Joel 3:9-11
Joel 3:9-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ kede eyi li ãrin awọn keferi; ẹ yà ogun si mimọ́, ẹ ji awọn alagbara, ẹ sunmọ tòsi, ẹ goke wá gbogbo ẹnyin ọkunrin ologun. Ẹ fi irin ọkọ́ itulẹ̀ nyin rọ idà, ati dojé nyin rọ ọkọ̀: jẹ ki alailera wi pe, Ara mi le koko. Ẹ kó ara nyin jọ, si wá, gbogbo ẹnyin keferi, ẹ si gbá ara nyin jọ yikakiri: nibẹ̀ ni ki o mu awọn alagbara rẹ sọkalẹ, Oluwa.
Joel 3:9-11 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ kéde èyí láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè. Ẹ múra ogun, ẹ rú àwọn akọni sókè. Kí gbogbo àwọn ọmọ ogun súnmọ́ tòsí, ogun yá! Ẹ fi irin ọkọ́ yín rọ idà, ẹ fi dòjé yín rọ ọ̀kọ̀, kí àwọn tí wọn kò lágbára wí pé, “Ọmọ ogun ni mí.” Ẹ yára, ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tí ẹ wà ní àyíká, ẹ parapọ̀ níbẹ̀. Rán àwọn ọmọ ogun rẹ wá, OLUWA.
Joel 3:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ kéde èyí ní àárín àwọn kèfèrí; Ẹ dira ogun, ẹ jí àwọn alágbára, Jẹ kí àwọn ajagun kí wọn bẹ̀rẹ̀ ogun, Ẹ fi irin ìtulẹ̀ yín rọ idà, àti dòjé yín rọ ọ̀kọ̀. Jẹ́ kí aláìlera wí pé, “Ara mi le koko.” Ẹ wá kánkán, gbogbo ẹ̀yin kèfèrí láti gbogbo àyíká, kí ẹ sì gbá ara yín jọ yí káàkiri.