Joel 3:1-16
Joel 3:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORINA kiyesi i, li ọjọ wọnni, ati li akokò na, nigbati emi o tun mu igbèkun Juda ati Jerusalemu padà bọ̀. Emi o kó gbogbo orilẹ-ède jọ pẹlu, emi o si mu wọn wá si afonifojì Jehoṣafati, emi o si ba wọn wijọ nibẹ̀ nitori awọn enia mi, ati nitori Israeli iní mi, ti nwọn ti fọ́n ka sãrin awọn orilẹ̀-ede, nwọn si ti pín ilẹ mi. Nwọn si ti di ibò fun awọn enia mi; nwọn si ti fi ọmọdekunrin kan fun panṣagà obinrin kan, nwọn si ti tà ọmọdebinrin kan fun ọti-waini, ki nwọn ki o le mu. Nitõtọ, ati ki li ẹnyin ni ifi mi ṣe, ẹnyin Tire ati Sidoni, ati gbogbo ẹkùn Palestina? ẹnyin o ha san ẹsan fun mi? bi ẹnyin ba si san ẹsan fun mi, ni kánkan ati ni koyákoyá li emi o san ẹsan nyin padà sori ara nyin. Nitoriti ẹnyin ti mu fàdakà mi ati wurà mi, ẹnyin si ti mu ohun rere daradara mi lọ sinu tempili nyin: Ati awọn ọmọ Juda, ati awọn ọmọ Jerusalemu li ẹnyin ti tà fun awọn ara Griki, ki ẹnyin ba le sìn wọn jina kuro li agbègbe wọn. Kiyesi i, emi o gbe wọn dide kuro nibiti ẹnyin ti tà wọn si, emi o si san ẹsan nyin padà sori ara nyin. Emi o si tà awọn ọmọkunrin nyin ati awọn ọmọbinrin nyin si ọwọ́ awọn ọmọ Juda, nwọn o si tà wọn fun awọn ara Sabia, fun orilẹ-ède kan ti o jinà rére, nitori Oluwa li o ti sọ ọ. Ẹ kede eyi li ãrin awọn keferi; ẹ yà ogun si mimọ́, ẹ ji awọn alagbara, ẹ sunmọ tòsi, ẹ goke wá gbogbo ẹnyin ọkunrin ologun. Ẹ fi irin ọkọ́ itulẹ̀ nyin rọ idà, ati dojé nyin rọ ọkọ̀: jẹ ki alailera wi pe, Ara mi le koko. Ẹ kó ara nyin jọ, si wá, gbogbo ẹnyin keferi, ẹ si gbá ara nyin jọ yikakiri: nibẹ̀ ni ki o mu awọn alagbara rẹ sọkalẹ, Oluwa. Ẹ ji, ẹ si goke wá si afonifojì Jehoṣafati ẹnyin keferi: nitori nibẹ̀ li emi o joko lati ṣe idajọ awọn keferi yikakiri. Ẹ tẹ̀ doje bọ̀ ọ, nitori ikore pọ́n: ẹ wá, ẹ sọkalẹ; nitori ifunti kún, nitori awọn ọpọ́n kún rekọja, nitori ìwa-buburu wọn pọ̀. Ọ̀pọlọpọ, ọ̀pọlọpọ li afonifojì idajọ, nitori ọjọ Oluwa kù si dẹ̀dẹ ni afonifojì idajọ. Õrùn ati oṣupa yio ṣu òkunkun, ati awọn irawọ̀ yio fà titàn wọn sẹhin. Oluwa yio si ké ramùramù lati Sioni wá, yio si fọ ohùn rẹ̀ jade lati Jerusalemu wá; awọn ọrun ati aiye yio si mì: ṣugbọn Oluwa yio ṣe ãbò awọn enia rẹ̀, ati agbara awọn ọmọ Israeli.
