Joel 2:1-32

Joel 2:1-32 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹ fun ipè ni Sioni, ẹ si dá idagìri ni oke mimọ́ mi; jẹ ki awọn ará ilẹ na warìri: nitoriti ọjọ Oluwa mbọ̀ wá, nitori o kù si dẹ̀dẹ; Ọjọ òkunkun ati òkudu, ọjọ ikũku ati òkunkun biribiri, bi ọyẹ̀ owurọ̀ ti ilà bò ori awọn oke-nla: enia nla ati alagbara; kò ti isi iru rẹ̀ ri, bẹ̃ni iru rẹ̀ kì yio si mọ lẹhin rẹ̀, titi de ọdun iran de iran. Iná njó niwaju wọn; ọwọ́-iná si njó lẹhin wọn: ilẹ na dàbi ọgbà Edeni niwaju wọn, ati lẹhin wọn bi ahoro ijù; nitõtọ, kò si si ohun ti yio bọ́ lọwọ wọn. Irí wọn dàbi irí awọn ẹṣin; ati bi awọn ẹlẹṣin, bẹ̃ni nwọn o sure. Bi ariwo kẹkẹ́ lori oke ni nwọn o fò, bi ariwo ọwọ́-iná ti o jó koriko gbigbẹ, bi alagbara enia ti a tẹ́ ni itẹ́gun. Li oju wọn, awọn enia yio jẹ irora pupọ̀: gbogbo oju ni yio ṣú dùdu. Nwọn o sare bi awọn alagbara; nwọn o gùn odi bi ọkunrin ologun; olukuluku wọn o si rìn lọ li ọ̀na rẹ̀, nwọn kì yio si bà ọ̀wọ́ wọn jẹ. Bẹ̃ni ẹnikan kì yio tì ẹnikeji rẹ̀; olukuluku wọn o rìn li ọ̀na rẹ̀: nigbati nwọn ba si ṣubu lù idà, nwọn kì o gbọgbẹ́. Nwọn o sure siwa sẹhin ni ilu: nwọn o sure lori odi, nwọn o gùn ori ile; nwọn o gbà oju fèrese wọ̀ inu ile bi olè. Aiye yio mì niwaju wọn; awọn ọrun yio warìri: õrùn ati oṣupa yio ṣu òkunkun, awọn iràwọ yio si fà imọlẹ wọn sẹhìn. Oluwa yio si fọ̀ ohùn rẹ̀ jade niwaju ogun rẹ̀: nitori ibùdo rẹ̀ tobi gidigidi: nitori alagbara li on ti nmu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ; nitori ọjọ Oluwa tobi o si li ẹ̀ru gidigidi; ara tali o le gbà a? Njẹ nitorina nisisiyi, ni Oluwa wi, Ẹ fi gbogbo ọkàn nyin yipada si mi, ati pẹlu ãwẹ̀, ati pẹlu ẹkún, ati pẹlu ọ̀fọ. Ẹ si fà aiyà nyin ya, kì isi ṣe aṣọ nyin, ẹ si yipadà si Oluwa Ọlọrun nyin, nitoriti o pọ̀ li ore-ọfẹ, o si kún fun ãnu, o lọra lati binu, o si ṣeun pupọ̀, o si ronupiwada ati ṣe buburu. Tali o mọ̀ bi on o yipadà, ki o si ronupiwàda, ki o si fi ibukún silẹ̀ lẹhin rẹ̀; ani ọrẹ-jijẹ ati ọrẹ-mimu fun Oluwa Ọlọrun nyin? Ẹ fun ipè ni Sioni, ẹ yà ãwẹ̀ kan si mimọ́, ẹ pè ajọ ti o ni irònu. Ẹ kó awọn enia jọ, ẹ yà ijọ si mimọ́, ẹ pè awọn àgba jọ, ẹ kó awọn ọmọde jọ, ati awọn ti nmu ọmú: jẹ ki ọkọ iyàwo jade kuro ni iyẹ̀wu rẹ̀, ati iyàwo kuro ninu iyẹ̀wu rẹ̀. Jẹ ki awọn alufa, awọn iranṣẹ Oluwa, sọkun