Job 38:1-41
Job 38:1-41 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni OLUWA da Jobu lohùn lati inu ìji ajayika wá o si wipe, Tani eyi ti nfi ọ̀rọ aini igbiro ṣú ìmọ li òkunkun. Di ẹgbẹ ara rẹ li amure bi ọkunrin nisisiyi, nitoripe emi o bère lọwọ rẹ ki o si da mi lohùn. Nibo ni iwọ wà nigbati mo fi ipilẹ aiye sọlẹ? wi bi iwọ ba moye! Tali o fi ìwọn rẹ̀ lelẹ, bi iwọ ba mọ̀, tabi tani o ta okun wiwọn sori rẹ̀. Lori ibo ni a gbe kan ipilẹ rẹ̀ mọ́, tabi tali o fi okuta igun rẹ̀ le ilẹ? Nigbati awọn irawọ owurọ jumọ kọrin pọ̀, ti gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun nhó iho ayọ̀? Tabi tali o fi ilẹkun sé omi okun mọ́, nigbati o ya jade bi ẹnipe o ti inu tu jade wá? Nigbati mo fi awọsanma ṣe aṣọ rẹ̀, ati òkunkun ṣiṣu ṣe ọ̀ja igbanu rẹ̀? Ti mo ti paṣẹ ipinnu mi fun u, ti mo si ṣe bèbe ati ilẹkun. Ti mo si wipe, Nihinyi ni iwọ o dé, ki o má si rekọja, nihinyi si ni igberaga riru omi rẹ yio gbe duro mọ. Iwọ paṣẹ fun owurọ lati igba ọjọ rẹ̀ wá, iwọ si mu ila-õrun mọ̀ ipo rẹ̀? Ki o le idi opin ilẹ aiye mu, ki a le gbọ̀n awọn enia buburu kuro ninu rẹ̀. Ki o yipada bi amọ fun edidi amọ, ki gbogbo rẹ̀ ki o si fi ara rẹ̀ hàn bi ẹnipe ninu aṣọ igunwa. A si fa imọlẹ wọn sẹhin kuro lọdọ enia buburu, apa giga li o si ṣẹ́. Iwọ ha wọ inu isun okun lọ ri bi? iwọ si rin lori isalẹ ibú nla? A ha ṣilẹkun ikú silẹ fun ọ ri bi, iwọ si ri ilẹkun ojiji ikú? Iwọ̀ moye ibú aiye bi? sọ bi iwọ ba mọ̀ gbogbo rẹ̀? Ọ̀na wo ni imọlẹ igbé, bi o ṣe ti òkunkun, nibo ni ipò rẹ̀? Ti iwọ o fi mu u lọ si ibi àla rẹ̀, ti iwọ o si le imọ̀ ipa-ọ̀na lọ sinu ile rẹ̀? Iwọ mọ̀ eyi, nitoriti ni igbana ni a bi ọ? ati iye ọjọ rẹ si pọ! Iwọ ha wọ inu iṣura ojò-dídì lọ ri bí, iwọ si ri ile iṣura yinyin ri? Ti mo ti fi pamọ de igba iyọnu, de ọjọ ogun ati ijà. Ọ̀na wo ni imọlẹ fi nyà, ti afẹfẹ ila-orun tàn kakiri lori ilẹ aiye? Tali o la ipado fun ẹkún iṣan omi, ati ọ̀na fun manamana ãrá? Lati mu u rọ̀jo sori aiye, nibiti enia kò si, ni aginju nibiti enia kò si. Lati mu ilẹ tutù, ijù ati alairo, ati lati mu irudi ọmudún eweko ru jade? Ojo ha ni baba bi, tabi tali o bi ikán ìsẹ-iri? Lati inu tani ìdi omi ti jade wá, ati ìri didi ọrun tali o bi i? Omi bò o mọlẹ bi ẹnipe labẹ okuta, oju ibú nla si dìlupọ̀. Iwọ le ifi ọja de awọn irawọ meje [Pleyade] tabi iwọ le itudi irawọ Orionu? Iwọ le imu awọn ami mejejila irawọ [Masaroti] jade wá ni igba akoko wọn? tabi iwọ le iṣe àmọna Arketuru pẹlu awọn ọmọ rẹ̀? Iwọ mọ̀ ilana-ilana ọrun, iwọ le ifi ijọba rẹ̀ lelẹ li aiye? Iwọ le igbé ohùn rẹ soke de awọsanma, ki ọ̀pọlọpọ omi ki o le bò ọ? Iwọ le iran mànamána ki nwọn ki o le ilọ, ki nwọn ki o si wi fun ọ pe, Awa nĩ! Tali o fi ọgbọ́n si odo-inu, tabi tali o fi oye sinu aiya? Tali o fi ọgbọ́n ka iye awọsanma, tali o si mu igo ọrun dàjade. Nigbati erupẹ di lile, ati ogulutu dipọ̀? Iwọ o ha dẹ ọdẹ fun abo kiniun bi, iwọ o si tẹ́ ebi ẹgbọrọ kiniun lọrun? Nigbati nwọn ba mọlẹ ninu iho wọn, ti nwọn si ba ni ibuba de ohun ọdẹ. Tani npese ohun jijẹ fun ìwo? nigbati awọn ọmọ rẹ̀ nkepe Ọlọrun, nwọn a ma fò kiri nitori aili ohun jijẹ.
