Job 3:11-26

Job 3:11-26 Yoruba Bible (YCE)

“Kí ló dé tí n kò kú nígbà tí ìyá mi ń rọbí lọ́wọ́, tí ó fẹ́ bí mi, tabi kí n kú, lẹsẹkẹsẹ tí wọ́n bí mi? Kí ló dé tí ìyá mi gbé mi lẹ́sẹ̀? Kí ló dé tí ó fi fún mi lọ́mú? Ǹ bá ti dùbúlẹ̀, ǹ bá ti dákẹ́ jẹ́ẹ́; ǹ bá ti sùn, ǹ bá sì ti máa sinmi pẹlu àwọn ọba ati àwọn ìgbìmọ̀ àgbáyé, tí wọ́n ti sùn, àwọn tí wọ́n tún àlàpà kọ́ fún ara wọn; tabi pẹlu àwọn ọmọ aládé tí wọ́n ní wúrà, tí fadaka sì kún ilé wọn. Tabi kí n rí bí ọmọ tí a bí ní ọjọ́ àìpé, tí a bò mọ́lẹ̀ láì tíì lajú sáyé. Níbi tí àwọn oníṣẹ́ ibi kò ti lágbára mọ́, tí àwọn tí gbogbo nǹkan ti sú gbé ń sinmi. Níbẹ̀, àwọn ẹlẹ́wọ̀n ń gbé pọ̀ pẹlu ìrọ̀rùn, wọn kò sì gbọ́ ohùn akóniṣiṣẹ́ mọ́. Àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki jọ wà níbẹ̀, àwọn ẹrú sì bọ́ lọ́wọ́ oluwa wọn. “Kí ló dé tí a fi ìmọ́lẹ̀ fún ẹni tí ń kérora, tí a fi ẹ̀mí fún ẹni tí inú rẹ̀ bàjẹ́; tí ó ń wá ikú, ṣugbọn tí kò rí; tí ó ń wá ikú lójú mejeeji ju ẹni tí ń wá ìṣúra tí a fi pamọ́ lọ? Àwọn tí inú wọn ìbá dùn lọpọlọpọ bí wọ́n bá rí ẹni gbé wọn sin. Kí ló dé tí a fi fi ìmọ́lẹ̀ fún ẹni tí ọ̀nà dàrú mọ́ lójú; ẹni tí Ọlọrun ti tì sinu àhámọ́? Nítorí ìmí ẹ̀dùn di oúnjẹ fún mi, ìráhùn mi sì ń tú jáde bí omi. Ohun tí mo bẹ̀rù jù ti dé bá mi, ohun tí ń fò mí láyà ti ṣẹlẹ̀ sí mi. N kò ní alaafia, bẹ́ẹ̀ ni ara kò rọ̀ mí, n kò sì ní ìsinmi, àfi ìyọnu.”

Job 3:11-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Èéṣe tí èmi kò fi kú láti inú wá, tàbí tí èmi kò kú ní ìgbà tí mo ti inú jáde wá? Èéṣe tí orúnkún wá pàdé mi, tàbí ọmú tí èmi yóò mu? Ǹjẹ́ nísinsin yìí èmi ìbá ti dùbúlẹ̀ jẹ́ẹ́; èmi ìbá ti sùn, èmi ìbá ti sinmi pẹ̀lú àwọn ọba àti ìgbìmọ̀ ayé tí wọ́n mọ ilé fún ara wọn wá dùbúlẹ̀ nínú ìsọdahoro. Tàbí pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé tí ó ní wúrà, tí wọ́n sì fi fàdákà kun ilé wọn Tàbí bí ọlẹ̀ tí a sin, èmi kì bá ti sí: bí ọmọ ìṣunú tí kò rí ìmọ́lẹ̀? Níbẹ̀ ni ẹni búburú ṣíwọ́ ìyọnilẹ́nu, níbẹ̀ ni ẹni àárẹ̀ wà nínú ìsinmi. Níbẹ̀ ni àwọn ìgbèkùn sinmi pọ̀, wọn kò gbóhùn amúnisìn mọ́. Àti èwe àti àgbà wà níbẹ̀, ẹrú sì di òmìnira kúrò lọ́wọ́ olówó rẹ̀. “Nítorí kí ni a ṣe fi ìmọ́lẹ̀ fún òtòṣì, àti ìyè fún ọlọ́kàn kíkorò, tí wọ́n dúró de ikú, ṣùgbọ́n òun kò wá, tí wọ́n wá a jù ìṣúra tí a bò mọ́lẹ̀ pamọ́ lọ. Ẹni tí ó yọ̀ gidigidi, tí inú wọ́n sì dùn nígbà tí wọ́n wá ibojì òkú rí? Kí ni a fi ìmọ́lẹ̀ fún ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ fi ara pamọ́ fún, tí Ọlọ́run sì ṣọgbà dí mọ́ ká? Nítorí pé èémí-ẹ̀dùn wà ṣáájú oúnjẹ mi; ìkérora mi sì tú jáde bí omi. Nítorí pé ohun náà tí mo bẹ̀rù gidigidi ni ó dé bá mi yìí, àti ohun tí mo fòyà rẹ̀ bá mi ó sì ṣubú lù mí. Èmi wà láìní àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ní ìsinmi; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ni ìfàyàbalẹ̀, bí kò ṣe ìdààmú.”