Job 9:1-20

Job 9:1-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

JOBU si dahùn o si wipe, Emi mọ̀ pe bẹ̃ni nitõtọ! bawo li enia yio ha ti ṣe alare niwaju Ọlọrun? Bi o ba ṣepe yio ba a jà, on kì yio lè idá a lohùn kan ninu ẹgbẹrun ọ̀ran. Ọlọgbọ́n-ninu ati alagbara ni ipá li on; tali o ṣagidi si i, ti o si gbè fun u ri? Ẹniti o ṣi okè ni idi, ti nwọn kò si mọ̀: ti o tari wọn ṣubu ni ibinu rẹ̀. Ti o mì ilẹ aiye tìti kuro ni ipò rẹ̀, ọwọ̀n rẹ̀ si mì tìti. Ti o paṣẹ fun õrùn, ti on kò si là, ti o si dí irawọ̀ mọ́. On nikanṣoṣo li o na oju ọrun lọ, ti o si nrìn lori ìgbì okun. Ẹniti o da irawọ̀ Arketuru, Orioni ati Pleiade ati iyàra pipọ ti gusu. Ẹniti nṣe ohun ti o tobi jù awari lọ, ani ohun iyanu laini iye. Kiyesi i, on kọja lọ li ẹ̀ba ọdọ mi, emi kò si ri i, o si kọja siwaju, bẹ̃li emi kò ri oju rẹ̀. Kiyesi i, o jãgbà lọ, tani yio fa a pada? tani yio bi i pe, kini iwọ nṣe nì? Ọlọrun kò ni fà ibinu rẹ̀ sẹhin, awọn oniranlọwọ ìgberaga a si tẹriba labẹ rẹ̀. Ambọtori emi ti emi o fi dá a lohùn, ti emi o fi má ṣa ọ̀rọ awawì mi ba a ṣawiye? Bi o tilẹ ṣepe mo ṣe olododo, emi kò gbọdọ̀ da a lohùn, ṣugbọn emi o gbadura ẹ̀bẹ mi sọdọ onidajọ mi. Bi emi ba si kepè e, ti on si da mi lohùn, emi kì yio si gbagbọ pe, on ti feti si ohùn mi. Nitoripe o fi ẹ̀fufu nla ṣẹ mi tutu, o sọ ọgbẹ mi di pipọ lainidi. On kì yio jẹ ki emi ki o fà ẹmi mi, ṣugbọn o fi ohun kikorò kún u fun mi. Bi mo ba sọ ti agbara, wò o! alagbara ni, tabi niti idajọ, tani yio da akoko fun mi lati rò? Bi mo tilẹ da ara mi lare, ẹnu ara mi ni yio dá mi lẹbi; bi mo wipe, olododo li emi, yio si fi mi hàn ni ẹni-òdi.

Job 9:1-20 Yoruba Bible (YCE)

Jobu dáhùn pé: “Lóòótọ́, mo mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí, ṣugbọn báwo ni ẹlẹ́ran ara ṣe lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun? Bí eniyan tilẹ̀ fẹ́ bá a jiyàn, olúwarẹ̀ kò ní lè dáhùn ẹyọ kan ninu ẹgbẹrun ìbéèrè tí yóo bèèrè. Ọgbọ́n rẹ̀ jinlẹ̀, agbára rẹ̀ sì pọ̀. Ta ló tó ṣe oríkunkun sí i kí ó mú un jẹ? Ẹni tí ó ṣí àwọn òkè nídìí, ninu ibinu rẹ̀; tí wọn kò sì mọ ẹni tí ó bì wọ́n ṣubú. Ó ti ayé kúrò ní ipò rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀ sì wárìrì. Ó pàṣẹ fún oòrùn, oòrùn kò sì yọ; ó sé àwọn ìràwọ̀ mọ́lé; òun nìkan ṣoṣo ni ó dá ojú ọ̀run tẹ́ bí aṣọ, tí ó sì tẹ ìgbì omi òkun mọ́lẹ̀. Ó dá àwọn ìràwọ̀ sójú ọ̀run: Beari, Orioni, ati Pileiadesi ati àwọn ìràwọ̀ ìhà gúsù. Ó ṣe àwọn ohun ńlá tí ó kọjá òye ẹ̀dá, ati àwọn iṣẹ́ ìyanu tí kò ní òǹkà. Ó gba ẹ̀gbẹ́ mi kọjá, n kò rí i, ó ń kọjá lọ, n kò sì mọ̀. Wò ó! Ó já àwọn ohun tí ó wù ú gbà, ta ló lè dá a dúró? Ta ló tó bi í pé, ‘Kí ni ò ń ṣe?’ “Ọlọrun kò ní dáwọ́ ibinu rẹ̀ dúró, yóo fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn olùrànlọ́wọ́ Rahabu mọ́lẹ̀. Báwo ni mo ṣe lè bá a rojọ́? Kí ni kí n sọ? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi, sibẹsibẹ n kò lè dá a lóhùn. Ẹ̀bẹ̀ nìkan ni mo lè bẹ̀ fún àánú, lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ẹ̀sùn kàn mí. Bí mo bá pè é pé kó wá gbọ́, tí ó sì dá mi lóhùn, sibẹ n kò lè gbàgbọ́ pé yóo dẹtí sílẹ̀ gbọ́rọ̀ mi. Nítorí pé ó ti fi ìjì tẹ̀ mí mọ́lẹ̀, ó sì sọ egbò mi di pupọ láìnídìí; kò ní jẹ́ kí n mí, ìbànújẹ́ ni ó fi kún ọkàn mi. Bí ó bá ṣe ti pé kí á dán agbára wò ni, agbára rẹ̀ pọ̀ tayọ! Bí ó bá sì jẹ́ pé ti ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́, ta ló lè pè é lẹ́jọ́? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi, sibẹsibẹ ọ̀rọ̀ ẹnu mi yóo di ẹ̀bi rù mí; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́ṣẹ̀, sibẹsibẹ yóo fihàn pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.