Job 38:1-41 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni OLUWA dá Jobu lóhùn láti inú ìjì líle. Ó bi í pé, “Ta ni ẹni tí ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìmọ̀ràn, tí ń sọ̀rọ̀ tí kò ní ìmọ̀? Nisinsinyii, múra gírí bí ọkunrin, mo ní ìbéèrè kan láti bí ọ, o óo sì dá mi lóhùn. Níbo lo wà, nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Bí o bá mọ ìgbà náà, sọ fún mi. Ta ló ṣe ìdíwọ̀n rẹ̀– ṣebí o mọ̀ ọ́n, dá mi lóhùn! Àbí ta ló ta okùn ìwọ̀n sórí rẹ̀? Orí kí ni a gbé ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé, àbí ta ló fi òkúta igun rẹ̀ sọlẹ̀; tí àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ ń jùmọ̀ kọrin, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọrun sì búsáyọ̀? Ta ló tìlẹ̀kùn mọ́ òkun, nígbà tí ó ń ru jáde, tí mo fi awọsanma ṣe ẹ̀wù rẹ̀, tí òkùnkùn biribiri sì jẹ́ ọ̀já ìgbànú rẹ̀, tí mo sì pa ààlà fún un, tí mo sé ìlẹ̀kùn mọ́ ọn, tí mo wí pé, ‘Dúró níhìn-ín, o kò gbọdọ̀ kọjá ibẹ̀, ibí ni ìgbì líle rẹ ti gbọdọ̀ dáwọ́ dúró?’ Jobu, láti ọjọ́ tí o ti dé ayé, ǹjẹ́ o ti pàṣẹ pé kí ilẹ̀ mọ́ rí, tabi pé kí àfẹ̀mọ́jú mọ́ àkókò rẹ̀, kí ìmọ́lẹ̀ lè tàn sí gbogbo ayé, kí ó sì lè gbọn àwọn ẹni ibi dànù, kúrò ní ibi ìsápamọ́sí wọn? A ti yí ayé pada bí amọ̀ tí a fi òǹtẹ̀ tẹ̀, ati bí aṣọ tí a pa láró. A mú ìmọ́lẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹni ibi, a sì ká wọn lápá kò. “Ṣé o ti wọ orísun òkun lọ rí, tabi o ti rìn nísàlẹ̀ ibú rí? Ṣé a ti fi ìlẹ̀kùn ikú hàn ọ́ rí, tabi o ti rí ìlẹ̀kùn òkùnkùn biribiri rí? Ṣé o mọ̀ bí ayé ti tóbi tó? Dá mi lóhùn, bí o bá mọ àwọn nǹkan wọnyi. “Níbo ni ọ̀nà ilé ìmọ́lẹ̀, ibo sì ni ibùgbé òkùnkùn, tí o óo fi lè mú un lọ sí ààyè rẹ̀, tí o fi lè mọ ọ̀nà tí ó lọ sí ilé rẹ̀? Dájúdájú o mọ̀, nítorí pé wọ́n ti bí ọ nígbà náà, o sá ti dàgbà! “Ṣé o ti wọ àwọn ilé ìkẹ́rùsí, tí mò ń kó yìnyín pamọ́ sí rí, tabi ibi tí mò ń kó òjò dídì sí, àní, àwọn tí mo ti pamọ́ de àkókò ìyọnu, fún ọjọ́ ogun ati ọjọ́ ìjà? Ṣé o mọ ibi tí ìmọ́lẹ̀ ti ń tàn wá, tabi ibi tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ti ń fẹ́ wá sórí ayé? “Ta ló lànà fún ọ̀wààrà òjò, ati fún ààrá, láti rọ òjò sí orí ilẹ̀ níbi tí kò sí eniyan, ati ní aṣálẹ̀, níbi tí kò sí ẹnikẹ́ni? Láti tẹ́ aṣálẹ̀ lọ́rùn, ati láti mú kí ilẹ̀ hu koríko? Ṣé òjò ní baba; àbí, baba wo ló sì bí ìrì? Ìyá wo ló bí yìnyín, inú ta