Job 7:1-6
Job 7:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ ija kan kò ha si fun enia lori ilẹ, ọjọ rẹ̀ pẹlu kò dabi ọjọ alagbaṣe? Bi ọmọ-ọdọ ti ima kanju bojuwo ojiji, ati bi alagbaṣe ti ima kanju wọ̀na owo iṣẹ rẹ̀. Bẹ̃li a mu mi ni oṣoṣu asan, oru idanilagãra ni a si là silẹ fun mi. Nigbati mo dubulẹ̀, emi wipe, nigbawo ni emi o dide, ti oru yio si kọja? o si tó fun mi lati yi sihin yi sọhun titi yio fi di afẹmọ́jumọ. Kòkoro ati ogulùtu erupẹ li a fi wọ̀ mi li aṣọ, àwọ mi bù, o si di sisun ni. Ọjọ mi yara jù ọkọ̀ iwunṣọ lọ, o si di lilò li ainireti.
Job 7:1-6 Yoruba Bible (YCE)
“Ìgbésí ayé eniyan le koko, ọjọ́ ayé rẹ̀ sì dàbí ti alágbàṣe. Ó dàbí ẹrú tí ń wá ìbòòji kiri ati bí alágbàṣe tí ń dúró de owó iṣẹ́ rẹ̀. Òfo ni ọ̀rọ̀ mi látoṣù-dóṣù, ìbànújẹ́ ní sì ń dé bá mi láti ọjọ́ dé ọjọ́ Bí mo bá sùn lóru, n óo máa ronú pé, ‘Ìgbà wo ni ilẹ̀ óo mọ́ tí n óo dìde?’ Òru a gùn bí ẹni pé ojúmọ́ kò ní mọ́ mọ́, ma wá máa yí síhìn-ín, sọ́hùn-ún, títí ilẹ̀ yóo fi mọ́. Gbogbo ara mi kún fún kòkòrò, ati ìdọ̀tí, gbogbo ara mi yi, ó sì di egbò. Ọjọ́ ayé mi ń sáré ju ọ̀kọ̀ ìhunṣọ lọ, Ó sì ń lọ sópin láìní ìrètí.
Job 7:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ṣé ìjà kò ha si fún ènìyàn lórí ilẹ̀? Ọjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú kò ha dàbí ọjọ́ alágbàṣe? Bí ọmọ ọ̀dọ̀ tí máa ń kánjú bojú wo òjìji, àti bí alágbàṣe ti í kánjú wo ọ̀nà owó iṣẹ́ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni a mú mi ní ìbànújẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù, òru ìdáni-lágara ni a sì là sílẹ̀ fún mi. Nígbà ti mo dùbúlẹ̀, èmi wí pé, ‘Nígbà wo ni èmi ó dìde?’ Tí òru yóò sì kọjá, ó sì tó fún mi láti yí síhìn-ín yí sọ́hùn-ún, títí yóò fi di àfẹ̀mọ́júmọ́. Kòkòrò àti ògúlùtu erùpẹ̀ ni á fi wọ̀ mi ni aṣọ, awọ ara mi bù, o sì di bíbàjẹ́. “Ọjọ́ mi yára jù ọkọ̀ ìhunṣọ lọ, o sì di lílò ní àìní ìrètí.