Job 24:1-25
Job 24:1-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
ẼṢE bi igba-igba kò pamọ lọdọ Olodumare; ti awọn ojulumọ rẹ̀ kò ri ọjọ rẹ̀? Nwọn a ṣi àmi àla ilẹ, nwọn a fi agbara ko agbo ẹran lọ, nwọn si bọ́ wọn. Nwọn a si dà kẹtẹkẹtẹ alainibaba lọ, nwọn a si gba ọdá-malu opó li ohun ògo. Nwọn a bì alaini kuro loju ọ̀na, awọn talaka aiye a sa pamọ́ pọ̀. Kiyesi i, bi kẹtẹkẹtẹ igbẹ ninu ijù ni nwọn ijade lọ si iṣẹ wọn; nwọn a tete dide lati wá ohun ọdẹ; ijù pese onjẹ fun wọn ati fun awọn ọmọ wọn. Olukuluku a si ṣa ọka onjẹ-ẹran rẹ̀ ninu oko, nwọn a si ká ọgba-ajara enia buburu. Nihoho ni nwọn ma sùn laini aṣọ, ti nwọn kò ni ibora ninu otutu. Ọwara ojo oke-nla si pa wọn, nwọn si lẹ̀mọ apata nitoriti kò si abo. Nwọn ja ọmọ-alainibaba kuro li ẹnu-ọmu, nwọn si gbà ohun ẹ̀ri li ọwọ talaka. Nwọn rìn kiri nihoho laili aṣọ, awọn ti ebi npa rẹrù ìdi-ọka. Awọn ẹniti nfún ororo ninu agbala wọn, ti nwọn si ntẹ ifunti àjara, ongbẹ si ngbẹ wọn. Awọn enia nkerora lati ilu wá, ọkàn awọn ẹniti o gbọgbẹ kigbe soke; sibẹ Ọlọrun kò kiyesi iwère na. Awọn li o wà ninu awọn ti o kọ̀ imọlẹ, nwọn kò mọ̀ ipa ọ̀na rẹ̀, bẹni nwọn kò duro nipa ọ̀na rẹ̀. Panipani a dide li afẹmọ́jumọ pa talaka ati alaini, ati li oru a di olè. Oju àlagbere pẹlu duro de ofefe ọjọ, o ni, Oju ẹnikan kì yio ri mi, o si fi iboju boju rẹ̀. Li òkunkun nwọn a runlẹ wọle, ti nwọn ti fi oju sọ fun ara wọn li ọsan, nwọn kò mọ̀ imọlẹ. Nitoripe bi oru dudu ni owurọ̀ fun gbogbo wọn; nitoriti nwọn si mọ̀ ibẹru oru dudu. O yara lọ bi ẹni loju omi; ifibu ni ipin wọn li aiye, on kò rìn lọ mọ li ọ̀na ọgba-ajara. Ọdá ati õru ni imu omi ojo-didi gbẹ, bẹ̃ni isa-okú irun awọn ẹ̀lẹṣẹ. Inu ibímọ yio gbagbe rẹ̀, kokoro ni yio ma fi adun jẹun lara rẹ̀, a kì yio ranti rẹ̀ mọ́; bẹ̃ni a o si ṣẹ ìwa-buburu bi ẹni ṣẹ igi. Ẹniti o hù ìwa-buburu si agàn ti kò bí ri, ti kò ṣe rere si opó. O fi ipá rẹ̀ fà alagbara lọ pẹlu; o dide, kò si ẹniti ẹmi rẹ̀ da loju. On si fi ìwa ailewu fun u, ati ninu eyi ni a o si tì i lẹhin, oju rẹ̀ si wà ni ipa-ọna wọn. A gbe wọn lekè nigba diẹ, nwọn kọja lọ, a si rẹ̀ wọn silẹ, a si mu wọn kuro li ọ̀na, bi awọn ẹlomiran, a si ke wọn kuro bi ori ṣiri itú ọkà bàbà. Njẹ, bi kò ba ri bẹ̃ nisisiyi, tani yio mu mi li eké, ti yio si fi ọ̀rọ mi ṣe alainidi?
