Job 8:1-22
Job 8:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni Bildadi, ara Ṣua, dahùn wipe, Iwọ o ti ma sọ nkan wọnyi pẹ to? ti ọ̀rọ ẹnu rẹ yio si ma dabi ẹfufu nla? Ọlọrun a ha ma yi idajọ po bi, tabi Olodumare a ma fi otitọ ṣẹ̀ bi? Nigbati awọn ọmọ rẹ ṣẹ̀ si i, o si gbá wọn kuro nitori irekọja wọn. Bi iwọ ba si kepe Ọlọrun ni igba akokò, ti iwọ bá si gbadura ẹ̀bẹ si Olodumare. Iwọ iba mọ́, ki o si duro ṣinṣin: njẹ nitõtọ nisisiyi on o tají fun ọ, on a si sọ ibujoko ododo rẹ di pipọ. Ipilẹṣẹ rẹ iba tilẹ kere ri, bẹ̃ni igbẹhin rẹ iba pọ̀ si i gidigidi. Emi bẹ̀ ọ njẹ, bere lọwọ awọn ara igbãni, ki o si kiyesi iwádi awọn baba wọn. Nitoripe ọmọ-àná li awa, a kò si mọ̀ nkan, nitoripe òjiji li ọjọ wa li aiye. Awọn kì yio ha kọ́ ọ, nwọn kì yio si sọ fun ọ, nwọn kì yio si sọ̀rọ lati inu ọkàn wọn jade wá? Koriko odò ha le dàgba laini ẹrẹ̀, tabi ẽsú ha le dàgba lailomi? Nigbati o wà ni tutù, ti a kò ke e lulẹ̀, o rọ danu sin eweko miran gbogbo. Bẹ̃ni ipa ọ̀na gbogbo awọn ti o gbagbe Ọlọrun, abá awọn àgabàgebe yio di ofo. Abá ẹniti a o ke kuro, ati igbẹkẹle ẹniti o dàbi ile alantakùn. Yio fi ara tì ile rẹ̀, ṣugbọn kì yio le iduro, yio fi di ara rẹ̀ mu ṣinṣin ṣugbọn kì yio le iduro pẹ. O tutù niwaju õrùn, ẹka rẹ̀ si yọ jade ninu ọgbà rẹ̀. Gbòngbo rẹ̀ ta yi ebè ka, o si wò ibi okuta wọnni. Bi o ba si pa a run kuro ni ipò rẹ̀, nigbana ni ipò na yio sẹ ẹ pe: emi kò ri ọ ri! Kiyesi eyi ni ayọ̀ ọ̀na rẹ̀ ati lati inu ilẹ li omiran yio ti hù jade wá. Kiyesi i, Ọlọrun kì yio ta ẹni-otitọ nù, bẹ̃ni kì yio ràn oniwa-buburu lọwọ. Titi yio fi fi ẹ̀rin kún ọ li ẹnu, ati ète rẹ pẹlu iho ayọ̀. Itiju li a o fi bò awọn ti o korira rẹ, ati ibujoko enia buburu kì yio si mọ.
Job 8:1-22 Yoruba Bible (YCE)
Bilidadi ará Ṣuha dáhùn pé, “O óo ti sọ irú ọ̀rọ̀ wọnyi pẹ́ tó, tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ yóo sì dàbí afẹ́fẹ́ líle? Ṣé Ọlọrun a máa yí ìdájọ́ po? Ṣé Olodumare a máa yí òdodo pada? Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ọmọ rẹ dẹ́ṣẹ̀ ni, ó ti jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ṣugbọn bí o bá wá Ọlọrun, tí o sì sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún Olodumare; tí o bá jẹ́ ẹni mímọ́ ati olóòótọ́, dájúdájú OLUWA yóo dìde, yóo ràn ọ́ lọ́wọ́, yóo sì fi ibùgbé rere san ẹ̀san fún ọ. Díẹ̀ ni ọrọ̀ tí o ní tẹ́lẹ̀ yóo jẹ́ lára ohun tí Ọlọrun yóo fún ọ ní ọjọ́ iwájú. “Mo bẹ̀ ọ́, lọ wádìí nípa ìgbà àtijọ́, kí o ṣe akiyesi ìrírí àwọn baba wa. Nítorí ọmọde ni wá, a kò mọ nǹkankan, ọjọ́ ayé wa sì dàbí òjìji. Àwọn ni wọn óo kọ́ ọ, tí wọn óo bá ọ sọ̀rọ̀, tí wọn óo sì fún ọ ní ìmọ̀ràn ninu òye wọn. “Ṣé koríko etídò le hù níbi tí kò sí àbàtà? Tabi kí èèsún hù níbi tí kò sí omi? