Àmì-ìdánimọ̀ YouVersion
BíbélìÀwon ètòÀwon Fídíò
Gba ohun èlò náà
Àṣàyàn Èdè
Ṣe Àwárí

Joṣ 1:5-6

Joṣ 1:5-6 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ki yio sí ọkunrin kan ti yio le duro niwaju rẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo: gẹgẹ bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹ̃li emi o si wà pẹlu rẹ: Emi ki yio fi ọ silẹ, bẹ̃li emi ki yio kọ̀ ọ. Ṣe giri, ki o si mu àiya le: nitori iwọ ni yio pín ilẹ na fun awọn enia yi, ilẹ ti mo ti bura fun awọn baba wọn lati fi fun wọn.

Pín
Kà Joṣ 1

Joṣ 1:5-6 Yoruba Bible (YCE)

Kò ní sí ẹni tí yóo lè borí rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Bí mo ti wà pẹlu Mose ni n óo wà pẹlu rẹ. N kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lae. Múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí, nítorí ìwọ ni o óo jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn, pé n óo fún wọn.

Pín
Kà Joṣ 1

Joṣ 1:5-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò le è dúró níwájú rẹ ní ọjọ́ ayé è rẹ gbogbo. Bí mo ti wà pẹ̀lú u Mose, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èmi kì yóò kọ̀ ọ́. “Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le, nítorí ìwọ ni yóò ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, láti lè jogún ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fi fún wọn.

Pín
Kà Joṣ 1
YouVersion

Ńgbà ọ́ níyànjú ó ṣì ń pè ọ́ níjà láti súnmọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́.

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Nípaa

Àwọn iṣẹ́

Oluyọọda

Blọ́ọ̀gì

Tè

Àwọn ojú-ìwé tí ó wúlò

Ìrànlọ́wọ́

Fifún ni

Àwon Èyà Bíbélì

Àwọn Bíbélì àfetígbọ́

Àwọn Èdè Bíbélì

Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní


Isẹ́ Ìránṣẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé

Life.Church
English (US)

©2025 Life.Church / YouVersion

Ìṣe ìdá kọ́ńkó̩Àwon àdéhùn
Ètò Ìpolongo Àwọn Àìléwu
FacebookTwitterInstagramYouTubePinterest

Ilé

Bíbélì

Àwon ètò

Àwon Fídíò