Joel 3:1-2
Joel 3:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORINA kiyesi i, li ọjọ wọnni, ati li akokò na, nigbati emi o tun mu igbèkun Juda ati Jerusalemu padà bọ̀. Emi o kó gbogbo orilẹ-ède jọ pẹlu, emi o si mu wọn wá si afonifojì Jehoṣafati, emi o si ba wọn wijọ nibẹ̀ nitori awọn enia mi, ati nitori Israeli iní mi, ti nwọn ti fọ́n ka sãrin awọn orilẹ̀-ede, nwọn si ti pín ilẹ mi.
Joel 3:1-2 Yoruba Bible (YCE)
“Wò ó! Nígbà tó bá yá, tí mo bá dá ire Juda ati ti Jerusalẹmu pada, n óo kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí àfonífojì Jehoṣafati, n óo sì dá wọn lẹ́jọ́ níbẹ̀; nítorí ohun tí wọ́n ti ṣe sí Israẹli, àwọn eniyan mi. Wọ́n ti fọ́n wọn káàkiri sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì ti pín ilẹ̀ mi.
Joel 3:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti ní àkókò náà, nígbà tí èmi tún mú ìgbèkùn Juda àti Jerusalẹmu padà bọ̀. Èmi yóò kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ pẹ̀lú èmi yóò sì mú wọn wá sí Àfonífojì Jehoṣafati. Èmi yóò sì bá wọn wíjọ́ níbẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn mi, àti nítorí Israẹli ìní mi, tí wọ́n fọ́nká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì pín ilẹ̀ mi.