Joel 1:14-20
Joel 1:14-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ yà àwẹ kan si mimọ́, ẹ pè ajọ kan ti o ni irònu, ẹ pè awọn agbà, ati gbogbo awọn ará ilẹ na jọ si ile Oluwa Ọlọrun nyin, ki ẹ si kepe Oluwa, A! fun ọjọ na, nitori ọjọ Oluwa kù si dẹ̀dẹ, ati bi iparun lati ọwọ́ Olodumare ni yio de. A kò ha ké onjẹ kuro niwaju oju wa, ayọ̀ ati inu didùn kuro ninu ile Ọlọrun wa? Irugbìn bajẹ ninu ebè wọn, a sọ aká di ahoro, a wó abà palẹ; nitoriti a mu ọ̀ka rọ. Awọn ẹranko ti nkerora to! awọn agbo-ẹran dãmu, nitoriti nwọn kò ni papa oko; nitõtọ, a sọ awọn agbo agùtan di ahoro. Oluwa, si ọ li emi o ké, nitori iná ti run pápa oko tutú aginju, ọwọ́ iná si ti jo gbogbo igi igbẹ. Awọn ẹranko igbẹ gbé oju soke si ọ pẹlu: nitoriti awọn iṣàn omi gbẹ, iná si ti jó awọn pápa oko aginju run.
Joel 1:14-20 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ kéde ààwẹ̀, kí ẹ sì pe àpèjọ. Ẹ pe àwọn àgbààgbà, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà jọ sí ilé OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì kígbe pe OLUWA. Ó ṣe! Ọjọ́ náà ń bọ̀, ọjọ́ OLUWA dé tán! Ọjọ́ náà yóo dé bí ọjọ́ ìparun láti ọ̀dọ̀ Olodumare. A ti gba oúnjẹ lẹ́nu yín, níṣojú yín, bẹ́ẹ̀ ni a gba ayọ̀ ati inú dídùn kúrò ní ilé Ọlọrun wa. Irúgbìn díbàjẹ́ sinu ebè, àwọn ilé ìṣúra ti di ahoro, àwọn àká ti wó lulẹ̀, nítorí kò sí ọkà láti kó sinu wọn mọ́. Àwọn ẹran ọ̀sìn ń kérora, àwọn agbo mààlúù dààmú, nítorí pé kò sí pápá oko fún wọn; àwọn agbo aguntan pàápàá dààmú. Ìwọ ni mo kígbe pè, OLUWA, nítorí iná ti jó gbogbo pápá oko run, ó sì ti jó gbogbo igi oko run. Àwọn ẹranko ìgbẹ́ pàápàá ń kígbe sí ọ, Ọlọrun, nítorí gbogbo àwọn odò ti gbẹ tán, àwọn pápá oko sì ti jóná.
Joel 1:14-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ yà àwẹ̀ kan sí mímọ́, ẹ pe àjọ kan tí o ní ìrònú, ẹ pe àwọn àgbàgbà, àti gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà jọ sí ilé OLúWA Ọlọ́run yín, kí ẹ sí ké pe OLúWA. A! Fún ọjọ́ náà, nítorí ọjọ́ OLúWA kù sí dẹ̀dẹ̀, yóò de bí ìparun láti ọwọ́ Olódùmarè. A kò ha ké oúnjẹ kúrò níwájú ojú wá yìí, ayọ̀ àti inú dídùn kúrò nínú ilé Ọlọ́run wá? Irúgbìn bàjẹ́ nínú ebè wọn, a sọ àká di ahoro, a wó àká palẹ̀; nítorí tí a mú ọkà rọ. Àwọn ẹranko tí ń kérora tó! Àwọn agbo ẹran dààmú, nítorí tí wọ́n kò ni pápá oko; nítòótọ́, àwọn agbo àgùntàn jìyà. OLúWA, sí ọ ni èmi o ké pè, nítorí iná tí run pápá oko tútù aginjù, ọwọ́ iná sí ti jó gbogbo igi igbó. Àwọn ẹranko igbó gbé ojú sókè sí ọ pẹ̀lú: nítorí tí àwọn ìṣàn omi gbẹ, iná sí ti jó àwọn pápá oko aginjù run.