Joel 3:1-4
Joel 3:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORINA kiyesi i, li ọjọ wọnni, ati li akokò na, nigbati emi o tun mu igbèkun Juda ati Jerusalemu padà bọ̀. Emi o kó gbogbo orilẹ-ède jọ pẹlu, emi o si mu wọn wá si afonifojì Jehoṣafati, emi o si ba wọn wijọ nibẹ̀ nitori awọn enia mi, ati nitori Israeli iní mi, ti nwọn ti fọ́n ka sãrin awọn orilẹ̀-ede, nwọn si ti pín ilẹ mi. Nwọn si ti di ibò fun awọn enia mi; nwọn si ti fi ọmọdekunrin kan fun panṣagà obinrin kan, nwọn si ti tà ọmọdebinrin kan fun ọti-waini, ki nwọn ki o le mu. Nitõtọ, ati ki li ẹnyin ni ifi mi ṣe, ẹnyin Tire ati Sidoni, ati gbogbo ẹkùn Palestina? ẹnyin o ha san ẹsan fun mi? bi ẹnyin ba si san ẹsan fun mi, ni kánkan ati ni koyákoyá li emi o san ẹsan nyin padà sori ara nyin.
Joel 3:1-4 Yoruba Bible (YCE)
“Wò ó! Nígbà tó bá yá, tí mo bá dá ire Juda ati ti Jerusalẹmu pada, n óo kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí àfonífojì Jehoṣafati, n óo sì dá wọn lẹ́jọ́ níbẹ̀; nítorí ohun tí wọ́n ti ṣe sí Israẹli, àwọn eniyan mi. Wọ́n ti fọ́n wọn káàkiri sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì ti pín ilẹ̀ mi. Wọ́n ti ṣẹ́ gègé lórí àwọn eniyan mi, wọ́n ti ta àwọn ọmọkunrin wọn, wọ́n fi owó wọn san owó aṣẹ́wó, wọ́n sì ta àwọn ọmọbinrin wọn, wọ́n fi owó wọn ra ọtí waini. “Kí ni mo fi ṣe yín rí, ẹ̀yin ilẹ̀ Tire, ati ilẹ̀ Sidoni ati gbogbo agbègbè Filistini? Ṣé ẹ̀ ń gbẹ̀san nǹkankan lára mi ni? Bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀ ń gbẹ̀san nǹkankan ni, n óo da ẹ̀san tí ẹ̀ ń gbà le yín lórí kíákíá
Joel 3:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti ní àkókò náà, nígbà tí èmi tún mú ìgbèkùn Juda àti Jerusalẹmu padà bọ̀. Èmi yóò kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ pẹ̀lú èmi yóò sì mú wọn wá sí Àfonífojì Jehoṣafati. Èmi yóò sì bá wọn wíjọ́ níbẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn mi, àti nítorí Israẹli ìní mi, tí wọ́n fọ́nká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì pín ilẹ̀ mi. Wọ́n si ti di ìbò fún àwọn ènìyàn mi; wọ́n sì ti fi ọmọdékùnrin kan fún panṣágà obìnrin kan, wọ́n sì ta ọmọdébìnrin kan fún ọtí wáìnì, kí wọ́n kí ó lè mu. “Nísinsin yìí, kí ni ẹ̀yin ní fi mí ṣe Tire àti Sidoni, àti gbogbo ẹ̀yin ẹkún Filistia? Ẹ̀yin yóò ha sàn ẹ̀san fún mi? Bí ẹ̀yin bá sì san ẹ̀san fún mi, ní kánkán àti ní kíákíá ní èmi yóò san ẹ̀san ohun ti ẹ̀yin ṣe padà sórí ara yín.