ni òjò dídì sì ti jáde? Ó sọ omi odò di líle bí òkúta, ojú ibú sì dì bíi yìnyín. “Ṣé o lè fokùn so ìràwọ̀ Pileiadesi, tabi kí o tú okùn ìràwọ̀ Orioni? Ṣé o lè darí àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀, ní àkókò wọn, tabi kí o ṣe atọ́nà ìràwọ̀ Beari ati àwọn ọmọ rẹ̀? Ṣé o mọ àwọn òfin tí ó de ojú ọ̀run? Tabi o lè fìdí wọn múlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé? “Ǹjẹ́ o lè pàṣẹ fún ìkùukùu pé, kí ó rọ òjò lé ọ lórí? Ṣé o lè pe mànàmáná pé kí ó wá kí o rán an níṣẹ́ kí ó wá bá ọ kí ó wí pé, ‘Èmi nìyí?’ Ta ló fi ọgbọ́n sinu ìkùukùu ati ìmọ̀ sinu ìrì? Ta ló lè fi ọgbọ́n ká ìkùukùu, tabi tí ó lè tú omi inú ìkùukùu dà sílẹ̀, nígbà tí ilẹ̀ bá gbẹ, tóbẹ́ẹ̀ tí ó dì, tí ó sì le koko? “Ṣé o lè wá oúnjẹ fún kinniun, tabi kí o fi oúnjẹ tẹ́ àwọn ọ̀dọ́ kinniun lọ́rùn, nígbà tí wọ́n bá dùbúlẹ̀ ninu ihò wọn, tabi tí wọ́n ba ní ibùba wọn? Ta ní ń wá oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò, nígbà tí àwọn ọmọ wọn bá kígbe sí Ọlọrun, tí wọ́n sì ń káàkiri tí wọn ń wá oúnjẹ?
Job 38:1-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ní OLúWA dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé: “Ta ni èyí tí ń fi ọ̀rọ̀ àìlóye láti fi ṣókùnkùn bo ìmọ̀ mi? Di ẹ̀gbẹ́ ara rẹ ní àmùrè bí ọkùnrin nísinsin yìí, nítorí pé èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ kí o sì dá mi lóhùn. “Níbo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Wí bí ìwọ bá mòye. Ta ni ó fi ìwọ̀n rẹ lélẹ̀, dájú bí ìwọ bá mọ̀ ọ́n? Tàbí ta ni ó ta okùn wíwọ̀n sórí rẹ? Lórí ibo ni a gbé kan ìpìlẹ̀ rẹ̀ mọ́, tàbí ta ni ó fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀, Nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ kọrin pọ̀, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run hó ìhó ayọ̀? “Tàbí ta ni ó fi ìlẹ̀kùn sé omi Òkun mọ́, nígbà tí ó ya padà bí ẹni pé ó ti inú jáde wá, Nígbà tí mo fi àwọsánmọ̀ ṣe aṣọ rẹ̀, tí mo sì fi òkùnkùn biribiri ṣe ọ̀já ìgbà inú rẹ̀, Nígbà tí mo ti pàṣẹ ìpinnu mi fún un, tí mo sì ṣe bèbè àti ìlẹ̀kùn, Tí mo sì wí pé níhìn-ín ni ìwọ ó dé, kí o má sì rékọjá, níhìn-ín sì ni ìgbéraga rẹ yóò gbé dúró mọ? “Ìwọ pàṣẹ fún òwúrọ̀ láti ìgbà ọjọ́ rẹ̀ wá, ìwọ sì mú ìlà-oòrùn mọ ipò rẹ̀, Kí ó lè di òpin ilẹ̀ ayé mú, ki a lè gbọ́n àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú rẹ̀? Kí ó yí padà bí amọ̀ fún