Job 38:16-33

Job 38:16-33 Yoruba Bible (YCE)

“Ṣé o ti wọ orísun òkun lọ rí, tabi o ti rìn nísàlẹ̀ ibú rí? Ṣé a ti fi ìlẹ̀kùn ikú hàn ọ́ rí, tabi o ti rí ìlẹ̀kùn òkùnkùn biribiri rí? Ṣé o mọ̀ bí ayé ti tóbi tó? Dá mi lóhùn, bí o bá mọ àwọn nǹkan wọnyi. “Níbo ni ọ̀nà ilé ìmọ́lẹ̀, ibo sì ni ibùgbé òkùnkùn, tí o óo fi lè mú un lọ sí ààyè rẹ̀, tí o fi lè mọ ọ̀nà tí ó lọ sí ilé rẹ̀? Dájúdájú o mọ̀, nítorí pé wọ́n ti bí ọ nígbà náà, o sá ti dàgbà! “Ṣé o ti wọ àwọn ilé ìkẹ́rùsí, tí mò ń kó yìnyín pamọ́ sí rí, tabi ibi tí mò ń kó òjò dídì sí, àní, àwọn tí mo ti pamọ́ de àkókò ìyọnu, fún ọjọ́ ogun ati ọjọ́ ìjà? Ṣé o mọ ibi tí ìmọ́lẹ̀ ti ń tàn wá, tabi ibi tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ti ń fẹ́ wá sórí ayé? “Ta ló lànà fún ọ̀wààrà òjò, ati fún ààrá, láti rọ òjò sí orí ilẹ̀ níbi tí kò sí eniyan, ati ní aṣálẹ̀, níbi tí kò sí ẹnikẹ́ni? Láti tẹ́ aṣálẹ̀ lọ́rùn, ati láti mú kí ilẹ̀ hu koríko? Ṣé òjò ní baba; àbí, baba wo ló sì bí ìrì? Ìyá wo ló bí yìnyín, inú ta ni òjò dídì sì ti jáde? Ó sọ omi odò di líle bí òkúta, ojú ibú sì dì bíi yìnyín. “Ṣé o lè fokùn so ìràwọ̀ Pileiadesi, tabi kí o tú okùn ìràwọ̀ Orioni? Ṣé o lè darí àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀, ní àkókò wọn, tabi kí o ṣe atọ́nà ìràwọ̀ Beari ati àwọn ọmọ rẹ̀? Ṣé o mọ àwọn òfin tí ó de ojú ọ̀run? Tabi o lè fìdí wọn múlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé?

Job 38:16-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

“Ìwọ ha wọ inú ìsun òkun lọ rí bí? Ìwọ sì rìn lórí ìsàlẹ̀ ibú ńlá? A ha ṣílẹ̀kùn ikú sílẹ̀ fún ọ rí bí, ìwọ sì rí ìlẹ̀kùn òjìji òkú? Ìwọ mòye ìbú ayé bí? Sọ bí ìwọ bá mọ gbogbo èyí. “Ọ̀nà wo ni ìmọ́lẹ̀ ń gbé? Bí ó ṣe ti òkùnkùn, níbo ni ipò rẹ̀, tí ìwọ í fi mú un lọ sí ibi àlá rẹ̀, tí ìwọ ó sì le mọ ipa ọ̀nà lọ sínú ilé rẹ̀? Ìwọ mọ èyí, nítorí nígbà náà ni a bí ọ? Iye ọjọ́ rẹ sì pọ̀. “Ìwọ ha wọ inú ìṣúra ìdì òjò lọ rí bí, ìwọ sì rí ilé ìṣúra yìnyín rí, tí mo ti fi pamọ́ de ìgbà ìyọnu, dé ọjọ́ ogun àti ìjà? Ọ̀nà wo ni ó lọ sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ fi ń la, tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ń tàn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé? Ta ni ó la ipadò fún ẹ̀kún omi, àti ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá, láti mú u rọ̀jò sórí ayé níbi tí ènìyàn kò sí, ní aginjù níbi tí ènìyàn kò sí; láti mú ilẹ̀ tútù, ijù àti aláìro láti mú àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ewéko rú jáde? Òjò ha ní baba bí? Tàbí ta ni o bí ìkún ìṣe ìrì? Láti inú ta ni ìdì omi ti jáde wá? Ta ni ó bí ìrì dídì ọ̀run? Nígbà tí omi di líle bí òkúta, nígbà tí ojú ibú ńlá sì dìpọ̀. “Ìwọ ha le fi ọ̀já de àwọn ìràwọ̀ Pleiadesi dáradára? Tàbí ìwọ le tún di ìràwọ̀ Orioni? Ìwọ le mú àwọn àmì méjìlá ìràwọ̀ Masaroti jáde wá nígbà àkókò wọn? Tàbí ìwọ le ṣe amọ̀nà Beari pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀? Ǹjẹ́ ìwọ mọ ìlànà ọ̀run? Ìwọ le fi ìjọba Ọlọ́run lélẹ̀ lórí ayé?