Job 9:1-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Jobu sì dáhùn ó sì wí pé: “Èmi mọ̀ pe bẹ́ẹ̀ ni ní òtítọ́. Báwo ní ènìyàn yóò ha ti ṣe jẹ́ aláre níwájú Ọlọ́run? Bí ó bá ṣe pé yóò bá a jà, òun kì yóò lè dalóhùn kan nínú ẹgbẹ̀rún ọ̀rọ̀. Ọlọ́gbọ́n nínú àwọn alágbára ní ipa ní Òun; ta ni ó ṣe agídí sí i tí ó sì gbé fún rí? Ẹni tí ó sí òkè nídìí tí wọn kò sì mọ́: tí ó taari wọn ṣubú ní ìbínú rẹ̀. Tí ó mi ilẹ̀ ayé tìtì kúrò ní ipò rẹ̀, ọwọ́n rẹ̀ sì mì tìtì. Ó pàṣẹ fún oòrùn kò sì le è ràn, kí ó sì dí ìmọ́lẹ̀ ìràwọ̀ mọ́. Òun nìkan ṣoṣo ni ó ta ojú ọ̀run, ti ó sì ń rìn lórí ìgbì Òkun. Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Beari, Orioni àti Pleiadesi àti ìràwọ̀ púpọ̀ ti gúúsù. Ẹni tí ń ṣe ohun tí ó tóbi jù àwárí lọ, àní ohun ìyanu láìní iye. Kíyèsi i, ó ń kọjá lọ ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ mi, èmi kò sì rí i, ó sì kọjá síwájú, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò rí ojú rẹ̀. Kíyèsi i, ó já a gbà lọ, ta ni ó lè fà á padà? Ta ni yóò bi í pé kí ni ìwọ ń ṣe nì? Ọlọ́run kò ní fa ìbínú rẹ̀ sẹ́yìn, àwọn onírànlọ́wọ́ ti Rahabu a sì tẹríba lábẹ́ rẹ̀. “Kí ní ṣe tí èmi ti n o fi ba ṣàròyé? Tí èmi yóò fi ma ṣe àwáwí? Bí ó tilẹ̀ ṣe pé mo ṣe aláìlẹ́bi, èmi kò gbọdọ̀ dá a lóhùn; ṣùgbọ́n èmi ó gbàdúrà fún àánú. Bí èmi bá sì ké pè é, tí Òun sì dá mi lóhùn, èmi kì yóò sì gbàgbọ́ pé, Òun ti fetí sí ohùn mi. Nítorí pé òun yóò lọ̀ mí lúúlúú pẹ̀lú ìjì ńlá, ó sọ ọgbẹ́ mi di púpọ̀ láìnídìí. Òun kì yóò jẹ́ kí èmi kí ó rí ẹ̀mí mi, ṣùgbọ́n ó mú ohun kíkorò kún un fún mi. Bí mo bá sọ ti agbára, wò ó! Alágbára ni, tàbí ní ti ìdájọ́, ta ni yóò dá àkókò fún mi láti rò? Bí mo tilẹ̀ dá ara mi láre, ẹnu ara mi yóò dá mi lẹ́bi; bí mo wí pé olódodo ni èmi yóò sì fi mí hàn ní ẹni ẹ̀bi.