Jon 1:1-5
Jon 1:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jona ọmọ Amittai wá, wipe, Dide, lọ si Ninefe, ilu nla nì, ki o si kigbe si i; nitori ìwa buburu wọn goke wá iwaju mi. Ṣugbọn Jona dide lati sá lọ si Tarṣiṣi kuro niwaju Oluwa, o si sọkalẹ lọ si Joppa; o si ri ọkọ̀ kan ti nlọ si Tarṣiṣi: bẹ̃li o sanwo ọkọ, o si sọkalẹ sinu rẹ̀, lati ba wọn lọ si Tarṣiṣi lati sá kuro niwaju Oluwa. Ṣugbọn Oluwa rán ẹfufu nla jade si oju okun, ijì lile si wà ninu okun, tobẹ̃ ti ọkọ̀ na dabi ẹnipe yio fọ. Nigbana ni awọn atukọ̀ bẹ̀ru, olukuluku si kigbe si ọlọrun rẹ̀, nwọn ko ẹrù ti o wà ninu ọkọ dà sinu okun, lati mu u fẹrẹ. Ṣugbọn Jona sọkalẹ lọ si ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀; o si dubulẹ sùn wọra.
Jon 1:1-5 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA bá Jona ọmọ Amitai sọ̀rọ̀, ó ní, “Dìde, lọ sí Ninefe, ìlú ńlá nì, kéde, kí o sì kìlọ̀ fún wọn pé mo rí gbogbo ìwà burúkú wọn!” Ṣugbọn Jona gbéra ó fẹ́ sálọ sí Taṣiṣi, kí ó lè kúrò níwájú OLUWA. Ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jọpa, ó sì rí ọkọ̀ ojú omi kan tí ń lọ sí Taṣiṣi níbẹ̀. Ó san owó ọkọ̀, ó bá bọ́ sinu ọkọ̀, ó fẹ́ máa bá a lọ sí Taṣiṣi kí ó sì sá kúrò níwájú OLUWA. Ṣugbọn OLUWA gbé ìjì kan dìde lójú omi òkun, afẹ́fẹ́ náà le tóbẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ ojú omi fẹ́rẹ̀ ya. Ẹ̀rù ba àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀, olukuluku bá bẹ̀rẹ̀ sí ké pe oriṣa rẹ̀, wọ́n ń da ẹrù wọn tí ó wà ninu ọkọ̀ sinu òkun kí ọkọ̀ lè fúyẹ́. Ṣugbọn Jona ti lọ dùbúlẹ̀ sí ìsàlẹ̀ ọkọ̀, ó sì ti sùn lọ fọnfọn.
Jon 1:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ Jona ọmọ Amittai wá, wí pé: “Dìde lọ sí ìlú ńlá Ninefe kí o sì wàásù sí i, nítorí ìwà búburú rẹ̀ gòkè wá iwájú mi.” Ṣùgbọ́n Jona dìde kúrò láti sálọ sí Tarṣiṣi kúrò níwájú OLúWA, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Joppa, ìbí ti ó tí rí ọkọ̀ kan tí ń lọ sí Tarṣiṣi: lẹ́yìn ti ó sanwó ọkọ̀, ó wọlé sínú rẹ̀, láti bá wọn lọ sí Tarṣiṣi kúrò níwájú OLúWA. Nígbà náà ni OLúWA rán ìjì ńlá jáde sí ojú Òkun, ìjì líle sì wà nínú Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ náà dàbí ẹni pé yóò fọ́. Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ bẹ̀rù, olúkúlùkù sì ń kígbe sí ọlọ́run rẹ̀, wọ́n kó ẹrù tí ó wà nínú ọkọ̀ dà sínú Òkun, kí ó bá à lè fúyẹ́. Ṣùgbọ́n Jona sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ọkọ̀ ó sì dùbúlẹ̀, ó sùn wọra.