Job 27:11-23

Job 27:11-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Èmi ó kọ́ yín ní ẹ̀kọ́ ní ti ọwọ́ Ọlọ́run: ọ̀nà tí ń bẹ lọ́dọ̀ Olódùmarè ni èmi kì yóò fi pamọ́. Kíyèsi i, gbogbo yín ni ó ti rí i; kín ni ìdí ọ̀rọ̀ asán yín? “Ẹ̀yin ni ìpín ènìyàn búburú lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àti ogún àwọn aninilára, tí wọ́n ó gbà lọ́wọ́ Olódùmarè: Bí àwọn ọmọ rẹ bá di púpọ̀, fún idà ni; àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ kì yóò yó fún oúnjẹ. Àwọn tí ó kù nínú tirẹ̀ ni a ó sìnkú nínú àjàkálẹ̀-ààrùn: àwọn opó rẹ̀ kì yóò sì sọkún fún wọn. Bí ó tilẹ̀ kó fàdákà jọ bí erùpẹ̀, tí ó sì dá aṣọ jọ bí amọ̀; àwọn ohun tí ó tò jọ àwọn olóòtítọ́ ni yóò lò ó; àwọn aláìṣẹ̀ ni yóò sì pín fàdákà rẹ̀. Òun kọ́ ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí kòkòrò aṣọ, àti bí ahéré tí olùṣọ́ kọ́. Ọlọ́rọ̀ yóò dùbúlẹ̀, ṣùgbọ́n òun kì yóò túnṣe bẹ́ẹ̀ mọ́; Nígbà tí ó bá la ojú rẹ̀, gbogbo rẹ̀ a lọ Ẹ̀rù ńlá bà á bí omi ṣíṣàn; ẹ̀fúùfù ńlá jí gbé lọ ní òru. Ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn gbé e lọ, òun sì lọ; àti bí ìjì ńlá ó sì fà á kúrò ní ipò rẹ̀. Nítorí pé Olódùmarè yóò kọlù ú, kì yóò sì dá sí; òun ìbá yọ̀ láti sá kúrò ní ọwọ́ rẹ̀. Àwọn ènìyàn yóò sì ṣápẹ́ sí i lórí, wọn yóò sì ṣe síọ̀ sí i kúrò ní ipò rẹ̀.”