Job 42:3-6
Job 42:3-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Tani ẹniti nfi ìgbimọ pamọ laini ìmọ? nitorina ni emi ṣe nsọ eyi ti emi kò mọ̀, ohun ti o ṣe iyanu jọjọ niwaju mi, ti emi kò moye. Emi bẹ̀ ọ, gbọ́, emi o si sọ, emi o bère lọwọ rẹ, ki iwọ ki o si bùn mi ni oye. Emi ti fi gbigbọ́ eti gburo rẹ, ṣugbọn nisisiyi oju mi ti ri ọ. Njẹ nitorina emi korira ara mi, mo si ronupiwada ṣe tóto ninu ekuru ati ẽru.
Job 42:3-6 Yoruba Bible (YCE)
Ta nìyí tí ń fi ìmọ̀ràn pamọ́ láìní òye? Àwọn ohun tí mo sọ kò yé mi, ìyanu ńlá ni wọ́n jẹ́ fún mi, n kò sì mọ̀ wọ́n. O ní kí n tẹ́tí sílẹ̀, nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀, kí n sì dáhùn nígbà tí o bá bèèrè nǹkan lọ́wọ́ mi. Ìró rẹ ni mo gbọ́ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn nisinsinyii mo ti rí ọ; nítorí náà, ojú ara mi tì mí, fún ohun tí mo ti sọ, mo sì ronupiwada ninu erùpẹ̀ ati eérú.”
Job 42:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ béèrè, ta ni ẹni tí ń fi ìgbìmọ̀ pamọ́ láìní ìmọ̀? Nítorí náà ní èmi ṣe ń sọ èyí tí èmi kò mọ̀, ohun tí ó ṣe ìyanu jọjọ níwájú mi, ti èmi kò mòye. “Ìwọ wí pé, ‘gbọ́ tèmi báyìí, èmi ó sì sọ; èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, ìwọ yóò sì dá mi lóhùn.’ Etí mi sì ti gbọ́ nípa rẹ, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ojú mi ti rí ọ. Ǹjẹ́ nítorí náà èmi kórìíra ara mi, mo sì ronúpìwàdà nínú ekuru àti eérú.”