lãrin iloro ati pẹpẹ, si jẹ ki wọn wi pe, Dá awọn enia rẹ si, Oluwa, má si ṣe fi iní rẹ fun ẹ̀gan, ti awọn keferi yio fi ma jọba lori wọn: ẽṣe ti nwọn o fi wi ninu awọn enia pe, Ọlọrun wọn há da? Nigbana ni Oluwa yio jowú fun ilẹ rẹ̀, yio si kãnu fun enia rẹ̀. Nitõtọ, Oluwa yio dahùn, yio si wi fun awọn enia rẹ̀ pe, Wò o emi o rán ọkà, ati ọti-waini, ati ororo si nyin, a o si fi wọn tẹ́ nyin lọrùn: emi kì yio si fi nyin ṣe ẹ̀gan mọ lãrin awọn keferi. Ṣugbọn emi o ṣi ogun ariwa nì jinà rére kuro lọdọ nyin, emi o si le e lọ si ilẹ ti o ṣá, ti o si di ahoro, pẹlu oju rẹ̀ si okun ila-õrun, ati ẹhìn rẹ̀ si ipẹkùn okun, õrùn rẹ̀ yio si goke, õrùn buburu rẹ̀ yio si goke, nitoriti o ti ṣe ohun nla. Má bẹ̀ru, iwọ ilẹ; jẹ ki inu rẹ dùn, ki o si yọ̀: nitori Oluwa yio ṣe ohun nla. Ẹ má bẹ̀ru, ẹranko igbẹ: nitori pápa-oko aginju nrú, nitori igi nso eso rẹ̀, igi ọ̀pọtọ ati àjara nso eso ipá wọn. Njẹ jẹ ki inu nyin dùn, ẹnyin ọmọ Sioni, ẹ si yọ̀ ninu Oluwa Ọlọrun nyin; nitoriti o ti fi akọrọ̀ ojò fun nyin bi o ti tọ́, on o si mu ki ojò rọ̀ silẹ fun nyin, akọrọ̀ ati arọ̀kuro ojò ni oṣù ikini. Ati awọn ilẹ ipakà yio kún fun ọkà, ati ọpọ́n wọnni yio ṣàn jade pẹlu ọti-waini ati ororo. Emi o si mu ọdun wọnni padà fun nyin wá, eyi ti ẽṣú on iru kòkoro jewejewe, ati iru kòkoro keji, ati iru kòkoro jewejewe miràn ti fi jẹ, awọn ogun nla mi ti mo rán sãrin nyin. Ẹnyin o si jẹun li ọ̀pọlọpọ, ẹ o si yó, ẹ o si yìn orukọ Oluwa Ọlọrun nyin, ẹniti o fi iyanu ba nyin lò; oju kì o si tì awọn enia mi lai. Ẹnyin o si mọ̀ pe, emi wà lãrin Israeli, ati pe: Emi li Oluwa Ọlọrun nyin, kì iṣe ẹlomiràn: oju kì yio si tì awọn enia mi lai. Yio si ṣe, nikẹhìn emi o tú ẹmi mi jade si ara enia gbogbo; ati awọn ọmọ nyin ọkunrin, ati awọn ọmọ nyin obinrin yio ma ṣotẹlẹ, awọn arugbo nyin yio ma lá alá, awọn ọdọmọkunrin nyin yio ma riran: Ati pẹlu si ara awọn ọmọ-ọdọ ọkunrin, ati si ara awọn ọmọ-ọdọ obinrin, li emi o tú ẹmi mi jade li ọjọ wọnni. Emi o si fi iṣẹ iyanu hàn li ọrun ati li aiye, ẹjẹ̀ ati iná, ati ọwọ̀n ẹ̃fin. A ó sọ õrùn di òkunkun, ati oṣùpá di ẹjẹ̀, ki ọjọ nla ati ẹ̀ru Oluwa to de. Yio si ṣe ẹnikẹni ti o ba ke pè orukọ Oluwa li a o gbàla: nitori li oke Sioni ati ni Jerusalemu ni igbàla yio gbe wà, bi Oluwa ti wi, ati ninu awọn iyokù ti Oluwa yio pè.

