Jon 1:4-9
Jon 1:4-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn Oluwa rán ẹfufu nla jade si oju okun, ijì lile si wà ninu okun, tobẹ̃ ti ọkọ̀ na dabi ẹnipe yio fọ. Nigbana ni awọn atukọ̀ bẹ̀ru, olukuluku si kigbe si ọlọrun rẹ̀, nwọn ko ẹrù ti o wà ninu ọkọ dà sinu okun, lati mu u fẹrẹ. Ṣugbọn Jona sọkalẹ lọ si ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀; o si dubulẹ sùn wọra. Bẹ̃li olori-ọkọ̀ tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Kini iwọ rò, iwọ olõrun? dide, kepe Ọlọrun rẹ, boya Ọlọrun yio ro tiwa, ki awa ki o má bà ṣegbé. Olukuluku wọn si wi fun ẹgbẹ rẹ̀ pe, Wá, ẹ si jẹ ka ṣẹ keké, ki awa ki o le mọ̀ itori tani buburu yi ṣe wá sori wa. Bẹ̃ni nwọn ṣẹ keké, keké si mu Jona. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Sọ fun wa, awa bẹ̀ ọ, nitori ti tani buburu yi ṣe wá sori wa? kini iṣẹ rẹ? nibo ni iwọ si ti wá? orukọ ilu rẹ? orilẹ-ède wo ni iwọ si iṣe? On si wi fun wọn pe, Heberu li emi; mo si bẹ̀ru Oluwa, Ọlọrun ọrun, ti o dá okun ati iyangbẹ ilẹ.
Jon 1:4-9 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn OLUWA gbé ìjì kan dìde lójú omi òkun, afẹ́fẹ́ náà le tóbẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ ojú omi fẹ́rẹ̀ ya. Ẹ̀rù ba àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀, olukuluku bá bẹ̀rẹ̀ sí ké pe oriṣa rẹ̀, wọ́n ń da ẹrù wọn tí ó wà ninu ọkọ̀ sinu òkun kí ọkọ̀ lè fúyẹ́. Ṣugbọn Jona ti lọ dùbúlẹ̀ sí ìsàlẹ̀ ọkọ̀, ó sì ti sùn lọ fọnfọn. Olórí àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Kí ló ṣe ọ́ tí ò ń sùn, olóorun? Dìde, ké pe ọlọrun rẹ, bóyá a jẹ́ ṣàánú wa, kí á má baà ṣègbé.” Wọ́n bá dámọ̀ràn láàrin ara wọn, wọ́n ní “Ẹ jẹ́ kí á ṣẹ́ gègé, kí á lè mọ ẹni tí ó fà á, tí nǹkan burúkú yìí fi dé bá wa.” Wọ́n ṣẹ́ gègé, gègé bá mú Jona. Wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa, nítorí ta ni nǹkan burúkú yìí fi dé bá wa? Kí ni iṣẹ́ rẹ? Níbo ni o ti wá? Níbo ni orílẹ̀-èdè rẹ? Inú ẹ̀yà wo ni o sì ti wá?” Ó bá dá wọn lóhùn pé: “Heberu ni mí, ẹ̀rù OLUWA ni ó bà mí, àní Ọlọrun ọ̀run, tí ó dá òkun ati ilẹ̀ gbígbẹ.”
Jon 1:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni OLúWA rán ìjì ńlá jáde sí ojú Òkun, ìjì líle sì wà nínú Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ náà dàbí ẹni pé yóò fọ́. Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ bẹ̀rù, olúkúlùkù sì ń kígbe sí ọlọ́run rẹ̀, wọ́n kó ẹrù tí ó wà nínú ọkọ̀ dà sínú Òkun, kí ó bá à lè fúyẹ́. Ṣùgbọ́n Jona sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ọkọ̀ ó sì dùbúlẹ̀, ó sùn wọra. Bẹ́ẹ̀ ni olórí ọkọ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi sùn, ìwọ olóòórùn? Dìde kí o ké pe Ọlọ́run rẹ! Bóyá yóò ro tiwa, kí àwa má ba à ṣègbé.” Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ sọ fún ara wọn pé, “Wá, ẹ jẹ́ kí a sẹ́ kèké, kí àwa kí o le mọ̀ nítorí ta ni búburú yìí ṣe wá sórí wa.” Wọ́n ṣẹ́ kèké, kèké sì mú Jona. Nígbà náà ni wọn wí fún un pé, “Sọ fún wa, àwa bẹ̀ ọ́, nítorí ta ni búburú yìí ṣe wá sórí wa? Kí ni iṣẹ́ rẹ? Níbo ni ìwọ ti wá? Kí ni orúkọ ìlú rẹ? Ẹ̀yà orílẹ̀-èdè wo sì ni ìwọ sì í ṣe?” Òun sì dá wọn lóhùn pé, “Heberu ni èmi, mo sì bẹ̀rù OLúWA, Ọlọ́run ọ̀run ẹni tí ó dá Òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀.”