Jon 3:1-10
Jon 3:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ Jona wá lẹ̃keji, wipe, Dide, lọ si Ninefe, ilu nla nì, ki o si kede si i, ikede ti mo sọ fun ọ. Jona si dide, o si lọ si Ninefe, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa. Ninefe si jẹ ilu nla gidigidi tó irin ijọ mẹta. Jona si bẹrẹsi wọ inu ilu na lọ ni irin ijọ kan, o si kede, o si wipe, Niwọn ogoji ọjọ si i, a o bì Ninefe wo. Awọn enia Ninefe si gba Ọlọrun gbọ́, nwọn si kede awẹ̀, nwọn si wọ aṣọ ọ̀fọ, lati agbà wọn titi de kekere wọn. Ọ̀rọ na si de ọdọ ọba Ninefe, o si dide kuro lori itẹ rẹ̀, o si bọ aṣọ igunwa rẹ̀ kuro lara rẹ̀, o si daṣọ ọ̀fọ bora, o si joko ninu ẽru. O si kede rẹ̀, o si wi pe ki a là Ninefe ja nipa aṣẹ ọba, ati awọn agbagbà rẹ̀ pe, Máṣe jẹ ki enia, tabi ẹranko, ọwọ-ẹran tabi agbo-ẹran, tọ́ ohunkohun wò: má jẹ ki wọn jẹun, má jẹ ki wọn mu omi. Ṣugbọn jẹ ki enia ati ẹranko fi aṣọ ọ̀fọ bora, ki nwọn si kigbe kikan si Ọlọrun: si jẹ ki nwọn yipada, olukuluku kuro li ọ̀na ibi rẹ̀, ati kuro ni ìwa agbara ti o wà lọwọ wọn. Tani le mọ̀ bi Ọlọrun yio yipada ki o si ronupiwada, ki o si yipada kuro ni ibinu gbigbona rẹ̀, ki awa má ṣegbe? Ọlọrun si ri iṣe wọn pe nwọn yipada kuro li ọ̀na ibi wọn: Ọlọrun si ronupiwada ibi ti on ti wi pe on o ṣe si wọn; on kò si ṣe e mọ.

Jon 3:1-10 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA tún bá Jona sọ̀rọ̀ nígbà keji, ó ní: “Dìde, lọ sí Ninefe, ìlú ńlá nì, kí o sì kéde iṣẹ́ tí mo rán ọ fún gbogbo eniyan ibẹ̀.” Jona bá dìde, ó lọ sí Ninefe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA. Ninefe jẹ́ ìlú tí ó tóbi, ó gbà tó ìrìn ọjọ́ mẹta láti la ìlú náà já. Jona rin ìlú náà fún odidi ọjọ́ kan, ó sì ń kéde pé: “Níwọ̀n ogoji ọjọ́ sí i, Ninefe óo parun.” Àwọn ará Ninefe gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbọ́, wọ́n bá kéde pé kí gbogbo eniyan gbààwẹ̀, àtọmọdé, àtàgbà, wọ́n sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora. Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà dé etígbọ̀ọ́ ọba Ninefe ó dìde lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó bọ́ ẹ̀wù oyè sílẹ̀, ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì jókòó ninu eérú. Ó bá ní kí wọn kéde fún àwọn ará Ninefe, pé, “Ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ pàṣẹ pé, eniyan tabi ẹranko, tabi ẹran ọ̀sìn kankan kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan ohunkohun. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ, wọn kò sì gbọdọ̀ mu. Ṣugbọn kí gbogbo wọn fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, kí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn wọn gbadura sí Ọlọrun. Kí olukuluku pa ọ̀nà burúkú ati ìwà ipá tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ tì. A kì í mọ̀, bóyá Ọlọrun lè yí ọkàn rẹ̀ pada, kí ó má jẹ wá níyà mọ́. Bóyá yóo tilẹ̀ dá ibinu rẹ̀ dúró, kò sì ní pa wá run.” Nígbà tí Ọlọrun rí i pé wọ́n ti pa ìwà burúkú wọn tì, Ọlọrun náà bá yí ìpinnu rẹ̀ pada, kò sì jẹ wọ́n níyà mọ́.
Jon 3:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ Jona wá nígbà kejì wí pé: “Dìde lọ sí Ninefe, ìlú ńlá a nì, kí o sì kéde sí i, ìkéde tí mo sọ fún ọ.” Jona sì dìde ó lọ sí Ninefe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLúWA. Ninefe jẹ́ ìlú títóbi gidigidi, ó tó ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. Jona sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ ìlú náà lọ ní ìrìn ọjọ́ kan, ó sì ń kéde, ó sì wí pé, “Níwọ́n ogójì ọjọ́ sí i, a ó bi Ninefe wó.” Àwọn ènìyàn Ninefe sì gba Ọlọ́run gbọ́. Wọ́n sì kéde àwẹ̀, gbogbo wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, bẹ̀rẹ̀ láti orí ọmọdé títí dé orí àgbà wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì dé ọ̀dọ̀ ọba Ninefe, ó sì dìde kúrò lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì bọ́ aṣọ ìgúnwà rẹ̀ kúrò lára rẹ̀, ó sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì jókòó nínú eérú. Nígbà náà ní ó kéde rẹ̀ ni Ninefe pé: “Kí a la Ninefe já nípa àṣẹ ọba, àti àwọn àgbàgbà rẹ̀ pé: “Má ṣe jẹ́ kí ènìyàn, tàbí ẹranko, ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo ẹran, tọ́ ohunkóhun wò: má jẹ́ kí wọn jẹ tàbí mu omi. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn àti ẹranko da aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara, kí wọn sì kígbe kíkan sí Ọlọ́run, sì jẹ́ kí wọn yípadà, olúkúlùkù kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀ àti kúrò ní ìwà ìpa tí ó wà lọ́wọ́ wọn. Ta ni ó lè mọ̀ bí Ọlọ́run yóò yípadà kí ó sì ronúpìwàdà, kí ó sì yípadà kúrò ní ìbínú gbígbóná rẹ̀, kí àwa má ṣègbé?” Ọlọ́run sì rí ìṣe wọn pé wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀nà ibi wọn: Ọlọ́run sì ronúpìwàdà ibi tí òun ti wí pé òun yóò ṣe sí wọn, òun kò sì ṣe e mọ́.