Job 8:8-22

Job 8:8-22 Yoruba Bible (YCE)

“Mo bẹ̀ ọ́, lọ wádìí nípa ìgbà àtijọ́, kí o ṣe akiyesi ìrírí àwọn baba wa. Nítorí ọmọde ni wá, a kò mọ nǹkankan, ọjọ́ ayé wa sì dàbí òjìji. Àwọn ni wọn óo kọ́ ọ, tí wọn óo bá ọ sọ̀rọ̀, tí wọn óo sì fún ọ ní ìmọ̀ràn ninu òye wọn. “Ṣé koríko etídò le hù níbi tí kò sí àbàtà? Tabi kí èèsún hù níbi tí kò sí omi? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà tí ó bá ń tanná lọ́wọ́, yóo rọ ṣáájú gbogbo ewéko, láìjẹ́ pé ẹnikẹ́ni gé e lulẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ẹni tí ó gbàgbé Ọlọrun rí; ìrètí ẹni tí kò mọ Ọlọrun yóo parun. Igbẹkẹle rẹ̀ já sí asán, ìmúlẹ̀mófo ni, bí òwú aláǹtakùn. Ó farati ilé rẹ̀, ṣugbọn kò le gbà á dúró. Ó dì í mú, ṣugbọn kò lè mú un dúró. Kí oòrùn tó yọ, ẹni ibi a máa tutù yọ̀yọ̀, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ a sì gbilẹ̀ káàkiri inú ọgbà rẹ̀. Ṣugbọn ara òkúta ni gbòǹgbò rẹ̀ rọ̀ mọ́, òun gan-an sì ń gbé ààrin àpáta. Bí wọ́n bá fà á tu kúrò ní ààyè rẹ̀, kò sí ẹni tí yóo mọ̀ pé ó wà níbẹ̀ rí. Ayọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ kò jù báyìí lọ, àwọn mìíràn óo dìde, wọn yóo sì gba ipò rẹ̀. “Ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ́ fi àwọn olóòótọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ́ ran ẹni ibi lọ́wọ́. Yóo tún fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́, ẹnu rẹ yóo kún fún ìhó ayọ̀. Ojú yóo ti àwọn ọ̀tá rẹ, ilé àwọn eniyan burúkú yóo sì parẹ́.”

Job 8:8-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Èmi bẹ̀ ọ́ ǹjẹ́, béèrè lọ́wọ́ àwọn ará ìgbà nì kí o sì kíyèsi ìwádìí àwọn baba wọn. Nítorí pé ọmọ-àná ni àwa, a kò sì mọ nǹkan, nítorí pé òjìji ni ọjọ́ wa ni ayé. Àwọn kì yóò wa kọ ọ́, wọn kì yóò sì sọ fún ọ? Wọn kì yóò sì sọ̀rọ̀ láti inú òye wọn jáde wá? Papirusi ha lè dàgbà láìní ẹrẹ̀ tàbí eèsún ha lè dàgbà láìlómi? Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò ké e lulẹ̀, ó rọ dànù, ewéko gbogbo mìíràn hù dípò rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn àgàbàgebè yóò di òfo. Àbá ẹni tí a ó kèé kúrò, àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dàbí ilé aláǹtakùn. Yóò fi ara ti ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró, yóò fi di ara rẹ̀ mú ṣinṣin ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró pẹ́. Ó tutù bí irúgbìn tí a bomirin níwájú oòrùn, ẹ̀ka rẹ̀ sì yọ jáde nínú ọgbà rẹ̀. Gbòǹgbò rẹ̀ ta yí ebè ká, ó sì wó ibi òkúta wọ̀n-ọn-nì. Bí ó bá sì pa á run kúrò ní ipò rẹ̀, nígbà náà ni ipò náà yóò sọ, ‘Èmi kò ri ọ rí!’ Kíyèsi i, ayé rẹ̀ gbẹ dànù àti láti inú ilẹ̀ ní irúgbìn òmíràn yóò hù jáde wá. “Kíyèsi i, Ọlọ́run kì yóò ta ẹni òtítọ́ nù, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ran oníwà búburú lọ́wọ́ títí yóò fi fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹnu, àti ètè rẹ pẹ̀lú ìhó ayọ̀, ìtìjú ní a o fi bo àwọn tí ó kórìíra rẹ̀, àti ibùjókòó ènìyàn búburú kì yóò sí mọ́.”