Job 36:1-15

Job 36:1-15 Yoruba Bible (YCE)

Elihu tún tẹ̀síwájú ninu ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní, “Ní sùúrù fún mi díẹ̀, n óo ṣe àlàyé fún ọ, nítorí mo ní ohun kan tí mo fẹ́ gbẹnusọ fún Ọlọrun. N óo gba ìmọ̀ mi láti ọ̀nà jíjìn, n óo sì fi júbà Ẹlẹ́dàá mi, tí ó ní ìmọ̀ òdodo. Nítorí òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ mi; ẹni tí ìmọ̀ rẹ̀ péye ni èmi tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí. “Ọlọrun lágbára, kì í kẹ́gàn ẹnikẹ́ni, agbára ati òye rẹ̀ pọ̀ gan-an. Kì í jẹ́ kí eniyan burúkú ó wà láàyè, ṣugbọn a máa fún ẹni tí ìyà ń jẹ ní ẹ̀tọ́ rẹ̀. Kìí mú ojú kúrò lára àwọn olódodo, ṣugbọn a máa gbé wọn sórí ìtẹ́ pẹlu àwọn ọba, á gbé wọn ga, á sì fi ìdí wọn múlẹ̀ títí lae. Ṣugbọn bí a bá fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè wọ́n, tí ayé wọn kún fún ìpọ́njú, a máa fi àṣìṣe wọn hàn wọ́n, ati ẹ̀ṣẹ̀ ìgbéraga wọn. Ó fún wọn ní etígbọ̀ọ́, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀. Bí wọ́n bá gbọ́ràn, tí wọ́n sì sìn ín, wọn yóo lo ọjọ́ ayé wọn pẹlu ìdẹ̀rùn, wọn yóo ṣe ọ̀pọ̀ ọdún ninu ìgbádùn. Ṣugbọn bí wọn kò bá gbọ́ràn, a óo fi idà pa wọ́n, wọn yóo sì kú láìní ìmọ̀. “Àwọn tí kò mọ Ọlọrun fẹ́ràn ibinu, wọn kì í kígbe fún ìrànlọ́wọ́, nígbà tí ó bá fi wọ́n sinu ìdè. Wọn á kú ikú ìtìjú, nígbà tí wọ́n wà ní èwe. A máa lo ìpọ́njú àwọn tí à ń pọ́n lójú láti gbà wọ́n là, a sì máa lo ìdààmú wọn láti ṣí wọn létí.

Job 36:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

Elihu sì tún sọ̀rọ̀ wí pé, “Fún mi láyè díẹ̀ èmi ó sì fihàn ọ́, nítorí ọ̀rọ̀ sísọ ní ó kún fún Ọlọ́run. Èmi ó mú ìmọ̀ mi ti ọ̀nà jíjìn wá, èmi ó sì fi òdodo fún Ẹlẹ́dàá mi. Rí i dájú pé ọ̀rọ̀ mi kì yóò ṣèké nítòótọ́; ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀. “Kíyèsi i, Ọlọ́run ni alágbára, òun kò i sì gàn ènìyàn; ó ní agbára ní ipá àti òye. Òun kì í dá ẹ̀mí ènìyàn búburú sí, ṣùgbọ́n ó fi òtítọ́ fún àwọn tálákà. Òun kì í mú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo, ṣùgbọ́n àwọn ọba ni wọ́n wà lórí ìtẹ́; àní ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé, a sì gbé wọn lékè. Bí ó bá sì dè wọ́n nínú àbà, tí a sì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n, nígbà náà ni ó ń sọ àwọn ohun tí wọn ti ṣe fún wọn, wí pé wọ́n ti ṣẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga wọn. Ó sí wọn létí pẹ̀lú sí ọ̀nà ẹ̀kọ́, ó sì pàṣẹ kí wọn kí ó padà kúrò nínú àìṣedédé. Bí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì sìn ín, wọn ó lo ọjọ́ wọn ní ìrọ̀rùn, àti ọdún wọn nínú afẹ́. Ṣùgbọ́n, bí wọn kò bá gbàgbọ́, wọ́n ó ti ọwọ́ idà ṣègbé, wọ́n á sì kú láìní òye. “Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní ayé kó ìbínú jọ; wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá wọ́n wí. Nígbà náà ni ọkàn wọn yóò kú ní èwe, ní àárín àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà. Òun gba òtòṣì nínú ìpọ́njú wọn, a sì sọ̀rọ̀ sí wọn ní etí nínú ìnira wọn.