Job 41:1-34
Job 41:1-34 Bibeli Mimọ (YBCV)
IWỌ le ifi ìwọ fa Lefiatani [ọni nla] jade, tabi iwọ le imu ahọn rẹ̀ ninu okùn? Iwọ le ifi ìwọ bọ̀ ọ ni imu, tabi o le ifi ẹgun lu u li ẹrẹkẹ? On o ha jẹ bẹ ẹ̀bẹ lọdọ rẹ li ọ̀pọlọpọ bi, on o ha ba ọ sọ̀rọ pẹlẹ? On o ha ba ọ dá majẹmu bi, iwọ o ha ma mu u ṣe iranṣẹ lailai bi? Iwọ ha le ba a ṣire bi ẹnipe ẹiyẹ ni, tabi iwọ o dè e fun awọn ọmọbinrin iranṣẹ rẹ? Ẹgbẹ awọn apẹja yio ha ma tà a bi, nwọn o ha pin i lãrin awọn oniṣowo? Iwọ le isọ awọ rẹ̀ kun fun irin abeti, tabi iwọ o sọ ori rẹ̀ kún fun ẹṣín apẹja. Fi ọwọ rẹ le e lara, iwọ o ranti ìja na, iwọ kì yio ṣe bẹ̃ mọ. Kiyesi i, abá nipasẹ rẹ̀ ni asan, ni kìki ìri rẹ̀ ara kì yio ha rọ̀ ọ wẹsi? Kò si ẹni-alaiya lile ti o le iru u soke; njẹ tali o le duro niwaju rẹ̀? Tani o ṣaju ṣe fun mi, ti emi iba fi san fun u? ohunkohun ti mbẹ labẹ ọrun gbogbo ti emi ni. Emi kì yio fi ipin ara rẹ̀ pamọ, tabi ipá rẹ̀, tabi ihamọra rẹ̀ ti o li ẹwà. Tani yio le iridi oju aṣọ apata rẹ̀, tabi tani o le isunmọ ọ̀na meji ehin rẹ̀. Tani o le iṣi ilẹkun iwaju rẹ̀? ayika ehin rẹ̀ ni ìbẹru nla. Ipẹ lile ni igberaga rẹ̀, o pade pọ mọtimọti bi ami edidi, Ekini fi ara mọ ekeji tobẹ̃ ti afẹfẹ kò le iwọ̀ arin wọn. Ekini fi ara mọra ekeji rẹ̀, nwọn lẹmọ pọ̀ ti a kò le iyà wọn. Nipa sísin rẹ̀ imọlẹ a mọ́, oju rẹ̀ a si dabi ipénpeju owurọ. Lati ẹnu rẹ̀ ni ọwọ́-iná ti ijade wá, ipẹpẹ iná a si ta jade. Lati iho-imú rẹ̀ li ẽfin ti ijade wá, bi ẹnipe lati inu ikoko ti a fẹ́ iná ifefe labẹ rẹ̀. Ẹmi rẹ̀ tinabọ ẹyin, ọ̀wọ-iná si ti ẹnu rẹ̀ jade. Li ọrùn rẹ̀ li agbara kù si, ati ibinujẹ aiya si pada di ayọ̀ niwaju rẹ̀. Jabajaba ẹran rẹ̀ dijọ pọ̀, nwọn mura giri fun ara wọn, a kò le iṣi wọn ni ipò. Aiya rẹ̀ duro gbagigbagi bi okuta, ani o le bi iya-ọlọ. Nigbati o ba gbe ara rẹ̀ soke, awọn alagbara a bẹ̀ru, nitori ìbẹru nla, nwọn damu. Idà ẹniti o ṣa a kò le iràn a, ọ̀kọ, ẹṣin tabi ọfa. O ka irin si bi koriko gbigbẹ, ati idẹ si bi igi hihù. Ọfa kò le imu u sá, okuta kànakana lọdọ rẹ̀ dabi akeku koriko. O ka ẹṣin si bi akeku idi koriko, o rẹrin si ìmisi ọ̀kọ. Okuta mimú mbẹ nisalẹ abẹ rẹ̀, o si tẹ́ ohun mimú ṣonṣo sori ẹrẹ. O mu ibu omi hó bi ìkoko, o sọ agbami okun dabi kolobó ìkunra. O mu ipa-ọ̀na tàn lẹhin rẹ̀, enia a ma ka ibu si ewú arugbo. Lori ilẹ aiye kò si iru rẹ̀, ti a da laini ìbẹru. O bojuwo ohun giga gbogbo, o si nikan jasi ọba lori gbogbo awọn ọmọ igberaga.