Joel 3:1-16 Yoruba Bible (YCE)
“Wò ó! Nígbà tó bá yá, tí mo bá dá ire Juda ati ti Jerusalẹmu pada, n óo kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí àfonífojì Jehoṣafati, n óo sì dá wọn lẹ́jọ́ níbẹ̀; nítorí ohun tí wọ́n ti ṣe sí Israẹli, àwọn eniyan mi. Wọ́n ti fọ́n wọn káàkiri sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì ti pín ilẹ̀ mi. Wọ́n ti ṣẹ́ gègé lórí àwọn eniyan mi, wọ́n ti ta àwọn ọmọkunrin wọn, wọ́n fi owó wọn san owó aṣẹ́wó, wọ́n sì ta àwọn ọmọbinrin wọn, wọ́n fi owó wọn ra ọtí waini. “Kí ni mo fi ṣe yín rí, ẹ̀yin ilẹ̀ Tire, ati ilẹ̀ Sidoni ati gbogbo agbègbè Filistini? Ṣé ẹ̀ ń gbẹ̀san nǹkankan lára mi ni? Bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀ ń gbẹ̀san nǹkankan ni, n óo da ẹ̀san tí ẹ̀ ń gbà le yín lórí kíákíá; nítorí ẹ ti kó fadaka ati wúrà ati àwọn ìṣúra mi olówó iyebíye lọ sí ilé oriṣa yín. Ẹ ta àwọn ará Juda ati àwọn ará Jerusalẹmu fún àwọn ará Giriki, ẹ kó wọn jìnnà réré sí ilẹ̀ wọn. Ṣugbọn nisinsinyii, n óo gbé wọn dìde níbi tí ẹ tà wọ́n sí, n óo sì gbẹ̀san ìwà yín lára ẹ̀yin alára. N óo ta àwọn ọmọ yín ọkunrin ati àwọn ọmọ yín obinrin lẹ́rú fún àwọn ará Juda. Wọn yóo sì tà wọ́n fún àwọn ará Sabea, orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà réré; nítorí OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.” Ẹ kéde èyí láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè. Ẹ múra ogun, ẹ rú àwọn akọni sókè. Kí gbogbo àwọn ọmọ ogun súnmọ́ tòsí, ogun yá! Ẹ fi irin ọkọ́ yín rọ idà, ẹ fi dòjé yín rọ ọ̀kọ̀, kí àwọn tí wọn kò lágbára wí pé, “Ọmọ ogun ni mí.” Ẹ yára, ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tí ẹ wà ní àyíká, ẹ parapọ̀ níbẹ̀. Rán àwọn ọmọ ogun rẹ wá, OLUWA. Jẹ́ kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè dìde, kí wọ́n wá sí àfonífojì Jehoṣafati, nítorí níbẹ̀ ni n óo ti ṣe ìdájọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó wà ní àyíká. Ẹ ti dòjé bọ oko, nítorí àkókò ìkórè ti tó, ẹ lọ fún ọtí waini nítorí ibi ìfúntí ti kún. Ìkòkò ọtí ti kún àkúnwọ́sílẹ̀, nítorí ìkà wọ́n pọ̀. Ogunlọ́gọ̀ wà ní àfonífojì ìdájọ́, nítorí ọjọ́ OLUWA kù sí dẹ̀dẹ̀ níbẹ̀. Oòrùn ati òṣùpá ti ṣókùnkùn, àwọn ìràwọ̀ kò sì tan ìmọ́lẹ̀ mọ́. OLUWA kígbe láti Sioni, ó sọ̀rọ̀ láti Jerusalẹmu; ọ̀run ati ayé mì tìtì, ṣugbọn OLUWA ni ààbò fún àwọn eniyan rẹ̀, òun ni ibi ààbò fún Israẹli.
