Joel 2:13-14
Joel 2:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ si fà aiyà nyin ya, kì isi ṣe aṣọ nyin, ẹ si yipadà si Oluwa Ọlọrun nyin, nitoriti o pọ̀ li ore-ọfẹ, o si kún fun ãnu, o lọra lati binu, o si ṣeun pupọ̀, o si ronupiwada ati ṣe buburu. Tali o mọ̀ bi on o yipadà, ki o si ronupiwàda, ki o si fi ibukún silẹ̀ lẹhin rẹ̀; ani ọrẹ-jijẹ ati ọrẹ-mimu fun Oluwa Ọlọrun nyin?
Joel 2:13-14 Yoruba Bible (YCE)
Ìrònúpìwàdà tòótọ́ ni mò ń fẹ́, kì í ṣe pé kí ẹ fa aṣọ yín ya nìkan.” Ẹ yipada sí OLUWA Ọlọrun yín, nítorí olóore-ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni. Kì í yára bínú, Ó kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, a sì máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan. Ó ṣeéṣe kí Ọlọrun ṣàánú, kí ó yí ibinu rẹ̀ pada, kí ó sì tú ibukun rẹ̀ sílẹ̀, kí ẹ lè rú ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu fún OLUWA Ọlọrun yín.
Joel 2:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Ẹ sì fa ọkàn yín ya, kì í sì í ṣe aṣọ yín, ẹ sì yípadà sí OLúWA Ọlọ́run yín, nítorí tí o pọ̀ ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì kún fun àánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì ṣeun púpọ̀, ó sì ronúpìwàdà láti ṣe búburú. Ta ni ó mọ̀ bí òun yóò yípadà, kí o sì ronúpìwàdà, kí ó sì fi ìbùkún sílẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀— àní ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu fún OLúWA Ọlọ́run yín?