Joel 2:1-17

Joel 2:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹ fun ipè ni Sioni, ẹ si dá idagìri ni oke mimọ́ mi; jẹ ki awọn ará ilẹ na warìri: nitoriti ọjọ Oluwa mbọ̀ wá, nitori o kù si dẹ̀dẹ; Ọjọ òkunkun ati òkudu, ọjọ ikũku ati òkunkun biribiri, bi ọyẹ̀ owurọ̀ ti ilà bò ori awọn oke-nla: enia nla ati alagbara; kò ti isi iru rẹ̀ ri, bẹ̃ni iru rẹ̀ kì yio si mọ lẹhin rẹ̀, titi de ọdun iran de iran. Iná njó niwaju wọn; ọwọ́-iná si njó lẹhin wọn: ilẹ na dàbi ọgbà Edeni niwaju wọn, ati lẹhin wọn bi ahoro ijù; nitõtọ, kò si si ohun ti yio bọ́ lọwọ wọn. Irí wọn dàbi irí awọn ẹṣin; ati bi awọn ẹlẹṣin, bẹ̃ni nwọn o sure. Bi ariwo kẹkẹ́ lori oke ni nwọn o fò, bi ariwo ọwọ́-iná ti o jó koriko gbigbẹ, bi alagbara enia ti a tẹ́ ni itẹ́gun. Li oju wọn, awọn enia yio jẹ irora pupọ̀: gbogbo oju ni yio ṣú dùdu. Nwọn o sare bi awọn alagbara; nwọn o gùn odi bi ọkunrin ologun; olukuluku wọn o si rìn lọ li ọ̀na rẹ̀, nwọn kì yio si bà ọ̀wọ́ wọn jẹ. Bẹ̃ni ẹnikan kì yio tì ẹnikeji rẹ̀; olukuluku wọn o rìn li ọ̀na rẹ̀: nigbati nwọn ba si ṣubu lù idà, nwọn kì o gbọgbẹ́. Nwọn o sure siwa sẹhin ni ilu: nwọn o sure lori odi, nwọn o gùn ori ile; nwọn o gbà oju fèrese wọ̀ inu ile bi olè. Aiye yio mì niwaju wọn; awọn ọrun yio warìri: õrùn ati oṣupa yio ṣu òkunkun, awọn iràwọ yio si fà imọlẹ wọn sẹhìn. Oluwa yio si fọ̀ ohùn rẹ̀ jade niwaju ogun rẹ̀: nitori ibùdo rẹ̀ tobi gidigidi: nitori alagbara li on ti nmu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ; nitori ọjọ Oluwa tobi o si li ẹ̀ru gidigidi; ara tali o le gbà a? Njẹ nitorina nisisiyi, ni Oluwa wi, Ẹ fi gbogbo ọkàn nyin yipada si mi, ati pẹlu ãwẹ̀, ati pẹlu ẹkún, ati pẹlu ọ̀fọ. Ẹ si fà aiyà nyin ya, kì isi ṣe aṣọ nyin, ẹ si yipadà si Oluwa Ọlọrun nyin, nitoriti o pọ̀ li ore-ọfẹ, o si kún fun ãnu, o lọra lati binu, o si ṣeun pupọ̀, o si ronupiwada ati ṣe buburu. Tali o mọ̀ bi on o yipadà, ki o si ronupiwàda, ki o si fi ibukún silẹ̀ lẹhin rẹ̀; ani ọrẹ-jijẹ ati ọrẹ-mimu fun Oluwa Ọlọrun nyin? Ẹ fun ipè ni Sioni, ẹ yà ãwẹ̀ kan si mimọ́, ẹ pè ajọ ti o ni irònu. Ẹ kó awọn enia jọ, ẹ yà ijọ si mimọ́, ẹ pè awọn àgba jọ, ẹ kó awọn ọmọde jọ, ati awọn ti nmu ọmú: jẹ ki ọkọ iyàwo jade kuro ni iyẹ̀wu rẹ̀, ati iyàwo kuro ninu iyẹ̀wu rẹ̀. Jẹ ki awọn alufa, awọn iranṣẹ Oluwa, sọkun lãrin iloro ati pẹpẹ, si jẹ ki wọn wi pe, Dá awọn enia rẹ si, Oluwa, má si ṣe fi iní rẹ fun ẹ̀gan, ti awọn keferi yio fi ma jọba lori wọn: ẽṣe ti nwọn o fi wi ninu awọn enia pe, Ọlọrun wọn há da?

