẹ máa lé àwọn ọ̀tá yín lọ, kí ẹ máa pa wọ́n láti ẹ̀yìn. Ẹ má jẹ́ kí wọ́n pada wọnú ìlú wọn, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ti fi wọ́n le yín lọ́wọ́.” Nígbà tí Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli ti pa wọ́n ní ìpakúpa tán, tí wọ́n sì fẹ́rẹ̀ pa gbogbo wọn run, tí àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù sì ti sá wọ àwọn ìlú olódi wọn lọ tán, gbogbo àwọn eniyan pada sọ́dọ̀ Joṣua ní àgọ́ tí ó wà ní Makeda láìsí ewu. Kò sì sí ẹni tí ó sọ ìsọkúsọ sí àwọn ọmọ Israẹli. Lẹ́yìn náà, Joṣua ní, “Ẹ ṣí ẹnu ihò náà, kí ẹ sì kó àwọn ọba maraarun náà wá fún mi.” Wọ́n bá kó wọn jáde, láti inú ihò: ọba Jerusalẹmu, ọba Heburoni, ọba Jarimutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egiloni. Nígbà tí wọ́n kó àwọn ọba náà dé ọ̀dọ̀ Joṣua, ó pe gbogbo àwọn ọkunrin Israẹli jọ, ó sọ fún àwọn ọ̀gágun tí wọ́n bá a lọ sí ojú ogun pé, “Ẹ súnmọ́ mi, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ yín tẹ ọrùn àwọn ọba wọnyi.” Wọ́n bá súnmọ́ Joṣua, wọ́n sì tẹ àwọn ọba náà lọ́rùn mọ́lẹ̀. Joṣua bá sọ fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí àyà yín já. Ẹ múra, kí ẹ sì ṣe ọkàn gírí, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yóo ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀tá yín, tí ẹ̀ ń bá jà.” Lẹ́yìn náà, Joṣua fi idà pa wọ́n, ó so wọ́n kọ́ orí igi marun-un, wọ́n sì wà lórí àwọn igi náà títí di ìrọ̀lẹ́. Nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀, Joṣua pàṣẹ pé kí wọ́n já òkú wọn lulẹ̀ kí wọ́n sì sọ wọ́n sinu ihò tí wọ́n sápamọ́ sí, wọ́n sì yí òkúta ńlá dí ẹnu ihò náà. Ó wà níbẹ̀ títí di òní olónìí. Ní ọjọ́ náà gan-an ni Joṣua gba ìlú Makeda, ó sì fi idà pa àwọn eniyan inú rẹ̀ ati ọba wọn. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ ni ó parun, kò dá ẹnikẹ́ni sí. Bí ó ti ṣe sí ọba Jẹriko náà ló ṣe sí ọba Makeda.
Joṣ 10:16-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní báyìí àwọn ọba Amori márùn-ún ti sálọ, wọ́n sì fi ara pamọ́ nínú ihò àpáta kan ní Makkeda, Nígbà tí wọ́n sọ fún Joṣua pé, a ti rí àwọn ọba márààrún, ti ó fi ara pamọ́ nínú ihò àpáta ní Makkeda, ó sì wí pé, “Ẹ yí òkúta ńlá dí ẹnu ihò àpáta náà, kí ẹ sì yan àwọn ọkùnrin sí ibẹ̀ láti ṣọ́ ọ. Ṣùgbọ́n, ẹ má ṣe dúró! Ẹ lépa àwọn ọ̀tá yín, ẹ kọlù wọ́n láti ẹ̀yìn, kí ẹ má ṣe jẹ́ kí wọn kí ó dé ìlú wọn, nítorí tí OLúWA Ọlọ́run yín tí fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua àti àwọn ọmọ Israẹli pa wọ́n ní ìpakúpa wọ́n sì pa gbogbo ọmọ-ogun àwọn ọba márààrún run, àyàfi àwọn díẹ̀ tí wọ́n tiraka láti dé ìlú olódi wọn. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun sì padà sí ọ̀dọ̀ Joṣua ní ibùdó ogun ní Makkeda ní àlàáfíà, kò sí àwọn tí ó dábàá láti tún kọlu Israẹli. Joṣua sì wí pe, “Ẹ ṣí ẹnu ihò náà, kí ẹ sì mú àwọn ọba márààrún jáde wá fún mi.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú àwọn ọba márààrún náà kúrò nínú ihò àpáta, àwọn ọba Jerusalẹmu, Hebroni, Jarmatu, Lakiṣi àti Egloni. Nígbà tí wọ́n mú àwọn ọba náà tọ Joṣua wá, ó pe gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli, ó sì sọ fún àwọn olórí ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé, “Ẹ súnmọ́ bí, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ yín lé ọrùn àwọn ọba wọ̀nyí.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wá sí iwájú, wọ́n sì gbé ẹsẹ̀ lé ọrùn wọn. Joṣua sì sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ ṣe gírí, kí ẹ sì mú àyà le. Báyìí ni OLúWA yóò ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀tá yín, tí ẹ̀yin yóò bá jà.” Nígbà náà ni Joṣua kọlù wọ́n, ó sì pa àwọn ọba márààrún náà, ó sì so wọ́n rọ̀ ní orí igi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ márùn-ún, wọ́n sì fi wọ́n sí orí igi títí di ìrọ̀lẹ́. Nígbà tí oòrùn wọ̀, Joṣua pàṣẹ, wọ́n sì sọ̀ wọ́n kalẹ̀ kúrò ní orí igi, wọ́n sì gbé wọn jù sí inú ihò àpáta ní ibi tí wọ́n sápamọ́ sí. Wọ́n sì fi òkúta ńlá dí ẹnu ihò náà, tí ó sì wà níbẹ̀ di òní yìí. Ní ọjọ́ náà Joṣua gba Makkeda. Ó sì fi ojú idà kọlu ìlú náà àti ọba rẹ̀, ó sì run gbogbo wọn pátápátá, kò fi ẹnìkan sílẹ̀. Ó sì ṣe sí ọba Makkeda gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí ọba Jeriko.