Job 33:28-30
Job 33:28-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
O ti gba ọkàn mi kuro ninu ilọ sinu ihò, ẹmi mi yio si ri imọlẹ! Wò o! nkan wọnyi li Ọlọrun imaṣe fun enia nigba meji, ati nigba mẹta, Lati mu ọkàn rẹ̀ pada kuro ninu ihò, lati fi imọlẹ alãyè mọ́ si i.
Pín
Kà Job 33Job 33:28-30 Yoruba Bible (YCE)
Ó ti ra ọkàn mi pada kúrò lọ́wọ́ isà òkú, mo sì wà láàyè.’ “Wò ó, Ọlọrun a máa ṣe nǹkan wọnyi léraléra fún eniyan, lẹẹmeji tabi lẹẹmẹta, láti lè gba ọkàn rẹ̀ là lọ́wọ́ ikú, kí ó lè wà láàyè.
Pín
Kà Job 33Job 33:28-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run ti gba ọkàn mi kúrò nínú lílọ sínú ihò, ẹ̀mí mi yóò wà láti jẹ adùn ìmọ́lẹ̀ ayé.’ “Wò ó! Nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run máa ń ṣe fún ènìyàn nígbà méjì àti nígbà mẹ́ta, Láti mú ọkàn rẹ padà kúrò nínú isà òkú, láti fi ìmọ́lẹ̀ alààyè han sí i.
Pín
Kà Job 33