Joel 2:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ fun fèrè ní Sioni, ẹ kéde ìdágìrì lórí òkè mímọ́ mi. Kí gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà wárìrì, nítorí ọjọ́ OLUWA ń bọ̀, ó sì ti dé tán. Yóo jẹ́ ọjọ́ òkùnkùn ati ìbànújẹ́, ọjọ́ ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri. Àwọn ọmọ ogun yóo bo gbogbo òkè ńlá, bí ìgbà tí òkùnkùn bá ń ṣú bọ̀. Irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí ní ìgbà àtijọ́, bẹ́ẹ̀ ni irú rẹ̀ kò sì tún ní ṣẹlẹ̀ mọ́ títí lae. Iná ń jó àjórun níwájú wọn, ahọ́n iná ń yọ lálá lẹ́yìn wọn. Ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Edẹni níwájú wọn, ṣugbọn lẹ́yìn wọn, ó dàbí aṣálẹ̀ tí ó ti di ahoro, kò sì sí ohun tí yóo bọ́ lọ́wọ́ wọn. Ìrísí wọn dàbí ìrísí ẹṣin, wọ́n sì ń sáré bí ẹṣin tí ń lọ ojú ogun. Ìró wọn dàbí ìró kẹ̀kẹ́ ogun, wọ́n ń bẹ́ lórí àwọn òkè ńlá. Ìró wọn dàbí ìró iná tí ń jó pápá, bí ìgbà tí àwọn alágbára ọmọ ogun múra fún ogun. Ìdààmú bá àwọn orílẹ̀-èdè tí ó bá ti fojú kàn wọ́n, gbogbo ọkàn á rẹ̀wẹ̀sì. Wọ́n ń sáré bí akọni, wọ́n ń fo ògiri bí ọmọ ogun. Wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́, ẹnikẹ́ni kò sì yà kúrò ní ọ̀nà tirẹ̀. Wọn kò fi ara gbún ara wọn, olukuluku ń lọ ní ọ̀nà tirẹ̀; wọ́n kọlu àwọn nǹkan ààbò láìní ìdádúró. Wọ́n ń gun odi ìlú, wọ́n ń sáré lórí odi. Wọ́n ń gun orí ilé wọlé, wọ́n gba ojú fèrèsé bẹ́ sinu ọ̀dẹ̀dẹ̀ bí olè. Ilẹ̀ ń mì tìtì níwájú wọn, ọ̀run sì ń wárìrì, oòrùn, òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀ ṣókùnkùn. OLUWA sọ̀rọ̀ níwájú àwọn ọmọ ogun rẹ̀, nítorí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pọ̀ lọpọlọpọ, alágbára ni ẹni tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Ọjọ́ ńlá ati ọjọ́ ẹ̀rù ni ọjọ́ OLUWA! Ta ló lè faradà á? OLUWA ní, “Ẹ yipada sí mi tọkàntọkàn nisinsinyii, pẹlu ààwẹ̀, ẹkún ati ìkẹ́dùn, Ìrònúpìwàdà tòótọ́ ni mò ń fẹ́, kì í ṣe pé kí ẹ fa aṣọ yín ya nìkan.” Ẹ yipada sí OLUWA Ọlọrun yín, nítorí olóore-ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni. Kì í yára bínú, Ó kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, a sì máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan. Ó ṣeéṣe kí Ọlọrun ṣàánú, kí ó yí ibinu rẹ̀ pada, kí ó sì tú ibukun rẹ̀ sílẹ̀, kí ẹ lè rú ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu fún OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ fọn fèrè ní òkè Sioni, ẹ kéde ààwẹ̀ kí ẹ sì pe àpéjọ. Ẹ pe gbogbo eniyan jọ, kí ẹ sì ya ìjọ eniyan sí mímọ́. Ẹ pe àwọn àgbààgbà jọ, ẹ kó àwọn ọmọde ati àwọn ọmọ ọwọ́ jọ. Kí ọkọ iyawo jáde láti inú yàrá rẹ̀, kí iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé náà jáde ninu yàrá rẹ̀. Kí àwọn alufaa, àwọn iranṣẹ Ọlọrun, sọkún láàrin ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ati pẹpẹ ìrúbọ. Kí wọ́n wí pé “OLUWA, dá àwọn eniyan rẹ sí, má sì sọ ilẹ̀ rẹ di ohun ẹ̀gàn ati ohun ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Má jẹ́ kí àwọn eniyan láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù bèèrè pé, ‘Níbo ni Ọlọrun wọn wà?’ ”

