Job 7:1-21
Job 7:1-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ ija kan kò ha si fun enia lori ilẹ, ọjọ rẹ̀ pẹlu kò dabi ọjọ alagbaṣe? Bi ọmọ-ọdọ ti ima kanju bojuwo ojiji, ati bi alagbaṣe ti ima kanju wọ̀na owo iṣẹ rẹ̀. Bẹ̃li a mu mi ni oṣoṣu asan, oru idanilagãra ni a si là silẹ fun mi. Nigbati mo dubulẹ̀, emi wipe, nigbawo ni emi o dide, ti oru yio si kọja? o si tó fun mi lati yi sihin yi sọhun titi yio fi di afẹmọ́jumọ. Kòkoro ati ogulùtu erupẹ li a fi wọ̀ mi li aṣọ, àwọ mi bù, o si di sisun ni. Ọjọ mi yara jù ọkọ̀ iwunṣọ lọ, o si di lilò li ainireti. A! ranti pe afẹfẹ li ẹmi mi; oju mi kì yio pada ri rere mọ. Oju ẹniti o ri mi, kì yio ri mi mọ; oju rẹ tẹ mọra mi, emi kò sí mọ́! Bi awọ-sanma ti iparun, ti isi fò lọ, bẹ̃li ẹniti nlọ si ipò-okú, ti kì yio pada wá mọ. Kì yio pada sinu ile rẹ̀ mọ, bẹ̃ni ipò rẹ̀ kì yio mọ̀ ọ mọ. Nitorina emi kì yio pa ẹnu mi mọ, emi o ma sọ ninu irora ọkàn mi, emi o ma ṣe irahùn ninu kikoro ọkàn mi. Emi ama iṣe ejo okun tabi erinmi, ti iwọ fi yàn oluṣọ tì mi? Nigbati mo wipe, ibusùn mi yio tù mi lara, itẹ mi yio gbé ẹrù irahùn mi pẹlu. Nigbana ni iwọ fi alá da mi niji, iwọ si fi iran oru dẹrubà mi. Bẹ̃li ọkàn mi yan isà okú jù aye, ikú jù egungun mi lọ. O su mi, emi kò le wà titi: jọwọ mi jẹ, nitoripe asan li ọjọ mi. Kili enia ti iwọ o ma kokìki rẹ̀? ati ti iwọ iba fi gbe ọkàn rẹ le e? Ati ti iwọ o fi ma wa ibẹ̀ ẹ wò li orowurọ̀, ti iwọ o si ma dán a wò nigbakũgba! Yio ti pẹ́ to ki iwọ ki o to fi mi silẹ̀ lọ, ti iwọ o fi jọ mi jẹ titi emi o fi le dá itọ mi mì. Emi ti ṣẹ̀, kili emi o ṣe si ọ, iwọ Olùtọju enia? ẽṣe ti iwọ fi fi mi ṣe àmi itasi niwaju rẹ, bẹ̃li emi si di ẹrù-wuwo si ara rẹ? Ẽṣe ti iwọ kò si dari irekọja mi jì, ki iwọ ki o si mu aiṣedede mi kuro? njẹ nisisiyi li emi iba sùn ninu erupẹ, iwọ iba si wá mi kiri li owurọ̀, emi ki ba ti si.
Job 7:1-21 Yoruba Bible (YCE)
“Ìgbésí ayé eniyan le koko, ọjọ́ ayé rẹ̀ sì dàbí ti alágbàṣe. Ó dàbí ẹrú tí ń wá ìbòòji kiri ati bí alágbàṣe tí ń dúró de owó iṣẹ́ rẹ̀. Òfo ni ọ̀rọ̀ mi látoṣù-dóṣù, ìbànújẹ́ ní sì ń dé bá mi láti ọjọ́ dé ọjọ́ Bí mo bá sùn lóru, n óo máa ronú pé, ‘Ìgbà wo ni ilẹ̀ óo mọ́ tí n óo dìde?’ Òru a gùn bí ẹni pé ojúmọ́ kò ní mọ́ mọ́, ma wá máa yí síhìn-ín, sọ́hùn-ún, títí ilẹ̀ yóo fi mọ́. Gbogbo ara mi kún fún kòkòrò, ati ìdọ̀tí, gbogbo ara mi yi, ó sì di egbò. Ọjọ́ ayé mi ń sáré ju ọ̀kọ̀ ìhunṣọ lọ, Ó sì ń lọ sópin láìní ìrètí. “Ọlọrun, ranti pé afẹ́fẹ́ lásán ni mo jẹ́, ati pé ojú mi kò ní rí ohun rere mọ́. Ojú ẹni tí ó rí mi nisinsinyii kò ní rí mi mọ́; níṣojú yín báyìí ni n óo fi parẹ́. Bí ìkùukùu tíí parẹ́ tí a kì í rí i mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí tí ó lọ sí ipò òkú rí, kò ní pada mọ́. Kò ní pada sí ilé rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kò ní mọ̀ ọ́n mọ́. “Nítorí náà, n kò ní dákẹ́; n óo sọ ìrora ọkàn mi; n óo tú ìbànújẹ́ mi jáde. Ṣé òkun ni mí ni, tabi erinmi, tí ẹ fi yan olùṣọ́ tì mí? Nígbà tí mo wí pé, ‘Ibùsùn mi yóo tù mí lára, ìjókòó mi yóo sì mú kí ara tù mí ninu ìráhùn mi’. Nígbà náà ni ẹ̀yin tún wá fi àlá yín dẹ́rù bà mí, tí ẹ sì fi ìran pá mi láyà, kí n lè fara mọ́ ọn pé ó sàn kí á lọ́ mi lọ́rùn pa, kí n sì lè yan ikú dípò pé kí n wà láàyè. Ayé sú mi, n kò ní wà láàyè títí lae. Ẹ fi mí sílẹ̀, nítorí ọjọ́ ayé mi dàbí èémí lásán. Kí ni eniyan jẹ́, tí o fi gbé e ga, tí o sì fi ń náání rẹ̀; tí ò ń bẹ̀ ẹ́ wò láràárọ̀, tí o sì ń dán an wò nígbà gbogbo? Yóo ti pẹ́ tó kí ẹ tó mójú kúrò lára mi? Kí ẹ tó fi mí lọ́rùn sílẹ̀ kí n rí ààyè dá itọ́ mì? Bí mo bá ṣẹ̀, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ yín, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣọ́ mi? Kí ló dé tí ẹ fi dójú lé mi, tí mo di ẹrù lọ́rùn yín? Kí ló dé tí ẹ kò lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí kí ẹ sì fojú fo àìdára mi? Láìpẹ́ n óo lọ sinu ibojì. Ẹ óo wá mi, ṣugbọn n kò ní sí mọ́.”
