Joel 1:13-14
Joel 1:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ dì ara nyin li amùre, si pohùnrére ẹkún ẹnyin alufa: ẹ hu, ẹnyin iranṣẹ pẹpẹ: ẹ wá, fi gbogbo oru dùbulẹ ninu aṣọ-ọ̀fọ, ẹnyin iranṣẹ Ọlọrun mi: nitori ti a dá ọrẹ-jijẹ, ati ọrẹ-mimu duro ni ile Ọlọrun nyin. Ẹ yà àwẹ kan si mimọ́, ẹ pè ajọ kan ti o ni irònu, ẹ pè awọn agbà, ati gbogbo awọn ará ilẹ na jọ si ile Oluwa Ọlọrun nyin, ki ẹ si kepe Oluwa
Joel 1:13-14 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ sì sọkún, ẹ̀yin alufaa, ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin tí ẹ̀ ǹ ṣiṣẹ́ ní ibi pẹpẹ ìrúbọ. Ẹ̀yin òjíṣẹ́ Ọlọrun mi, ẹ wọlé, kí ẹ sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora sùn, nítorí a ti dáwọ́ ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu dúró ní ilé Ọlọrun yín. Ẹ kéde ààwẹ̀, kí ẹ sì pe àpèjọ. Ẹ pe àwọn àgbààgbà, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà jọ sí ilé OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì kígbe pe OLUWA.
Joel 1:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ di ara yín ni àmùrè, sí pohùnréré ẹkún ẹ̀yin àlùfáà: ẹ pohùnréré ẹkún, ẹ̀yin ìránṣẹ́ pẹpẹ: ẹ wá, fi gbogbo òru dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run mi: nítorí tí a dá ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu dúró ní ilé Ọlọ́run yín. Ẹ yà àwẹ̀ kan sí mímọ́, ẹ pe àjọ kan tí o ní ìrònú, ẹ pe àwọn àgbàgbà, àti gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà jọ sí ilé OLúWA Ọlọ́run yín, kí ẹ sí ké pe OLúWA.