Job 41:1-34 Yoruba Bible (YCE)
“Ṣé o lè fi ìwọ̀ fa Lefiatani jáde, tabi kí o fi okùn di ahọ́n rẹ̀? Ṣé o lè fi okùn sí imú rẹ̀, tabi kí o fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní àgbọ̀n? Ṣé yóo bẹ̀ ọ́, tabi kí ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀? Ṣé yóo bá ọ dá majẹmu, pé kí o fi òun ṣe iranṣẹ títí lae? Ṣé o lè máa fi ṣeré bí ọmọ ẹyẹ, tabi kí o dè é lókùn fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ? Ṣé àwọn oníṣòwò lè yọwó rẹ̀? Àbí wọ́n lè pín Lefiatani láàrin ara wọn? Ṣé o lè fi ọ̀kọ̀ gún ẹran ara rẹ̀, tabi kí o fi ẹ̀sín àwọn apẹja gún orí rẹ̀? Lọ fọwọ́ kàn án; kí o wo irú ìjà tí yóo bá ọ jà; o kò sì ní dán irú rẹ̀ wò mọ́ lae! “Ìrètí ẹni tí ó bá fẹ́ bá a jà yóo di òfo, nítorí ojora yóo mú un nígbà tí ó bá rí i. Ta ló láyà láti lọ jí i níbi tí ó bá sùn sí? Ta ló tó kò ó lójú? Ta ni mo gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀ tí mo níláti dá a pada fún un? Kò sí olúwarẹ̀ ní gbogbo ayé. “N kò ní yé sọ̀rọ̀ nípa ẹsẹ̀ rẹ̀, tabi nípa agbára rẹ̀ tabi dídára ìdúró rẹ̀. Ta ló tó bó awọ rẹ̀, tabi kí ó fi nǹkan gún igbá ẹ̀yìn rẹ̀? Ta ló tó ya ẹnu rẹ̀? Gbogbo eyín rẹ̀ ni ó kún fún ẹ̀rù. Ẹ̀yìn rẹ̀ kún fún ìpẹ́ tí ó dàbí apata, a tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ, wọ́n súnmọ́ ara wọn pẹ́kípẹ́kí bí èdìdì. Àwọn ìpẹ́ náà lẹ̀ mọ́ ara wọn tímọ́tímọ́, tóbẹ́ẹ̀ tí afẹ́fẹ́ kò lè fẹ́ kọjá láàrin wọn. Wọ́n so pọ̀, wọ́n lẹ̀ mọ́ ara wọn tóbẹ́ẹ̀, tí ohunkohun kò lè ṣí wọn. Bí ó bá sín, ìmọ́lẹ̀ á tàn jáde ní imú rẹ̀, ojú rẹ̀ ń tàn bíi ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ kutukutu. Ahọ́n iná ń yọ lẹ́nu rẹ̀ bí iná tí ń ta jáde, bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n iná ń yọ lálá. Èéfín ń jáde ní imú rẹ̀, bíi ti ìkòkò gbígbóná ati ìgbẹ́ tí ń jó. Èémí tí ó ń mí jáde dàbí ògúnná, ahọ́n iná ń yọ ní ẹnu rẹ̀. Kìkì agbára ni ọrùn rẹ̀, ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ sì ń bẹ níwájú rẹ̀. Ìṣẹ́po ẹran ara rẹ̀ lẹ̀ pọ̀ mọ́ ara wọn, wọ́n lẹ̀ pọ̀, wọn kò sì ṣe é ṣí. Ọkàn rẹ̀ le bí òkúta, ó le ju ọlọ lọ. Bí ó bá dìde, ẹ̀rù á ba àwọn alágbára, wọn á bì sẹ́yìn, wọn á ṣubú lé ara wọn lórí. Bí idà tilẹ̀ bá a, kò ràn án, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀kọ̀, ati ọfà, ati ẹ̀sín. Irin kò yàtọ̀ sí koríko lójú rẹ̀, idẹ sì dàbí igi tí ó ti rà. Bí wọn ta á lọ́fà, kò ní torí rẹ̀ sá, àwọn òkúta kànnàkànnà dàbí àgékù koríko lójú rẹ̀. Kùmọ̀ dàbí koríko lára rẹ̀, a sì máa fi ẹni tí ó ju ọ̀kọ̀ lù ú rẹ́rìn-ín. Ìpẹ́ ikùn rẹ̀ dàbí àpáàdì tí ó mú, wọn ń fa ilẹ̀ tútù ya bí ọkọ́. Ó mú kí ibú hó bí omi inú ìkòkò, ó ṣe òkun bí ìkòkò òróró ìpara. Bí ó bá ń rìn lọ, ipa ọ̀nà rẹ̀ a máa hàn lẹ́yìn rẹ̀, eniyan á rò pé òkun ń hó bí ọṣẹ ni. Kò sí ohun tí a lè fi wé láyé, ẹ̀dá tí ẹ̀rù kì í bà. Ó fojú tẹmbẹlu gbogbo ohun gíga, ó sì jọba lórí gbogbo àwọn ọmọ agbéraga.”