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà tí ó bá ń tanná lọ́wọ́, yóo rọ ṣáájú gbogbo ewéko, láìjẹ́ pé ẹnikẹ́ni gé e lulẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ẹni tí ó gbàgbé Ọlọrun rí; ìrètí ẹni tí kò mọ Ọlọrun yóo parun. Igbẹkẹle rẹ̀ já sí asán, ìmúlẹ̀mófo ni, bí òwú aláǹtakùn. Ó farati ilé rẹ̀, ṣugbọn kò le gbà á dúró. Ó dì í mú, ṣugbọn kò lè mú un dúró. Kí oòrùn tó yọ, ẹni ibi a máa tutù yọ̀yọ̀, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ a sì gbilẹ̀ káàkiri inú ọgbà rẹ̀. Ṣugbọn ara òkúta ni gbòǹgbò rẹ̀ rọ̀ mọ́, òun gan-an sì ń gbé ààrin àpáta. Bí wọ́n bá fà á tu kúrò ní ààyè rẹ̀, kò sí ẹni tí yóo mọ̀ pé ó wà níbẹ̀ rí. Ayọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ kò jù báyìí lọ, àwọn mìíràn óo dìde, wọn yóo sì gba ipò rẹ̀. “Ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ́ fi àwọn olóòótọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ́ ran ẹni ibi lọ́wọ́. Yóo tún fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́, ẹnu rẹ yóo kún fún ìhó ayọ̀. Ojú yóo ti àwọn ọ̀tá rẹ, ilé àwọn eniyan burúkú yóo sì parẹ́.”
Job 8:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìgbà náà ni Bilidadi, ará Ṣuhi, sì dáhùn wí pé: “Ìwọ yóò ti máa sọ nǹkan wọ̀nyí pẹ́ tó? Tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ yóò sì máa bí ẹ̀fúùfù ńlá? Ọlọ́run a ha máa yí ìdájọ́ po bí? Tàbí Olódùmarè a máa gbé ẹ̀bi fún aláre? Nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣẹ̀ sí i, ó sì gbá wọn kúrò nítorí ìrékọjá wọn. Bí ìwọ bá sì ké pe Ọlọ́run ní àkókò, tí ìwọ sì gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ sí Olódùmarè. Ìwọ ìbá jẹ́ mímọ, kí ó sì dúró ṣinṣin: ǹjẹ́ nítòótọ́ nísinsin yìí òun yóò tají fún ọ, òun a sì sọ ibùjókòó òdodo rẹ di púpọ̀. Ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ ìbá tilẹ̀ kéré si í, bẹ́ẹ̀ ìgbẹ̀yìn rẹ ìbá pọ̀ sí i gidigidi. “Èmi bẹ̀ ọ́ ǹjẹ́, béèrè lọ́wọ́ àwọn ará ìgbà nì kí o sì kíyèsi ìwádìí àwọn baba wọn. Nítorí pé ọmọ-àná ni àwa, a kò sì mọ nǹkan, nítorí pé òjìji ni ọjọ́ wa ni ayé. Àwọn kì yóò wa kọ ọ́, wọn kì yóò sì sọ fún ọ? Wọn kì yóò sì sọ̀rọ̀ láti inú òye wọn jáde wá? Papirusi ha lè dàgbà láìní ẹrẹ̀ tàbí eèsún ha lè dàgbà láìlómi? Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò ké e lulẹ̀, ó rọ dànù, ewéko gbogbo mìíràn hù dípò rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn àgàbàgebè yóò di òfo. Àbá ẹni tí a ó kèé kúrò, àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dàbí ilé aláǹtakùn. Yóò fi ara ti ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró, yóò fi di ara rẹ̀ mú ṣinṣin ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró pẹ́. Ó tutù bí irúgbìn tí a bomirin níwájú oòrùn, ẹ̀ka rẹ̀ sì yọ jáde nínú ọgbà rẹ̀. Gbòǹgbò rẹ̀ ta yí ebè ká, ó sì wó ibi òkúta wọ̀n-ọn-nì. Bí ó bá sì pa á run kúrò ní ipò rẹ̀, nígbà náà ni ipò náà yóò sọ, ‘Èmi kò ri ọ rí!’ Kíyèsi i, ayé rẹ̀ gbẹ dànù àti láti inú ilẹ̀ ní irúgbìn òmíràn yóò hù jáde wá. “Kíyèsi i, Ọlọ́run kì yóò ta ẹni òtítọ́ nù, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ran oníwà búburú lọ́wọ́ títí yóò fi fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹnu, àti ètè rẹ pẹ̀lú ìhó ayọ̀, ìtìjú ní a o fi bo àwọn tí ó kórìíra rẹ̀, àti ibùjókòó ènìyàn búburú kì yóò sí mọ́.”