Joṣ 1:2-3
Joṣ 1:2-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mose iranṣẹ mi kú; njẹ iwọ, dide, gòke Jordani yi, iwọ, ati gbogbo enia yi, si ilẹ ti mo fi fun wọn, ani fun awọn ọmọ Israeli. Ibi gbogbo ti atẹlẹsẹ̀ nyin ba tẹ̀, ẹnyin ni mo fi fun, gẹgẹ bi mo ti sọ fun Mose.
Pín
Kà Joṣ 1Joṣ 1:2-3 Yoruba Bible (YCE)
“Mose iranṣẹ mi ti kú, nítorí náà, ìwọ ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ẹ múra kí ẹ la odò Jọdani kọjá, kí ẹ sì wọ ilẹ̀ tí n óo fun yín. Gbogbo ibi tí ẹsẹ̀ yín bá tẹ̀ ni mo ti fun yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣèlérí fún Mose.
Pín
Kà Joṣ 1Joṣ 1:2-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Mose ìránṣẹ́ mi ti kú. Nísinsin yìí, ìwọ àti gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí, ẹ múra láti kọjá odò Jordani lọ sí ilẹ̀ tí Èmi ó fi fún wọn fún àwọn ará Israẹli. Èmi yóò fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ ẹ yín tẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ìlérí fún Mose.
Pín
Kà Joṣ 1