Job 41:1-11
Job 41:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
IWỌ le ifi ìwọ fa Lefiatani [ọni nla] jade, tabi iwọ le imu ahọn rẹ̀ ninu okùn? Iwọ le ifi ìwọ bọ̀ ọ ni imu, tabi o le ifi ẹgun lu u li ẹrẹkẹ? On o ha jẹ bẹ ẹ̀bẹ lọdọ rẹ li ọ̀pọlọpọ bi, on o ha ba ọ sọ̀rọ pẹlẹ? On o ha ba ọ dá majẹmu bi, iwọ o ha ma mu u ṣe iranṣẹ lailai bi? Iwọ ha le ba a ṣire bi ẹnipe ẹiyẹ ni, tabi iwọ o dè e fun awọn ọmọbinrin iranṣẹ rẹ? Ẹgbẹ awọn apẹja yio ha ma tà a bi, nwọn o ha pin i lãrin awọn oniṣowo? Iwọ le isọ awọ rẹ̀ kun fun irin abeti, tabi iwọ o sọ ori rẹ̀ kún fun ẹṣín apẹja. Fi ọwọ rẹ le e lara, iwọ o ranti ìja na, iwọ kì yio ṣe bẹ̃ mọ. Kiyesi i, abá nipasẹ rẹ̀ ni asan, ni kìki ìri rẹ̀ ara kì yio ha rọ̀ ọ wẹsi? Kò si ẹni-alaiya lile ti o le iru u soke; njẹ tali o le duro niwaju rẹ̀? Tani o ṣaju ṣe fun mi, ti emi iba fi san fun u? ohunkohun ti mbẹ labẹ ọrun gbogbo ti emi ni.
Job 41:1-11 Yoruba Bible (YCE)
“Ṣé o lè fi ìwọ̀ fa Lefiatani jáde, tabi kí o fi okùn di ahọ́n rẹ̀? Ṣé o lè fi okùn sí imú rẹ̀, tabi kí o fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní àgbọ̀n? Ṣé yóo bẹ̀ ọ́, tabi kí ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀? Ṣé yóo bá ọ dá majẹmu, pé kí o fi òun ṣe iranṣẹ títí lae? Ṣé o lè máa fi ṣeré bí ọmọ ẹyẹ, tabi kí o dè é lókùn fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ? Ṣé àwọn oníṣòwò lè yọwó rẹ̀? Àbí wọ́n lè pín Lefiatani láàrin ara wọn? Ṣé o lè fi ọ̀kọ̀ gún ẹran ara rẹ̀, tabi kí o fi ẹ̀sín àwọn apẹja gún orí rẹ̀? Lọ fọwọ́ kàn án; kí o wo irú ìjà tí yóo bá ọ jà; o kò sì ní dán irú rẹ̀ wò mọ́ lae! “Ìrètí ẹni tí ó bá fẹ́ bá a jà yóo di òfo, nítorí ojora yóo mú un nígbà tí ó bá rí i. Ta ló láyà láti lọ jí i níbi tí ó bá sùn sí? Ta ló tó kò ó lójú? Ta ni mo gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀ tí mo níláti dá a pada fún un? Kò sí olúwarẹ̀ ní gbogbo ayé.
Job 41:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ǹjẹ́ ìwọ le è fi ìwọ̀ fa Lefitani jáde? Tàbí ìwọ lè fi okùn so ahọ́n rẹ̀ mọ́lẹ̀? Ìwọ lè fi okùn bọ̀ ọ́ ní í mú, tàbí fi ìwọ̀ ẹ̀gún gun ní ẹ̀rẹ̀kẹ́? Òun ha jẹ́ bẹ ẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀ rẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí òun ha bá ọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́? Òun ha bá ọ dá májẹ̀mú bí? Ìwọ ó ha máa mú ṣe ẹrú láéláé bí? Ìwọ ha lè ba sáré bí ẹni pé ẹyẹ ni, tàbí ìwọ ó dè é fún àwọn ọmọbìnrin ìránṣẹ́ rẹ̀? Ẹgbẹ́ àwọn apẹja yóò ha máa tà á bí? Wọn ó ha pín láàrín àwọn oníṣòwò? Ìwọ ha lè fi ọ̀kọ̀-irin gun awọ rẹ̀, tàbí orí rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ìpẹja. Fi ọwọ́ rẹ lé e lára, ìwọ ó rántí ìjà náà, ìwọ kì yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́. Kíyèsi, ìgbìyànjú láti mú un ní asán; ní kìkì ìrí rẹ̀ ara kì yóò ha rọ̀ ọ́ wẹ̀sì? Kò sí ẹni aláyà lílé tí ó lè ru sókè; Ǹjẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú mi. Ta ni ó kọ́kọ́ ṣe fún mi, tí èmi ìbá fi san án fún un? Ohunkóhun ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run gbogbo, tèmi ni.