Job 27:1-10
Job 27:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
PẸLUPẸLU Jobu si tun sọ kún ọ̀rọ owe rẹ̀ o si wipe, Bi Ọlọrun ti mbẹ ẹniti o gba idajọ mi lọ, ati Olodumare ti o bà mi li ọkàn jẹ. Niwọn igba ti ẹmi mi mbẹ ninu mi, ati ti ẹmi Ọlọrun mbẹ ni iho imú mi. Ete mi kì yio sọ̀rọ eké, bẹ̃li ahọn mi kì yio sọ̀rọ ẹ̀tan. Ki a ma ri pe emi ndá nyin li are, titi emi o fi kú emi kì yio ṣi ìwa otitọ mi kuro lọdọ mi. Ododo mi li emi dimú ṣinṣin, emi kì yio si jọwọ rẹ̀ lọwọ; aiya mi kì yio si gan ọjọ kan ninu ọjọ aiye mi. Ki ọta mi ki o dàbi enia buburu, ati ẹniti ndide si mi ki o dàbi ẹni alaiṣododo. Nitoripe kini ireti àgabagebe, nigbati Ọlọrun ba ke ẹmi rẹ̀ kuro, nigbati o si fà a jade. Ọlọrun yio ha gbọ́ adura rẹ̀, nigbati ipọnju ba de si i? On ha le ni inu-didùn si Olodumare, on ha le ma kepe Ọlọrun nigbagbogbo?
Job 27:1-10 Yoruba Bible (YCE)
Jobu tún dáhùn pé, “Mo fi Ọlọrun tí ó gba ẹ̀tọ́ mi búra, mo fi Olodumare tí ó mú kí ọkàn mi bàjẹ́ ṣẹ̀rí, níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè, tí mo sì ń mí, n kò ní fi ẹnu mi purọ́, ahọ́n mi kò sì ní sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. Kí á má rí i, n kò jẹ́ pè yín ní olóòótọ́; títí di ọjọ́ ikú mi ni n óo dúró lórí ọ̀rọ̀ mi, pé mo wà lórí àre. Mo dúró lórí òdodo mi láìyẹsẹ̀, ọkàn mi kò ní dá mi lẹ́bi, títí n óo fi kú. “Kí ó rí fún ọ̀tá mi gẹ́gẹ́ bí í ti í rí fún ẹni ibi, kí ó sì rí fún ẹni tí ó dojú kọ mí bí í ti í rí fún alaiṣododo. Ìrètí wo ni ẹni tí kò mọ Ọlọrun ní nígbà tí Ọlọrun bá pa á run, tí Ọlọrun sì gba ẹ̀mí rẹ̀? Ǹjẹ́ Ọlọrun yóo gbọ́ igbe rẹ̀, nígbà tí ìyọnu bá dé bá a? Ǹjẹ́ yóo ní inú dídùn sí Olodumare? Ǹjẹ́ yóo máa ké pe Ọlọrun nígbà gbogbo?
Job 27:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Pẹ̀lúpẹ̀lú Jobu sì tún sọkún ọ̀rọ̀ òwe rẹ̀, ó sì wí pé: “Bí Ọlọ́run ti ń bẹ, ẹni tí ó gba ìdájọ́ mi lọ, àti Olódùmarè tí ó bà mi ní ọkàn jẹ́; (Níwọ́n ìgbà tí ẹ̀mí mi ń bẹ nínú mi, àti tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń bẹ nínú ihò imú mi.) Ètè mi kì yóò sọ̀rọ̀ èké, Bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n mi kì yóò sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. Kí a má rí i pé èmi ń dá yín láre; títí èmi ó fi kú, èmi kì yóò ṣí ìwà òtítọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi. Òdodo mi ni èmi dìímú ṣinṣin, èmi kì yóò sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́; àyà mi kì yóò sì gan ọjọ́ kan nínú ọjọ́ ayé mi. “Kí ọ̀tá mi kí ó dàbí ènìyàn búburú, àti ẹni tí ń dìde sí mi kí ó dàbí ẹni aláìṣòdodo. Nítorí kí ni ìrètí àgàbàgebè, nígbà tí Ọlọ́run bá ké ẹ̀mí rẹ̀ kúrò, nígbà tí ó sì fà á jáde? Ọlọ́run yóò ha gbọ́ àdúrà rẹ̀, nígbà tí ìpọ́njú bá dé sí i? Òun ha le ní inú dídùn sí Olódùmarè? Òun ha lé máa ké pe Ọlọ́run nígbà gbogbo?