Job 40:3-6
Job 40:3-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni Jobu da Oluwa lohùn, o si wipe: Kiyesi i, ẹgbin li emi; ohùn kili emi o da? emi o fi ọwọ mi le ẹnu mi. Ẹ̃kan ni mo sọ̀rọ̀, ṣugbọn emi kì yio si tun sọ mọ, lẹ̃meji ni, emi kò si le iṣe e mọ́. Nigbana ni OLUWA da Jobu lohùn lati inu ìji ajayika wá o si wipe
Job 40:3-6 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni Jobu dá OLUWA lóhùn, ó ní: “OLUWA, kí ni mo jámọ́, tí n óo fi dá ọ lóhùn? Nítorí náà, mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́. Mo ti sọ̀rọ̀ ju bí ó ti yẹ lọ, n kò sì ní sọ̀rọ̀ mọ́.” Nígbà náà ni OLUWA tún bá Jobu sọ̀rọ̀ láti inú ìjì líle, ó ní
Job 40:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Jobu dá OLúWA lóhùn wá ó sì wí pé, “Kíyèsi i, ẹ̀gbin ni èmi—ohun kí ni èmi ó dà? Èmi ó fi ọwọ́ mi le ẹnu mi. Ẹ̀ẹ̀kan ní mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kì yóò tún sọ mọ́; lẹ́ẹ̀kejì ni, èmi kò sì le ṣe é mọ́.” Nígbà náà ní OLúWA dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àyíká wá, ó sì wí pé