Joel 2:1-32 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ fun fèrè ní Sioni, ẹ kéde ìdágìrì lórí òkè mímọ́ mi. Kí gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà wárìrì, nítorí ọjọ́ OLUWA ń bọ̀, ó sì ti dé tán. Yóo jẹ́ ọjọ́ òkùnkùn ati ìbànújẹ́, ọjọ́ ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri. Àwọn ọmọ ogun yóo bo gbogbo òkè ńlá, bí ìgbà tí òkùnkùn bá ń ṣú bọ̀. Irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí ní ìgbà àtijọ́, bẹ́ẹ̀ ni irú rẹ̀ kò sì tún ní ṣẹlẹ̀ mọ́ títí lae. Iná ń jó àjórun níwájú wọn, ahọ́n iná ń yọ lálá lẹ́yìn wọn. Ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Edẹni níwájú wọn, ṣugbọn lẹ́yìn wọn, ó dàbí aṣálẹ̀ tí ó ti di ahoro, kò sì sí ohun tí yóo bọ́ lọ́wọ́ wọn. Ìrísí wọn dàbí ìrísí ẹṣin, wọ́n sì ń sáré bí ẹṣin tí ń lọ ojú ogun. Ìró wọn dàbí ìró kẹ̀kẹ́ ogun, wọ́n ń bẹ́ lórí àwọn òkè ńlá. Ìró wọn dàbí ìró iná tí ń jó pápá, bí ìgbà tí àwọn alágbára ọmọ ogun múra fún ogun. Ìdààmú bá àwọn orílẹ̀-èdè tí ó bá ti fojú kàn wọ́n, gbogbo ọkàn á rẹ̀wẹ̀sì. Wọ́n ń sáré bí akọni, wọ́n ń fo ògiri bí ọmọ ogun. Wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́, ẹnikẹ́ni kò sì yà kúrò ní ọ̀nà tirẹ̀. Wọn kò fi ara gbún ara wọn, olukuluku ń lọ ní ọ̀nà tirẹ̀; wọ́n kọlu àwọn nǹkan ààbò láìní ìdádúró. Wọ́n ń gun odi ìlú, wọ́n ń sáré lórí odi. Wọ́n ń gun orí ilé wọlé, wọ́n gba ojú fèrèsé bẹ́ sinu ọ̀dẹ̀dẹ̀ bí olè. Ilẹ̀ ń mì tìtì níwájú wọn, ọ̀run sì ń wárìrì, oòrùn, òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀ ṣókùnkùn. OLUWA sọ̀rọ̀ níwájú àwọn ọmọ ogun rẹ̀, nítorí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pọ̀ lọpọlọpọ, alágbára ni ẹni tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Ọjọ́ ńlá ati ọjọ́ ẹ̀rù ni ọjọ́ OLUWA! Ta ló lè faradà á? OLUWA ní, “Ẹ yipada sí mi tọkàntọkàn nisinsinyii, pẹlu ààwẹ̀, ẹkún ati ìkẹ́dùn, Ìrònúpìwàdà tòótọ́ ni mò ń fẹ́, kì í ṣe pé kí ẹ fa aṣọ yín ya nìkan.” Ẹ yipada sí OLUWA Ọlọrun yín, nítorí olóore-ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni. Kì í yára bínú, Ó kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, a sì máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan. Ó ṣeéṣe kí Ọlọrun ṣàánú, kí ó yí ibinu rẹ̀ pada, kí ó sì tú ibukun rẹ̀ sílẹ̀, kí ẹ lè rú ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu fún OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ fọn fèrè ní òkè Sioni, ẹ kéde ààwẹ̀ kí ẹ sì pe àpéjọ. Ẹ pe gbogbo eniyan jọ, kí ẹ sì ya ìjọ eniyan sí mímọ́. Ẹ pe àwọn àgbààgbà jọ, ẹ kó àwọn ọmọde ati àwọn ọmọ ọwọ́ jọ. Kí ọkọ iyawo jáde láti inú yàrá rẹ̀, kí iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé náà jáde ninu yàrá rẹ̀. Kí àwọn alufaa, àwọn iranṣẹ Ọlọrun, sọkún láàrin ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ati pẹpẹ ìrúbọ. Kí wọ́n wí pé “OLUWA, dá àwọn eniyan rẹ sí, má sì sọ ilẹ̀ rẹ di ohun ẹ̀gàn ati ohun ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Má jẹ́ kí àwọn eniyan láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù bèèrè pé, ‘Níbo ni Ọlọrun wọn wà?’ ” Nígbà náà ni ara bẹ̀rẹ̀ sí ta OLUWA nítorí ilẹ̀ rẹ̀, ó sì ṣàánú fún àwọn eniyan rẹ̀. OLUWA dá àwọn eniyan rẹ̀ lóhùn pé, “Wò ó! N óo fun yín ní ọkà, waini ati òróró, ẹ óo ní ànítẹ́rùn. N kò ní sọ yín di ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́. N óo kó àwọn eṣú láti ìhà àríwá jìnnà kúrò lọ́dọ̀ yín, n óo lé wọn lọ sinu aṣálẹ̀ níbi tí kò sí nǹkankan. N óo lé àwọn tí wọ́n wà níwájú lọ sí inú òkun, ní apá ìlà oòrùn, n óo sì lé àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn lọ sí inú òkun, ní apá ìwọ̀ oòrùn. Òkú wọn yóo máa rùn; n óo pa wọ́n run nítorí ibi ńlá tí wọ́n ṣe. Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀, jẹ́ kí inú rẹ máa dùn, kí o sì máa yọ̀, nítorí OLUWA ti ṣe nǹkan ńlá. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ẹranko inú igbó, nítorí ewéko gbogbo ni ó tutù, igi gbogbo ti so èso, igi ọ̀pọ̀tọ́ ati ọgbà àjàrà sì ti so jìnwìnnì. “Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni, kí inú yín máa dùn ninu OLUWA Ọlọrun yín; nítorí ó ti da yín láre, ó ti fun yín ní àkọ́rọ̀ òjò, ó ti rọ ọpọlọpọ òjò fun yín: ati òjò àkọ́rọ̀, ati àrọ̀kẹ́yìn òjò, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀. Gbogbo ibi ìpakà ni yóo kún fún ọkà, ìkòkò waini ati ti òróró yín yóo kún àkúnwọ́sílẹ̀. Gbogbo ohun tí ẹ pàdánù ní àwọn ọdún tí àwọn ọmọ ogun mi tí mo rán si yín ti jẹ oko yín; ati èyí tí eṣú wẹẹrẹ jẹ, ati èyí tí eṣú ńláńlá jẹ, gbogbo rẹ̀ ni n óo dá pada fun yín. Ẹ óo jẹ oúnjẹ àjẹyó ati àjẹtẹ́rùn, ẹ óo sì yin orúkọ OLUWA Ọlọrun yín, tí ó ṣe ohun ìyanu ńlá fun yín, ojú kò sì ní ti àwọn eniyan mi mọ́ lae. Ẹ óo mọ̀ pé mo wà láàrin Israẹli; ati pé èmi OLUWA ni Ọlọrun yín, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi mọ́. Ojú kò sì ní ti àwọn eniyan mi mọ́ lae. “Lẹ́yìn náà, nígbà tí ó bá yá, n óo tú ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo eniyan, àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin yín yóo máa sọ àsọtẹ́lẹ̀, àwọn àgbààgbà yín yóo máa lá àlá, àwọn ọdọmọkunrin yín yóo sì máa ríran. Bákan náà, nígbà tí àkókò bá tó, n óo tú ẹ̀mí mi jáde sára àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin yín. “Ìtàjẹ̀sílẹ̀ yóo pọ̀, n óo sì fi iná, ati òpó èéfín sí ojú ọ̀run, ati sórí ilẹ̀ ayé; yóo jẹ́ ìkìlọ̀ fun yín. Oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá yóo pọ́n rẹ̀bẹ̀tẹ̀ bí ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ OLUWA tí ó lẹ́rù tó dé. Ṣugbọn gbogbo àwọn tí wọ́n bá ké pe orúkọ OLUWA ni a óo gbàlà. Àwọn kan yóo sá àsálà ní òkè Sioni, ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ, àwọn tí OLUWA pè yóo sì wà lára àwọn tí wọn yóo sá àsálà.