Joel 2:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ fun ìpè ní Sioni, ẹ sì fún ìpè ìdágìrì ní òkè mímọ́ mi. Jẹ́ kí àwọn ará ilẹ̀ náà wárìrì, nítorí tí ọjọ́ OLúWA ń bọ̀ wá, nítorí ó kù sí dẹ̀dẹ̀. Ọjọ́ òkùnkùn àti ìrọ́kẹ̀kẹ̀, ọjọ́ ìkùùkuu àti òkùnkùn biribiri, Bí ọyẹ́ òwúrọ̀ ti í la bo orí àwọn òkè ńlá: àwọn ènìyàn ńlá àti alágbára; ya dé, ti kó ti ì sí irú rẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni irú rẹ̀ kì yóò sí mọ́ lẹ́yìn rẹ̀, títí dé ọdún ìran dé ìran. Iná ń jó níwájú wọ́n; ọwọ́ iná sì ń jó lẹ́yìn wọn: Ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Edeni níwájú wọn, àti lẹ́yìn wọn bí ahoro ijù; nítòótọ́, kò sì sí ohun tí yóò bọ́ lọ́wọ́ wọn. Ìrí wọn dàbí ìrí àwọn ẹṣin; wọ́n ń sáré lọ bí àwọn ẹlẹ́ṣin ogun Bí ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ni wọn ń fo ní orí òkè bí ariwo ọ̀wọ́-iná tí ń jó koríko gbígbẹ, bí akọni ènìyàn tí a kójọ fún ogun. Ní ojú wọn, àwọn ènìyàn yóò jẹ ìrora púpọ̀: gbogbo ojú ní yóò ṣú dudu. Wọn yóò sáré bi àwọn alágbára; wọn yóò gùn odi bí ọkùnrin ológun; olúkúlùkù wọn yóò sì rìn lọ ní ọ̀nà rẹ̀, wọn kì yóò sì yà kúrò ni ọ̀nà wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò kọlu ẹnìkejì rẹ̀; olúkúlùkù wọn yóò rìn ní ọ̀nà rẹ̀: nígbà tí wọn bá sì ṣubú lù idà wọn kì yóò gbọgbẹ́. Wọn yóò sáré síwá sẹ́yìn ní ìlú; wọn yóò súré lórí odi, wọn yóò gùn orí ilé; wọn yóò gbà ojú fèrèsé wọ̀ inú ilé bí olè. Ayé yóò mì níwájú wọn; àwọn ọ̀run yóò wárìrì; oòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn, àwọn ìràwọ̀ yóò sì fà ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn. OLúWA yóò sì bú ramúramù jáde níwájú ogun rẹ̀: nítorí ibùdó rẹ̀ tóbi gidigidi; nítorí alágbára ní òun, tí n mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ; nítorí ọjọ́ OLúWA tóbi ó sì ní ẹ̀rù gidigidi; ara ta ni ó lè gbà á? “Ǹjẹ́ nítorí náà nísinsin yìí,” ni OLúWA wí, “Ẹ fi gbogbo ọkàn yín yípadà sí mi, àti pẹ̀lú àwẹ̀, àti pẹ̀lú ẹkún, àti pẹ̀lú ọ̀fọ̀.” Ẹ sì fa ọkàn yín ya, kì í sì í ṣe aṣọ yín, ẹ sì yípadà sí OLúWA Ọlọ́run yín, nítorí tí o pọ̀ ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì kún fun àánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì ṣeun púpọ̀, ó sì ronúpìwàdà láti ṣe búburú. Ta ni ó mọ̀ bí òun yóò yípadà, kí o sì ronúpìwàdà, kí ó sì fi ìbùkún sílẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀— àní ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu fún OLúWA Ọlọ́run yín? Ẹ fún ìpè ní Sioni, ẹ ya àwẹ̀ kan sí mímọ́, ẹ pe àjọ tí ó ni ìrònú. Ẹ kó àwọn ènìyàn jọ, ẹ ya ìjọ sí mímọ́; ẹ pe àwọn àgbàgbà jọ, ẹ kó àwọn ọmọdé jọ, àti àwọn tí ń mú ọmú: jẹ kí ọkọ ìyàwó kúrò nínú ìyẹ̀wù rẹ̀. Kí ìyàwó sì kúrò nínú iyàrá rẹ̀ Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ OLúWA, sọkún láàrín ìloro àti pẹpẹ. Sí jẹ́ kí wọn wí pé, “Dá àwọn ènìyàn rẹ sí, OLúWA. Má sì ṣe fi ìní rẹ fun ẹ̀gàn, tí yóò sì di òwe ní àárín àwọn kèfèrí. Èéṣe tí wọn yóò fi wí láàrín àwọn ènìyàn pé, ‘Ọlọ́run wọn ha da?’ ”