Job 29:1-17

Job 29:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Jobu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ báyìí pé, “Ìbá jẹ́ tún rí fún mi, bí ìgbà àtijọ́, nígbà tí Ọlọrun ń tọ́jú mi; nígbà tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn sí mi lórí, tí mo kọjá ninu òkùnkùn pẹlu ìmọ́lẹ̀ rẹ̀; kí ó tún rí fún mi bí ìgbà tí ara dẹ̀ mí, nígbà tí ìrẹ́pọ̀ wà láàrin Ọlọrun ati ìdílé mi; tí Olodumare wà pẹlu mi, tí gbogbo àwọn ọmọ mi yí mi ká; tí mò ń rí ọpọlọpọ wàrà lára àwọn ẹran ọ̀sìn mi, ati ọpọlọpọ òróró lára igi olifi tí ń dàgbà láàrin òkúta! Nígbà tí mo lọ sí ẹnubodè ìlú, tí mo jókòó ní gbàgede, tí àwọn ọdọmọkunrin bá rí mi, wọn á bìlà sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, àwọn àgbà á sì dìde dúró; àwọn ìjòyè á dákẹ́ rọ́rọ́, wọn á fi ọwọ́ bo ẹnu wọn. Àwọn olórí á panumọ́, ahọ́n wọn á lẹ̀ mọ́ wọn lẹ́nu. Àwọn tí wọ́n gbọ́ nípa mi, ń pè mí ní ẹni ibukun, àwọn tí wọ́n rí mi ń kan sáárá sí mi. Nítorí pé mò ń ran àwọn aláìní tí ń ké lọ́wọ́, ati àwọn aláìníbaba tí wọn kò ní olùrànlọ́wọ́. Ìre àwọn tí ń kú lọ mọ́ mi, mo sì mú kí opó kọrin ayọ̀. Mo fi òdodo bora bí aṣọ, ìdájọ́ òtítọ́ dàbí ẹ̀wù ati adé mi. Mo jẹ́ ojú fún afọ́jú, ati ẹsẹ̀ fún arọ. Mo jẹ́ baba fún talaka, mo gba ẹjọ́ àlejò rò. Mo ṣẹ́ ẹni ibi lápá, mo gba ẹni tí ó mú sílẹ̀.

Job 29:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Pẹ̀lúpẹ̀lú, Jobu sì tún tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé: “Háà! ìbá ṣe pé èmi wà bí ìgbà oṣù tí ó kọjá, bí ọjọ́ tí Ọlọ́run pa mí mọ́; Nígbà tí fìtílà rẹ tàn sí mi ní orí, àti nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ èmi rìn nínú òkùnkùn já; Bí mo ti rí nígbà ọ̀dọ́ mi, nígbà tí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ bùkún ilé mi Nígbà tí Olódùmarè wà pẹ̀lú mi, nígbà tí àwọn ọmọ mi wà yí mi ká; Nígbà tí èmi fi òrí-àmọ́ n wẹ ìṣísẹ̀ mi, àti tí apata ń tú ìṣàn òróró jáde fún mi wá. “Nígbà tí mo jáde la àárín ìlú lọ sí ẹnu ibodè, nígbà tí mo tẹ́ ìtẹ́ mi ní ìgboro, Nígbà náà ni àwọn ọmọkùnrin rí mi, wọ́n sì sápamọ́, àwọn àgbà dìde dúró ní ẹsẹ̀ wọn; Àwọn ọmọ-aládé dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, wọn a sì fi ọwọ́ wọn lé ẹnu; Àwọn ọlọ́lá dákẹ́, ahọ́n wọn sì lẹ̀ mọ́ èrìgì ẹnu wọn. Nígbà tí etí gbọ́, ó sì súre fún mi, àti nígbà tí ojú sì rí mi, ó jẹ́rìí mi; Nítorí mo gbà tálákà tí n fẹ́ ìrànlọ́wọ́, àti aláìní baba tí kò sí olùrànlọ́wọ́ fún un Ẹni tí ó ń kìlọ̀ súre fún mi, èmi sì mú àyà opó kọrin fún ayọ̀. Èmi sì mú òdodo wọ̀ bí aṣọ, ẹ̀tọ́ mi dàbí aṣọ ìgúnwà àti adé ọba. Mo ṣe ojú fún afọ́jú mo sì ṣe ẹsẹ̀ fún amúnkùn ún. Mo ṣe baba fún tálákà, mo ṣe ìwádìí ọ̀ràn àjèjì tí èmi kò mọ̀ rí. Mo sì ká eyín ẹ̀rẹ̀kẹ́ ènìyàn búburú, mo sì já ohun ọdẹ náà kúrò ní eyín rẹ̀.