Joel 2:1-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ fun ìpè ní Sioni, ẹ sì fún ìpè ìdágìrì ní òkè mímọ́ mi. Jẹ́ kí àwọn ará ilẹ̀ náà wárìrì, nítorí tí ọjọ́ OLúWA ń bọ̀ wá, nítorí ó kù sí dẹ̀dẹ̀. Ọjọ́ òkùnkùn àti ìrọ́kẹ̀kẹ̀, ọjọ́ ìkùùkuu àti òkùnkùn biribiri, Bí ọyẹ́ òwúrọ̀ ti í la bo orí àwọn òkè ńlá: àwọn ènìyàn ńlá àti alágbára; ya dé, ti kó ti ì sí irú rẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni irú rẹ̀ kì yóò sí mọ́ lẹ́yìn rẹ̀, títí dé ọdún ìran dé ìran. Iná ń jó níwájú wọ́n; ọwọ́ iná sì ń jó lẹ́yìn wọn: Ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Edeni níwájú wọn, àti lẹ́yìn wọn bí ahoro ijù; nítòótọ́, kò sì sí ohun tí yóò bọ́ lọ́wọ́ wọn. Ìrí wọn dàbí ìrí àwọn ẹṣin; wọ́n ń sáré lọ bí àwọn ẹlẹ́ṣin ogun Bí ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ni wọn ń fo ní orí òkè bí ariwo ọ̀wọ́-iná tí ń jó koríko gbígbẹ, bí akọni ènìyàn tí a kójọ fún ogun. Ní ojú wọn, àwọn ènìyàn yóò jẹ ìrora púpọ̀: gbogbo ojú ní yóò ṣú dudu. Wọn yóò sáré bi àwọn alágbára; wọn yóò gùn odi bí ọkùnrin ológun; olúkúlùkù wọn yóò sì rìn lọ ní ọ̀nà rẹ̀, wọn kì yóò sì yà kúrò ni ọ̀nà wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò kọlu ẹnìkejì rẹ̀; olúkúlùkù wọn yóò rìn ní ọ̀nà rẹ̀: nígbà tí wọn bá sì ṣubú lù idà wọn kì yóò gbọgbẹ́. Wọn yóò sáré síwá sẹ́yìn ní ìlú; wọn yóò súré lórí odi, wọn yóò gùn orí ilé; wọn yóò gbà ojú fèrèsé wọ̀ inú ilé bí olè. Ayé yóò mì níwájú wọn; àwọn ọ̀run yóò wárìrì; oòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn, àwọn ìràwọ̀ yóò sì fà ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn. OLúWA yóò sì bú ramúramù jáde níwájú ogun rẹ̀: nítorí ibùdó rẹ̀ tóbi gidigidi; nítorí alágbára ní òun, tí n mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ; nítorí ọjọ́ OLúWA tóbi ó sì ní ẹ̀rù gidigidi; ara ta ni ó lè gbà á? “Ǹjẹ́ nítorí náà nísinsin yìí,” ni OLúWA wí, “Ẹ fi gbogbo ọkàn yín yípadà sí mi, àti pẹ̀lú àwẹ̀, àti pẹ̀lú ẹkún, àti pẹ̀lú ọ̀fọ̀.” Ẹ sì fa ọkàn yín ya, kì í sì í ṣe aṣọ yín, ẹ sì yípadà sí OLúWA Ọlọ́run yín, nítorí tí o pọ̀ ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì kún fun àánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì ṣeun púpọ̀, ó sì ronúpìwàdà láti ṣe búburú. Ta ni ó mọ̀ bí òun yóò yípadà, kí o sì ronúpìwàdà, kí ó sì fi ìbùkún sílẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀— àní ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu fún OLúWA Ọlọ́run yín? Ẹ fún ìpè ní Sioni, ẹ ya àwẹ̀ kan sí mímọ́, ẹ pe àjọ tí ó ni ìrònú. Ẹ kó àwọn ènìyàn jọ, ẹ ya ìjọ sí mímọ́; ẹ pe àwọn àgbàgbà jọ, ẹ kó àwọn ọmọdé jọ, àti àwọn tí ń mú ọmú: jẹ kí ọkọ ìyàwó kúrò nínú ìyẹ̀wù rẹ̀. Kí ìyàwó sì kúrò nínú iyàrá rẹ̀ Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ OLúWA, sọkún láàrín ìloro àti pẹpẹ. Sí jẹ́ kí wọn wí pé, “Dá àwọn ènìyàn rẹ sí, OLúWA. Má sì ṣe fi ìní rẹ fun ẹ̀gàn, tí yóò sì di òwe ní àárín àwọn kèfèrí. Èéṣe tí wọn yóò fi wí láàrín àwọn ènìyàn pé, ‘Ọlọ́run wọn ha da?’ ” Nígbà náà ní OLúWA yóò jowú fún ilẹ̀ rẹ̀, yóò sì káàánú fún ènìyàn rẹ̀. Nítòótọ́, OLúWA yóò dá wọn lóhùn: “Yóò sì wí fun àwọn ènìyàn rẹ̀ pé, Wò ó èmi yóò rán ọkà, àti ọtí wáìnì tuntun, àti òróró sí i yín, a ó sì fi wọn tẹ́ yín lọ́rùn: èmi kì yóò sì fi yín ṣe ẹ̀gàn mọ́ láàrín àwọn aláìkọlà. “Ṣùgbọ́n èmi yóò lé ogun àríwá jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ yín, èmi yóò sì lé e lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣá, tí ó sì di ahoro, pẹ̀lú ojú rẹ̀ sí Òkun ìlà-oòrùn, àti ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìwọ̀-oòrùn Òkun. Òórùn rẹ̀ yóò sì gòkè, òórùn búburú rẹ̀ yóò sì gòkè.” Nítòótọ́ ó ti ṣe ohun ńlá. Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀; jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn kí o sì yọ̀, nítorí OLúWA ti ṣe ohun ńlá, Ẹ má bẹ̀rù, ẹranko igbó, nítorí pápá oko aginjù ń rú, nítorí igi ń so èso rẹ̀, igi ọ̀pọ̀tọ́ àti àjàrà ń so èso ọ̀rọ̀ wọn. Ẹ jẹ́ kí inú yín dùn, ẹ̀yin ọmọ Sioni, ẹ sì yọ̀ nínú OLúWA Ọlọ́run yín, nítorí ó ti fi àkọ́rọ̀ òjò fún yín bí ó ti tọ́, Òun ti mú kí òjò rọ̀ sílẹ̀ fún un yín, àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní oṣù kìn-ín-ní. Àwọn ilẹ̀ ìpakà yóò kún fún ọkà; àti ọpọ́n wọn nì yóò sàn jáde pẹ̀lú ọtí wáìnì tuntun àti òróró. “Èmi yóò sì mú ọdún wọ̀nyí ti eṣú jẹ run padà fún un yín. Èyí tí eṣú agénijẹ àti eṣú jewéjewé ọwọ́ eṣú agénijẹ àti kòkòrò ajẹnirun mìíràn ti fi jẹ àwọn ogun ńlá mi tí mo rán sí àárín yín. Ẹ̀yin yóò ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti jẹ, títí ẹ̀yin yóò fi yó ẹ ó sì yín orúkọ OLúWA Ọlọ́run yín, ẹni tí ó fi ìyanu bá yín lò; ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mi láéláé. Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, èmi wà láàrín Israẹli, àti pé; Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín, àti pé kò sí ẹlòmíràn: Ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mí láéláé. OLúWA “Yóò sì ṣe níkẹyìn ọjọ́, èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mí sí ara ènìyàn gbogbo; àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀, àwọn arúgbó yín yóò máa lá àlá, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò máa ríran. Àti pẹ̀lú sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ọkùnrin, àti sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin, ní èmi yóò tú ẹ̀mí mí jáde ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì. Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn ní ọrun àti ní ayé, ẹ̀jẹ̀ àti iná, àti ọ̀wọ́n èéfín. A á sọ oòrùn di òkùnkùn, àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ẹ̀rù OLúWA tó dé. Yóò sí ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó ba ké pè orúkọ OLúWA ní a ó gbàlà: nítorí ní òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu ní ìgbàlà yóò gbé wà, bí OLúWA ti wí, àti nínú àwọn ìyókù tí OLúWA yóò pè.