Job 30:1-15
Job 30:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
ṢUGBỌN nisisiyi awọn ti mo gbà li aburo nfi mi ṣẹ̀sin, baba ẹniti emi kẹgàn lati tò pẹlu awọn ajá agbo-ẹran mi. Pẹlupẹlu agbara ọwọ wọn kini o le igbè fun mi, awọn ẹniti kikún ọjọ wọn kò si. Nitori aini ati ìyan nwọn di ẹni itakete, nwọn si girijẹ ohun jijẹ iju, ti o wà ni isọdahoro ati òfo lati lailai. Awọn ẹniti njá ewe-iyọ li ẹ̀ba igbẹ, gbongbo igikigi li ohun jijẹ wọn. A le wọn jade kuro lãrin enia, nwọn si ho le wọn bi ẹnipe si olè. Lati gbé inu pàlapala okuta afonifoji, ninu iho ilẹ ati ti okuta. Ninu igbẹ ni nwọn ndún, nwọn ko ara wọn jọ pọ̀ labẹ ẹgun neteli. Awọn ọmọ ẹniti oye kò ye, ani ọmọ awọn enia lasan, a si le wọn kuro ninu ilẹ. Njẹ nisisiyi emi di ẹni-orin fun wọn, ani emi di ẹni-asọrọsi fun wọn. Nwọn korira mi, nwọn sa kuro jina si mi, nwọn kò si dá si lati tutọ́ si mi loju. Nitoriti Ọlọrun ti tu okun-ìye mi, o si pọn mi loju; awọn pẹlu si dẹ̀ ijanu niwaju mi. Awọn enia lasan dide li apa ọ̀tun mi, nwọn tì mi li ẹsẹ kuro, nwọn si là ipa-ọ̀na iparun silẹ dè mi. Nwọn dà ipa-ọ̀na mi rú, nwọn ran jàmba mi lọwọ, awọn ti kò li oluranlọwọ; Nwọn de si mi bi yiya omi gburu, ni ariwo nla ni nwọn ko ara wọn kátì si mi. Ẹ̀ru nla yipada bà mi, nwọn lepa ọkàn mi bi ẹfùfù, alafia mi si kọja lọ bi awọsanma.
Job 30:1-15 Yoruba Bible (YCE)
“Ṣugbọn nisinsinyii àwọn tí wọ́n kéré sí mi ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, àwọn tí baba wọn kò tó fi wé àwọn ajá tí ń ṣọ́ agbo ẹran mi. Kí ni anfaani agbára wọn fún mi, àwọn tí wọn kò lókun ninu? Ninu ìyà ati ebi, wọ́n ń jẹ gbòǹgbò igi gbígbẹ káàkiri lálẹ́ ninu aṣálẹ̀. Ewé igi inú igbó ni wọ́n ń já jẹ, àní, àwọn igi ọwọ̀ tí kò ládùn kankan. Wọ́n lé wọn jáde láàrin àwọn eniyan, wọ́n ń hó lé wọn lórí bí olè. Wọ́n níláti máa gbé ojú àgbàrá, ninu ihò ilẹ̀, ati ihò àpáta. Wọ́n ń dún bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ninu igbó, wọ́n ń kó ara wọn jọ sí abẹ́ igi ẹlẹ́gùn-ún. Àwọn aláìlóye ọmọ, àwọn ọmọ eniyan lásán, àwọn tí a ti nà kúrò lórí ilẹ̀ náà. “Nisinsinyii mo ti di orin lẹ́nu wọn, mo ti di àmúpòwe. Mo di ẹni ìríra lọ́dọ̀ wọn, wọ́n ń rí mi sá, ara kò tì wọ́n láti tutọ́ sí mi lójú. Nítorí Ọlọrun ti sọ mí di aláìlera, ó sì ti rẹ̀ mí sílẹ̀, wọn dojú ìjà kọ mí ninu ibinu wọn. Àwọn oníjàgídíjàgan dìde sí mi ní apá ọ̀tún mi, wọ́n lé mi kúrò, wọ́n sì la ọ̀nà ìparun sílẹ̀ fún mi. Wọ́n dínà mọ́ mi, wọ́n dá kún wahala mi, kò sì sí ẹni tí ó lè dá wọn lẹ́kun. Wọ́n jálù mí, bí ìgbà tí ọpọlọpọ ọmọ ogun bá gba ihò ara odi ìlú wọlé, wọ́n ya lù mí, wọ́n wó mi mọ́lẹ̀. Ìbẹ̀rù-bojo dé bá mi, wọ́n ń lépa ọlá mi bí afẹ́fẹ́, ọlà mi sì parẹ́ bí ìkùukùu.
Job 30:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, àwọn tí mo gbà ní àbúrò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà baba ẹni tí èmi kẹ́gàn láti tò pẹ̀lú àwọn ajá nínú agbo ẹran mi. Kí ni ìwúlò agbára ọwọ́ wọn sí mi, níwọ̀n ìgbà tí agbára wọn ti fi wọ́n sílẹ̀? Wọ́n rù nítorí àìní àti ìyàn wọ́n ń rìn káàkiri ní ilẹ̀ gbígbẹ ní ibi ìkọ̀sílẹ̀ ní òru. Àwọn ẹni tí ń já ewé iyọ̀ ní ẹ̀bá igbó; gbogbo igikígi ni oúnjẹ jíjẹ wọn. A lé wọn kúrò láàrín ènìyàn, àwọn ènìyàn sì pariwo lé wọn lórí bí ẹní pariwo lé olè lórí. A mú wọn gbe inú pàlàpálá òkúta Àfonífojì, nínú ihò ilẹ̀ àti ti òkúta. Wọ́n ń dún ní àárín igbó wọ́n kó ara wọn jọ pọ̀ ní abẹ́ ẹ̀gún neteli. Àwọn ọmọ ẹni tí òye kò yé, àní àwọn ọmọ lásán, a sì lé wọn jáde kúrò ní orí ilẹ̀. “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àwọn ọmọ wọn ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà nínú orin; àní èmi di ẹni ìṣọ̀rọ̀ sí láàrín wọn. Wọ́n kórìíra mi; wọ́n sá kúrò jìnnà sí mi, wọn kò sì bìkítà láti tutọ́ sí mi lójú. Nítorí Ọlọ́run ti tú okùn ìyè mi, ó sì pọ́n mi lójú; àwọn pẹ̀lú sì dẹ ìdẹ̀kùn níwájú mi. Àwọn ènìyàn lásán dìde ní apá ọ̀tún mi; wọ́n tì ẹsẹ̀ mi kúrò, wọ́n sì la ipa ọ̀nà ìparun sílẹ̀ dè mí. Wọ́n da ipa ọ̀nà mi rú; wọ́n sì sọ ìparun mi di púpọ̀, àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Wọ́n ya sí mi bí i omi tí ó ya gbuuru; ní ariwo ńlá ni wọ́n rọ́ wá. Ẹ̀rù ńlá bà mí; wọ́n lépa ọkàn mi bí ẹ̀fúùfù, àlàáfíà mi sì kọjá lọ bí àwọ̀ sánmọ̀.