Jon 1:6-8
Jon 1:6-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃li olori-ọkọ̀ tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Kini iwọ rò, iwọ olõrun? dide, kepe Ọlọrun rẹ, boya Ọlọrun yio ro tiwa, ki awa ki o má bà ṣegbé. Olukuluku wọn si wi fun ẹgbẹ rẹ̀ pe, Wá, ẹ si jẹ ka ṣẹ keké, ki awa ki o le mọ̀ itori tani buburu yi ṣe wá sori wa. Bẹ̃ni nwọn ṣẹ keké, keké si mu Jona. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Sọ fun wa, awa bẹ̀ ọ, nitori ti tani buburu yi ṣe wá sori wa? kini iṣẹ rẹ? nibo ni iwọ si ti wá? orukọ ilu rẹ? orilẹ-ède wo ni iwọ si iṣe?
Jon 1:6-8 Yoruba Bible (YCE)
Olórí àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Kí ló ṣe ọ́ tí ò ń sùn, olóorun? Dìde, ké pe ọlọrun rẹ, bóyá a jẹ́ ṣàánú wa, kí á má baà ṣègbé.” Wọ́n bá dámọ̀ràn láàrin ara wọn, wọ́n ní “Ẹ jẹ́ kí á ṣẹ́ gègé, kí á lè mọ ẹni tí ó fà á, tí nǹkan burúkú yìí fi dé bá wa.” Wọ́n ṣẹ́ gègé, gègé bá mú Jona. Wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa, nítorí ta ni nǹkan burúkú yìí fi dé bá wa? Kí ni iṣẹ́ rẹ? Níbo ni o ti wá? Níbo ni orílẹ̀-èdè rẹ? Inú ẹ̀yà wo ni o sì ti wá?”
Jon 1:6-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bẹ́ẹ̀ ni olórí ọkọ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi sùn, ìwọ olóòórùn? Dìde kí o ké pe Ọlọ́run rẹ! Bóyá yóò ro tiwa, kí àwa má ba à ṣègbé.” Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ sọ fún ara wọn pé, “Wá, ẹ jẹ́ kí a sẹ́ kèké, kí àwa kí o le mọ̀ nítorí ta ni búburú yìí ṣe wá sórí wa.” Wọ́n ṣẹ́ kèké, kèké sì mú Jona. Nígbà náà ni wọn wí fún un pé, “Sọ fún wa, àwa bẹ̀ ọ́, nítorí ta ni búburú yìí ṣe wá sórí wa? Kí ni iṣẹ́ rẹ? Níbo ni ìwọ ti wá? Kí ni orúkọ ìlú rẹ? Ẹ̀yà orílẹ̀-èdè wo sì ni ìwọ sì í ṣe?”