Job 4:1-8
Job 4:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni Elifasi, ara Tema, dahùn wipe, Bi awa ba fi ẹnu le e, lati ba ọ sọrọ, iwọ o ha binujẹ? ṣugbọn tali o le pa ọ̀rọ mọ ẹnu laisọ? Kiyesi i, iwọ sa ti kọ́ ọ̀pọ enia, iwọ sa ti mu ọwọ alailera le. Ọ̀rọ rẹ ti gbe awọn ti nṣubu lọ duro, iwọ si ti mu ẽkun awọn ti nwarirì lera. Ṣugbọn nisisiyi o de ba ọ, o si rẹ̀ ọ, o kọlu ọ, ara rẹ kò lelẹ̀. Ibẹru Ọlọrun rẹ kò ha jẹ igbẹkẹle rẹ? ati iduro ṣinṣin si ìwa ọ̀na rẹ kò ha si jẹ abá rẹ? Emi bẹ̀ ọ ranti, tali o ṣegbe ri laiṣẹ̀, tabi nibo li a gbe ké olododo kuro ri? Ani bi emi ti ri rí pe: awọn ti nṣe itulẹ ẹ̀ṣẹ, ti nwọn si fọ́n irugbin ìwa buburu, nwọn a si ká eso rẹ̀ na.
Job 4:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni Elifasi, ará Temani, dá Jobu lóhùn, ó ní: “Bí eniyan bá bá ọ sọ̀rọ̀, ṣé kò ní bí ọ ninu? Àbí eniyan ha lè dákẹ́ bí? O ti kọ́ ọpọlọpọ eniyan, o ti fún aláìlera lókun. O ti fi ọ̀rọ̀ gbé àwọn tí wọn ń ṣubú ró, ọ̀rọ̀ rẹ ti fún orúnkún tí ń yẹ̀ lọ lágbára. Ṣugbọn nisinsinyii tí ọ̀rọ̀ kàn ọ́, o kò ní sùúrù; Ó dé bá ọ, ìdààmú bá ọ. Ṣé ìbẹ̀rù Ọlọrun kò tó ìgboyà fún ọ? Àbí ìwà òdodo rẹ kò fún ọ ní ìrètí? “Ìwọ náà ronú wò, ṣé aláìṣẹ̀ kan ṣègbé rí? Tabi olódodo kan parun rí? Bí èmi ti rí i sí ni pé, ẹni tí ó kọ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ebè, tí ó sì gbin wahala, yóo kórè ìyọnu.
Job 4:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìgbà náà ni Elifasi, ará Temani dáhùn wí pé: “Bí àwa bá fi ẹnu lé e, láti bá ọ sọ̀rọ̀, ìwọ o ha banújẹ́? Ṣùgbọ́n ta ni ó lè pa ọ̀rọ̀ mọ́ ẹnu láìsọ? Kíyèsi i, ìwọ sá ti kọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn, ìwọ ṣá ti mú ọwọ́ aláìlera le. Ọ̀rọ̀ rẹ ti gbé àwọn tí ń ṣubú lọ dúró, ìwọ sì ti mú eékún àwọn tí ń wárìrì lera. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ó dé bá ọ, ó sì rẹ̀ ọ́, ó kọlù ọ́; ara rẹ kò lélẹ̀. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ kò ha jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ àti ìdúró ọ̀nà rẹ kò ha sì jẹ́ ìrètí rẹ? “Èmi bẹ̀ ọ́ rántí: Ta ni ó ṣègbé rí láìṣẹ̀? Tàbí níbo ni a gbé gé olódodo kúrò rí? Àní bí èmi ti rí i pé, àwọn tí ń ṣe ìtulẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n sì fún irúgbìn ìwà búburú, wọn a sì ká èso rẹ̀ náà.