Joel 3:17-21
Joel 3:17-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃li ẹnyin o mọ̀ pe, Emi li Oluwa Ọlọrun nyin, ti ngbe Sioni oke mimọ́ mi: nigbana ni Jerusalemu yio jẹ mimọ́, awọn alejo kì yio si là a kọja mọ. Yio si ṣe li ọjọ na, awọn oke-nla yio ma kán ọti-waini titún silẹ, awọn oke kékèké yio ma ṣàn fun warà, ati gbogbo odò Juda yio ma ṣan fun omi, orisun kan yio si jade lati inu ile Oluwa wá, yio si rin afonifojì Ṣittimu. Egipti yio di ahoro, Edomu yio si di aginju ahoro, nitori ìwa ipá si awọn ọmọ Juda, nitoriti nwọn ti ta ẹjẹ̀ alaiṣẹ̀ silẹ ni ilẹ wọn. Ṣugbọn Juda yio joko titi lai, ati Jerusalemu lati iran de iran. Nitori emi o wẹ̀ ẹjẹ̀ wọn nù, ti emi kò ti wẹ̀nu: nitori Oluwa ngbe Sioni.
Joel 3:17-21 Yoruba Bible (YCE)
“Israẹli, o óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA, Ọlọrun rẹ, èmi ni mò ń gbé Sioni, òkè mímọ́ mi. Jerusalẹmu yóo di ìlú mímọ́, àwọn àjèjì kò sì ní ṣẹgun mọ́. “Nígbà náà, àwọn òkè ńlá yóo kún fún èso àjàrà, agbo mààlúù yóo sì pọ̀ lórí àwọn òkè kéékèèké. Gbogbo àwọn odò Juda yóo kún fún omi. Odò kan yóo bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn láti ilé OLUWA, yóo sì bomi rin àfonífojì Ṣitimu. “Ijipti yóo di aṣálẹ̀; Edomu yóo sì di ẹgàn, nítorí ìwà ipá tí wọ́n hù sí àwọn ará Juda, nítorí wọ́n ti pa àwọn aláìṣẹ̀ ní ilẹ̀ wọn. Ṣugbọn àwọn eniyan yóo máa gbé ilẹ̀ Juda títí lae, wọn óo sì máa gbé ìlú Jerusalẹmu láti ìrandíran. N óo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn tí ẹ pa, n kò sì ní dá ẹlẹ́bi sí, nítorí èmi OLUWA ni mò ń gbé Sioni.”
Joel 3:17-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín, tí ń gbé Sioni òkè mímọ́ mi. Ìgbà náà ni Jerusalẹmu yóò jẹ́ mímọ́; àwọn àjèjì kì yóò sì kó o mọ́. “Ní ọjọ́ náà, àwọn òkè ńlá yóò máa kán ọtí wáìnì tuntun sílẹ̀, àwọn òkè kéékèèkéé yóò máa sàn fún wàrà; gbogbo odò Juda tí ó gbẹ́ yóò máa sàn fún omi. Orísun kan yóò sì ṣàn jáde láti inú ilé OLúWA wá, yóò sì rin omi sí àfonífojì Ṣittimu. Ṣùgbọ́n Ejibiti yóò di ahoro, Edomu yóò sì di aṣálẹ̀ ahoro, nítorí ìwà ipá tí a hù sì àwọn ọmọ Juda, ní ilẹ̀ ẹni tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n Juda yóò jẹ́ ibùgbé títí láé, àti Jerusalẹmu láti ìran dé ìran. Nítorí èmi yóò wẹ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn nù, tí èmi kò tí ì wẹ̀nù.