Job 41:1-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ǹjẹ́ ìwọ le è fi ìwọ̀ fa Lefitani jáde? Tàbí ìwọ lè fi okùn so ahọ́n rẹ̀ mọ́lẹ̀? Ìwọ lè fi okùn bọ̀ ọ́ ní í mú, tàbí fi ìwọ̀ ẹ̀gún gun ní ẹ̀rẹ̀kẹ́? Òun ha jẹ́ bẹ ẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀ rẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí òun ha bá ọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́? Òun ha bá ọ dá májẹ̀mú bí? Ìwọ ó ha máa mú ṣe ẹrú láéláé bí? Ìwọ ha lè ba sáré bí ẹni pé ẹyẹ ni, tàbí ìwọ ó dè é fún àwọn ọmọbìnrin ìránṣẹ́ rẹ̀? Ẹgbẹ́ àwọn apẹja yóò ha máa tà á bí? Wọn ó ha pín láàrín àwọn oníṣòwò? Ìwọ ha lè fi ọ̀kọ̀-irin gun awọ rẹ̀, tàbí orí rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ìpẹja. Fi ọwọ́ rẹ lé e lára, ìwọ ó rántí ìjà náà, ìwọ kì yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́. Kíyèsi, ìgbìyànjú láti mú un ní asán; ní kìkì ìrí rẹ̀ ara kì yóò ha rọ̀ ọ́ wẹ̀sì? Kò sí ẹni aláyà lílé tí ó lè ru sókè; Ǹjẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú mi. Ta ni ó kọ́kọ́ ṣe fún mi, tí èmi ìbá fi san án fún un? Ohunkóhun ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run gbogbo, tèmi ni. “Èmi kì yóò fi ẹ̀yà ara Lefitani, tàbí ipá rẹ, tàbí ìhámọ́ra rẹ tí ó ní ẹwà pamọ́. Ta ni yóò lè rídìí aṣọ àpáta rẹ̀? Tàbí ta ni ó lè súnmọ́ ọ̀nà méjì eyín rẹ̀? Ta ni ó lè ṣí ìlẹ̀kùn iwájú rẹ̀? Àyíká ẹ̀yin rẹ ni ìbẹ̀rù ńlá. Ìpẹ́ lílé ní ìgbéraga rẹ̀; ó pàdé pọ̀ tímọ́tímọ́ bí ààmì èdìdì. Èkínní fi ara mọ́ èkejì tó bẹ́ẹ̀ tí afẹ́fẹ́ kò lè wọ àárín wọn. Èkínní fi ara mọ́ èkejì rẹ̀; wọ́n lè wọ́n pọ̀ tí a kò lè mọ̀ wọ́n. Nípa sí sin rẹ̀ ìmọ́lẹ̀ á mọ́, ojú rẹ̀ a sì dàbí ìpéǹpéjú òwúrọ̀. Láti ẹnu rẹ ni ọ̀wọ́-iná ti jáde wá, ìpẹ́pẹ́ iná a sì ta jáde. Láti ihò imú rẹ ni èéfín ti jáde wá, bí ẹni pé láti inú ìkòkò tí a fẹ́ iná ìfèéfèé lábẹ́ rẹ̀. Èémí rẹ̀ tiná bọ ẹ̀yin iná, ọ̀wọ́-iná sì ti ẹnu rẹ̀ jáde. Ní ọrùn rẹ̀ ní agbára kù sí, àti ìbànújẹ́ àyà sì padà di ayọ̀ níwájú rẹ̀. Jabajaba ẹran rẹ̀ dìjọ pọ̀, wọ́n múra gírí fún ara wọn, a kò lè sí wọn ní ipò. Àyà rẹ̀ dúró gbagidi bí òkúta, àní, ó le bi ìyá ọlọ. Nígbà tí ó bá gbé ara rẹ̀ sókè, àwọn alágbára bẹ̀rù; nítorí ìbẹ̀rù ńlá, wọ́n dààmú. Ọ̀kọ̀ tàbí idà, tàbí ọfà, ẹni tí ó ṣá a kò lè rán an. Ó ká irin sí ibi koríko gbígbẹ àti idẹ si bi igi híhù. Ọfà kò lè mú un sá; òkúta kànnakánná lọ́dọ̀ rẹ̀ dàbí àgékù koríko. Ó ka ẹṣin sí bí àgékù ìdì koríko; ó rẹ́rìn-ín sí mímì ọ̀kọ̀. Òkúta mímú ń bẹ nísàlẹ̀ abẹ́ rẹ̀, ó sì tẹ́ ohun mímú ṣóńṣó sórí ẹrẹ̀. Ó mú ibú omi hó bí ìkòkò; ó sọ̀ agbami Òkun dàbí kólòbó ìkunra. Ó mú ipa ọ̀nà tan lẹ́yìn rẹ̀; ènìyàn a máa ka ibú sí ewú arúgbó. Lórí ilẹ̀ ayé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀, tí a dá láìní ìbẹ̀rù. Ó bojú wo ohun gíga gbogbo, ó sì nìkan jásí ọba lórí gbogbo àwọn ọmọ ìgbéraga.”