Job 40:15-24
Job 40:15-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ nisisiyi kiyesi Behemotu ti mo da pẹlu rẹ, on a ma jẹ koriko bi ọ̀da-malu. Wò o nisisiyi, agbara rẹ̀ wà li ẹgbẹ́ rẹ̀, ati ipa rẹ̀ ninu iṣan ikún rẹ̀. On a ma jù ìru rẹ̀ bi igi kedari, iṣan itan rẹ̀ dijọ pọ̀. Egungun rẹ̀ ni ogusọ idẹ, egungun rẹ̀ dabi ọpa irin. On ni olu nipa ọ̀na Ọlọrun; ẹniti o da a o fi idà rẹ̀ le e lọwọ. Nitõtọ oke nlanla ni imu ohun jijẹ fun u wá, nibiti gbogbo ẹranko igbẹ ima ṣire. O dubulẹ labẹ igi Lotosi, ninu ifefe bibò ati ẹrẹ. Igi Lotosi ṣiji wọn bò o, igi arọrọ odò yi i kakiri. Kiyesi i, odò nla ṣan jọjọ, on kò salọ, o wà lailewu bi o ba ṣe odò Jordani ti ṣan lọ si ẹnu rẹ̀. Ẹnikan ha le imu u li oju rẹ̀ tabi a ma fi ọkọ gun imú rẹ̀?
Job 40:15-24 Yoruba Bible (YCE)
“Wo Behemoti, ẹran ńlá inú omi, tí mo dá gẹ́gẹ́ bí mo ti dá ọ, koríko ni ó ń jẹ bíi mààlúù! Wò ó bí ó ti lágbára tó! Ati irú okun tí awọ inú rẹ̀ ní. Ìrù rẹ̀ dúró ṣánṣán bí igi kedari, gbogbo iṣan itan rẹ̀ dì pọ̀. Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá idẹ, ọwọ́ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ rí bí irin. “Ó wà lára àwọn ohun àkọ́kọ́ tí èmi Ọlọrun dá, sibẹ ẹlẹ́dàá rẹ̀ nìkan ló lè pa á. Orí àwọn òkè ni ó ti ń rí oúnjẹ jẹ, níbi tí àwọn ẹranko ìgbẹ́ ti ń ṣeré. Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lotusi, lábẹ́ ọ̀pá ìyè ninu ẹrẹ̀. Igi lotusi ni ó ń ṣíji bò ó, igi tí ó wà létí odò yí i ká. Kò náání ìgbì omi, kò bẹ̀rù bí odò Jọdani tilẹ̀ ru dé bèbè rẹ̀. Ṣé eniyan lè fi ìwọ̀ mú un? Tabi kí á fi ọ̀kọ̀ lu ihò sí imú rẹ̀?
Job 40:15-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
“Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi Behemoti, tí mo dá pẹ̀lú rẹ, òun a máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù. Wò o nísinsin yìí, agbára rẹ wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ, àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ. Òun a máa jù ìrù rẹ̀ bí i igi kedari, iṣan itan rẹ̀ dìjọ pọ̀. Egungun rẹ̀ ní ògùṣọ̀ idẹ, Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin. Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run; síbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́. Nítòótọ́ òkè ńlá ńlá ní i mu ohun jíjẹ fún un wá, níbi tí gbogbo ẹranko igbó máa ṣiré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀. Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótusì, lábẹ́ eèsún àti ẹrẹ̀. Igi lótusì síji wọn bò o; igi arọrọ odò yí i káàkiri. Kíyèsi i, odò ńlá sàn jọjọ, òun kò sálọ; ó wà láìléwu bí ó bá ṣe pé odò Jordani ti ṣàn lọ sí ẹnu rẹ̀. Ẹnìkan ha lè mú un ní ojú rẹ̀, tàbí dẹkùn fún tàbí a máa fi ọ̀kọ̀ gún imú rẹ̀?