Job 7:1-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ṣé ìjà kò ha si fún ènìyàn lórí ilẹ̀? Ọjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú kò ha dàbí ọjọ́ alágbàṣe? Bí ọmọ ọ̀dọ̀ tí máa ń kánjú bojú wo òjìji, àti bí alágbàṣe ti í kánjú wo ọ̀nà owó iṣẹ́ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni a mú mi ní ìbànújẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù, òru ìdáni-lágara ni a sì là sílẹ̀ fún mi. Nígbà ti mo dùbúlẹ̀, èmi wí pé, ‘Nígbà wo ni èmi ó dìde?’ Tí òru yóò sì kọjá, ó sì tó fún mi láti yí síhìn-ín yí sọ́hùn-ún, títí yóò fi di àfẹ̀mọ́júmọ́. Kòkòrò àti ògúlùtu erùpẹ̀ ni á fi wọ̀ mi ni aṣọ, awọ ara mi bù, o sì di bíbàjẹ́. “Ọjọ́ mi yára jù ọkọ̀ ìhunṣọ lọ, o sì di lílò ní àìní ìrètí. Háà! Rántí pé afẹ́fẹ́ ni ẹ̀mí mi; ojú mi kì yóò padà rí rere mọ́. Ojú ẹni tí ó rí mi, kì yóò rí mi mọ́; ojú rẹ̀ tẹ̀ mọ́ra mi, èmi kò sí mọ́. Bí ìkùùkuu tí i túká, tí í sì fò lọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sí ipò òkú tí kì yóò padà wa mọ́. Kì yóò padà sínú ilé rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ní ipò rẹ̀ kì yóò mọ̀ ọn mọ́. “Nítorí náà èmi kì yóò pa ẹnu mi mọ́, èmi yóò máa sọ nínú ìrora ọkàn mi, èmi yóò máa ṣe ìráhùn nínú kíkorò ọkàn mi. Èmi a máa ṣe Òkun tàbí ẹ̀mí búburú, tí ìwọ fi ń yan olùṣọ́ tì mi? Nígbà tí mo wí pé, ibùsùn mi yóò tù mí lára, ìtẹ́ mi yóò mú ara mi fúyẹ́ pẹ̀lú. Nígbà náà ni ìwọ fi àlá da yọ mi lénu bò mi, ìwọ sì fi ìran òru dẹ́rùbà mí. Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mí yàn láti fún pa àti ikú ju kí ń wà láààyè ní ipò tí ara mí wà yìí lọ. O sú mi, èmi kò le wà títí: jọ̀wọ́ mi jẹ́, nítorí pé asán ni ọjọ́ mi. “Kí ni ènìyàn tí ìwọ o máa kókìkí rẹ̀? Àti tí ìwọ ìbá fi gbé ọkàn rẹ lé e? Àti ti ìwọ ó fi máa wá í bẹ̀ ẹ́ wò ni òròòwúrọ̀, ti ìwọ o sì máa dán an wò nígbàkúgbà! Yóò ti pẹ́ tó kí ìwọ kí ó tó fi mí sílẹ̀ lọ, tí ìwọ o fi mí sílẹ̀ jẹ́ẹ́ títí èmi yóò fi lè dá itọ́ mi mì. Èmi ti ṣẹ̀, ki ní èmi ó ṣe sí ọ. Ìwọ Olùsójú ènìyàn? Èéṣe tí ìwọ fi fi mí ṣe ààmì itasi níwájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì di ẹrẹ̀ wíwo fún ọ? Èéṣe tí ìwọ kò sì dárí ìrékọjá mi jìn, kí ìwọ kí ó sì mú àìṣedéédéé mi kúrò? Ǹjẹ́ nísinsin yìí ni èmi ìbá sùn nínú erùpẹ̀, ìwọ ìbá sì wá mi kiri ní òwúrọ̀, èmi kì bá tí sí.”