èdìdì amọ̀, kí gbogbo rẹ̀ kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni pé nínú aṣọ ìgúnwà. A sì fa ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn búburú, apá gíga ni a sì ṣẹ́. “Ìwọ ha wọ inú ìsun Òkun lọ rí bí? Ìwọ sì rìn lórí ìsàlẹ̀ ibú ńlá? A ha ṣílẹ̀kùn ikú sílẹ̀ fún ọ rí bí, ìwọ sì rí ìlẹ̀kùn òjìji òkú? Ìwọ mòye ìbú ayé bí? Sọ bí ìwọ bá mọ gbogbo èyí. “Ọ̀nà wo ni ìmọ́lẹ̀ ń gbé? Bí ó ṣe ti òkùnkùn, níbo ni ipò rẹ̀, Tí ìwọ í fi mú un lọ sí ibi àlá rẹ̀, tí ìwọ ó sì le mọ ipa ọ̀nà lọ sínú ilé rẹ̀? Ìwọ mọ èyí, nítorí nígbà náà ni a bí ọ? Iye ọjọ́ rẹ sì pọ̀. “Ìwọ ha wọ inú ìṣúra ìdì òjò lọ rí bí, ìwọ sì rí ilé ìṣúra yìnyín rí, Tí mo ti fi pamọ́ de ìgbà ìyọnu, dé ọjọ́ ogun àti ìjà? Ọ̀nà wo ni ó lọ sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ fi ń la, tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ń tàn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé? Ta ni ó la ipadò fún ẹ̀kún omi, àti ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá, láti mú u rọ̀jò sórí ayé níbi tí ènìyàn kò sí, ní aginjù níbi tí ènìyàn kò sí; láti mú ilẹ̀ tútù, ijù àti aláìro láti mú àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ewéko rú jáde? Òjò ha ní baba bí? Tàbí ta ni o bí ìkún ìṣe ìrì? Láti inú ta ni ìdì omi ti jáde wá? Ta ni ó bí ìrì dídì ọ̀run? Nígbà tí omi di líle bí òkúta, nígbà tí ojú ibú ńlá sì dìpọ̀. “Ìwọ ha le fi ọ̀já de àwọn ìràwọ̀ Pleiadesi dáradára? Tàbí ìwọ le tún di Ìràwọ̀ Orioni? Ìwọ le mú àwọn ààmì méjìlá ìràwọ̀ Masaroti jáde wá nígbà àkókò wọn? Tàbí ìwọ le ṣe amọ̀nà Beari pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀? Ǹjẹ́ ìwọ mọ ìlànà ọ̀run? Ìwọ le fi ìjọba Ọlọ́run lélẹ̀ lórí ayé? “Ìwọ le gbé ohùn rẹ sókè dé àwọsánmọ̀ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi kí ó lè bò ọ́? Ìwọ le rán mọ̀nàmọ́ná kí wọn kí ó le lọ, ní ọ̀nà wọn kí wọn kí ó sì wí fún wọn pé, ‘àwa nìyí’? Ta ni ó fi ọgbọ́n pamọ́ sí odò ikùn tàbí tí ó fi òye sínú àyà? Ta ni ó fi ọgbọ́n ka iye àwọsánmọ̀? Ta ni ó sì mú ìgò ọ̀run dà jáde, Nígbà tí erùpẹ̀ di líle, àti ògúlùtu dìpọ̀? “Ìwọ ha dẹ ọdẹ fún abo kìnnìún bí? Ìwọ ó sì tẹ ebi ẹgbọrọ kìnnìún lọ́rùn, Nígbà tí wọ́n bá mọ́lẹ̀ nínú ihò tí wọ́n sì ba ní ibùba de ohun ọdẹ? Ta ni ó ń pèsè ohun jíjẹ fún ẹyẹ ìwò, nígbà tí àwọn ọmọ rẹ ń ké pe Ọlọ́run, tí wọ́n sì máa ń fò kiri nítorí àìní ohun jíjẹ?