Joel 3:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti ní àkókò náà, nígbà tí èmi tún mú ìgbèkùn Juda àti Jerusalẹmu padà bọ̀. Èmi yóò kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ pẹ̀lú èmi yóò sì mú wọn wá sí Àfonífojì Jehoṣafati. Èmi yóò sì bá wọn wíjọ́ níbẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn mi, àti nítorí Israẹli ìní mi, tí wọ́n fọ́nká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì pín ilẹ̀ mi. Wọ́n si ti di ìbò fún àwọn ènìyàn mi; wọ́n sì ti fi ọmọdékùnrin kan fún panṣágà obìnrin kan, wọ́n sì ta ọmọdébìnrin kan fún ọtí wáìnì, kí wọ́n kí ó lè mu. “Nísinsin yìí, kí ni ẹ̀yin ní fi mí ṣe Tire àti Sidoni, àti gbogbo ẹ̀yin ẹkún Filistia? Ẹ̀yin yóò ha sàn ẹ̀san fún mi? Bí ẹ̀yin bá sì san ẹ̀san fún mi, ní kánkán àti ní kíákíá ní èmi yóò san ẹ̀san ohun ti ẹ̀yin ṣe padà sórí ara yín. Nítorí tí ẹ̀yin tí mú fàdákà mi àti wúrà mi, ẹ̀yin si tí mú ohun rere dáradára mi lọ sínú tẹmpili yín. Àti àwọn ọmọ Juda, àti àwọn ọmọ Jerusalẹmu ní ẹ̀yin ti tà fún àwọn ará Giriki, kí ẹ̀yin bá à lè sí wọn jìnnà kúrò ní agbègbè ilẹ̀ ìní wọn. “Kíyèsi í, èmi yóò gbé wọ́n dìde kúrò níbi tì ẹ̀yin ti tà wọ́n sí, èmi yóò sì san ẹ̀san ohun ti ẹ ṣe padà sórí ara yín. Èmi yóò si tà àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín sí ọwọ́ àwọn ọmọ Juda, wọ́n yóò sì tà wọ́n fún àwọn ara Sabeani, fún orílẹ̀-èdè kan tí ó jìnnà réré.” Nítorí OLúWA ní o ti sọ ọ. Ẹ kéde èyí ní àárín àwọn kèfèrí; Ẹ dira ogun, ẹ jí àwọn alágbára, Jẹ kí àwọn ajagun kí wọn bẹ̀rẹ̀ ogun, Ẹ fi irin ìtulẹ̀ yín rọ idà, àti dòjé yín rọ ọ̀kọ̀. Jẹ́ kí aláìlera wí pé, “Ara mi le koko.” Ẹ wá kánkán, gbogbo ẹ̀yin kèfèrí láti gbogbo àyíká, kí ẹ sì gbá ara yín jọ yí káàkiri. Níbẹ̀ ní kí o mú àwọn alágbára rẹ sọ̀kalẹ̀, OLúWA. “Ẹ jí, ẹ sì gòkè wá sí Àfonífojì Jehoṣafati ẹ̀yin kèfèrí: nítorí níbẹ̀ ní èmi yóò jókòó láti ṣe ìdájọ́ àwọn kèfèrí yí káàkiri. Ẹ tẹ dòjé bọ̀ ọ́, nítorí ìkórè pọ́n: ẹ wá, ẹ sọ̀kalẹ̀; nítorí ìfúntí kún, nítorí àwọn ọpọ́n kún àkúnwọ́sílẹ̀ nítorí ìwà búburú wọn pọ̀!” Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní àfonífojì ìpinnu, nítorí ọjọ́ OLúWA kù si dẹ̀dẹ̀ ní àfonífojì ìdájọ́. Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣú òkùnkùn, àti àwọn ìràwọ̀ kí yóò tan ìmọ́lẹ̀ wọn mọ́. OLúWA yóò sí ké ramúramù láti Sioni wá, yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jerusalẹmu wá; àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtì Ṣùgbọ́n OLúWA yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀, àti agbára àwọn ọmọ Israẹli.