Job 33:1-7
Job 33:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ nitorina, Jobu, emi bẹ̀ ọ, gbọ́ ọ̀rọ mi, ki o si fetisi ọ̀rọ mi! Kiyesi i nisisiyi, emi ya ẹnu mi, ahọn mi si sọ̀rọ li ẹnu mi. Ọ̀rọ mi yio si jasi iduroṣinṣin ọkàn mi, ete mi yio si sọ ìmọ mi jade dajudaju. Ẹmi Ọlọrun li o ti da mi, ati imisi Olodumare li o ti fun mi ni ìye. Bi iwọ ba le da mi lohùn, tò ọ̀rọ rẹ lẹsẹsẹ niwaju mi, dide duro! Kiyesi i, bi iwọ jẹ ti Ọlọrun, bẹ̃li emi na; lati erupẹ wá ni a si ti dá mi pẹlu. Kiyesi i, ẹ̀ru nla mi kì yio bà ọ, bẹ̃li ọwọ mi kì yio wuwo si ọ lara.
Job 33:1-7 Yoruba Bible (YCE)
“Jobu, tẹ́tí sílẹ̀ nisinsinyii kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Wò ó! Mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ sì pọ̀ tí mo fẹ́ sọ. Òtítọ́ inú ni mo fi fẹ́ sọ̀rọ̀, ohun tí mo mọ̀ pé òdodo ni ni mo sì fẹ́ sọ. Ẹ̀mí Ọlọrun ni ó dá mi, èémí Olodumare ni ó sì fún mi ní ìyè. “Bí o bá lè dá mi lóhùn, dáhùn. Ro ohun tí o fẹ́ sọ dáradára, kí o sì múra láti wí àwíjàre. Wò ó, bákan náà ni èmi pẹlu rẹ rí lójú Ọlọrun, amọ̀ ni a fi mọ èmi náà. Má jẹ́ kí ẹ̀rù mi bà ọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní le kankan mọ́ ọ.
Job 33:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
“Ǹjẹ́ nítorí náà, Jobu, èmí bẹ̀ ọ, gbọ́ ọ̀rọ̀ mi kí o sì fetísí ọ̀rọ̀ mi! Kíyèsi i nísinsin yìí, èmí ya ẹnu mi, ahọ́n mi sì sọ̀rọ̀ ní ẹnu mi. Ọ̀rọ̀ mi yóò sì jásí ìdúró ṣinṣin ọkàn mi, ètè mi yóò sì sọ ìmọ̀ mi jáde dájúdájú. Ẹ̀mí Ọlọ́run ni ó tí dá mi, àti ìmísí Olódùmarè ni ó ti fún mi ní ìyè. Bí ìwọ bá le dá mi lóhùn, tò ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ níwájú mi; kíyèsi i, bí ìwọ ṣe jẹ́ ti Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà; láti amọ̀ wá ni a sì ti dá mi pẹ̀lú. Kíyèsi i, ẹ̀rù ńlá mi kì yóò bà ọ; bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi kì yóò wúwo sí ọ lára.