Job 24:1-25 Yoruba Bible (YCE)
“Kí ló dé tí Olodumare kò fi yan ọjọ́ ìdájọ́, kí àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́n sì rí ọjọ́ náà? “Àwọn eniyan a máa hú òkúta ààlà kúrò, láti gba ilẹ̀ ẹlòmíràn kún tiwọn, wọn a máa fi ipá sọ agbo ẹran ẹlòmíràn di tiwọn. Wọn a kó kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìníbaba lọ, wọn a gba akọ mààlúù opó gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò. Wọn a ti àwọn aláìní kúrò lójú ọ̀nà, gbogbo àwọn talaka a sì lọ sápamọ́. “Àwọn aláìní a máa ṣe làálàá káàkiri, bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú aṣálẹ̀, wọn a máa wá oúnjẹ fún àwọn ọmọ wọn ninu aṣálẹ̀. Wọn a máa kó oúnjẹ jọ fún ẹran wọn ninu oko olóko wọn a sì máa he èso àjàrà ní oko ìkà. Wọn a máa sùn ní ìhòòhò ní gbogbo òru, wọn kìí sìí rí aṣọ fi bora nígbà òtútù. Òjò a pa wọ́n lórí òkè, wọn a máa rọ̀ mọ́ àpáta nítorí àìsí ààbò. (Àwọn kan ń já àwọn ọmọ aláìníbaba gbà lẹ́nu ọmú, wọ́n sì ń gba ọmọ ọwọ́ lọ́wọ́ àwọn aláìní gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò.) Àwọn aláìní ń rìn kiri ní ìhòòhò láìrí aṣọ wọ̀; ebi ń pa wọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtí ọkà ni wọ́n rù. Wọ́n ń fún òróró lára èso olifi tí ó wà ní oko ìkà, òùngbẹ sì ń gbẹ wọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọtí ni wọ́n ń pọn. Àwọn tí wọn ń kú lọ ń kérora ní ìgboro, àwọn tí a pa lára ń ké fún ìrànlọ́wọ́, ṣugbọn Ọlọrun kò fetísí adura wọn. “A rí àwọn tí wọ́n kọ ìmọ́lẹ̀, tí wọn kò mọ ọ̀nà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró ní ọ̀nà náà. Bí ilẹ̀ bá ṣú, apànìyàn á dìde, kí ó lè pa talaka ati aláìní, a sì dàbí olè ní òru. Alágbèrè pàápàá ń ṣọ́ kí ilẹ̀ ṣú, ó ń wí pé, ‘Kò sí ẹni tí yóo rí mi’; ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀. Lóru, wọn á máa lọ fọ́ ilé kiri, ṣugbọn bí ilẹ̀ bá ti mọ́, wọn á ti ìlẹ̀kùn mọ́rí, wọn kì í rí ìmọ́lẹ̀. Àárọ̀ ni òkùnkùn biribiri jẹ́ fún gbogbo wọn, ọ̀rẹ́ wọn ni òkùnkùn biribiri tí ó bani lẹ́rù.” Sofari dáhùn pé, “O sọ wí pé, ‘Ìṣàn omi a máa gbá àwọn ẹni ibi lọ kíákíá; ìpín tiwọn a sì di ìfibú ninu ilẹ̀ náà, ẹnikẹ́ni kìí sì í lọ sinu ọgbà àjàrà wọn láti ṣiṣẹ́ mọ́. Bí ọ̀gbẹlẹ̀ ati ooru ṣe máa ń mú kí omi yìnyín gbẹ bẹ́ẹ̀ ni ibojì ṣe ń gbé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mì. Wọn á gbàgbé wọn láàrin ìlú, ẹnikẹ́ni kì í ranti orúkọ wọn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi ṣe é wó lulẹ̀ bí ìtì igi.’ Wọ́n ń jẹ oúnjẹ àgàn tí kò bímọ, wọn kò sì ṣe rere fún opó. Sibẹsibẹ Ọlọrun fi ẹ̀mí gígùn fún alágbára nípa agbára rẹ̀; wọn á gbéra nígbà tí ayé bá sú wọn. Ọlọrun ń dáàbò bò wọ́n, ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́, ó sì ń pa wọ́n mọ́ ni ọ̀nà wọn. A gbé wọn ga fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn náà, a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, wọn á rọ, wọn á sì rẹ̀ dànù bí ewé, a ké wọn kúrò bí orí ọkà bàbà. Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, kí ẹnìkan já mi nírọ́, kí ó sì fi hàn pé ìsọkúsọ ni mò ń sọ.”
Job 24:1-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ṣe bí ìgbà kò pamọ́ lọ́dọ̀ Olódùmarè fún ìdájọ́? Èéṣe tí ojúlùmọ̀ rẹ̀ kò fi rí ọjọ́ rẹ̀? Wọ́n a sún ààmì ààlà ilẹ̀, wọ́n á fi agbára kó agbo ẹran lọ, wọ́n a sì bọ́ wọn. Wọ́n á sì da kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìní baba lọ, wọ́n a sì gba ọ̀dá màlúù opó ní ohun ògo. Wọ́n á bi aláìní kúrò lójú ọ̀nà, àwọn tálákà ayé a fi agbára sápamọ́. Kíyèsi i, bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó nínú ijù ni àwọn tálákà jáde lọ sí iṣẹ́ wọn, wọ́n a tètè dìde láti wá ohun ọdẹ; ijù pèsè oúnjẹ fún wọn àti fún àwọn ọmọ wọn. Olúkúlùkù a sì sá ọkà oúnjẹ ẹran rẹ̀ nínú oko, wọn a sì ká ọgbà àjàrà ènìyàn búburú. Ní ìhòhò ni wọn máa sùn láìní aṣọ, tí wọn kò ní ìbora nínú òtútù. Ọ̀wààrà òjò òkè ńlá sì pa wọ́n, wọ́n sì lẹ̀ mọ́ àpáta nítorí tí kò sí ààbò. Wọ́n já ọmọ aláìní baba kúrò ní ẹnu ọmú, wọ́n sì gbà ọmọ tálákà nítorí gbèsè. Wọ́n rìn kiri ní ìhòhò láìní aṣọ; àwọn tí ebi ń pa rẹrù ìdì ọkà, Àwọn ẹni tí ń fún òróró nínú àgbàlá wọn, tí wọ́n sì ń tẹ ìfúntí àjàrà, síbẹ̀ òǹgbẹ sì ń gbẹ wọn. Àwọn ènìyàn ń kérora láti ìlú wá, ọkàn àwọn ẹni tí ó gbọgbẹ́ kígbe sókè fún ìrànlọ́wọ́ síbẹ̀ Ọlọ́run kò kíyèsi àṣìṣe náà. “Àwọn ni ó wà nínú àwọn tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀; Wọn kò mọ̀ ipa ọ̀nà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró nípa ọ̀nà rẹ̀. Apànìyàn a dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́, a sì pa tálákà àti aláìní, àti ní òru a di olè. Ojú alágbèrè pẹ̀lú dúró kí ilẹ̀ ṣú díẹ̀; ‘Ó ní, ojú ẹnìkan kì yóò rí mi,’ ó sì fi ìbòjú bojú rẹ̀. Ní òkùnkùn wọn á rúnlẹ̀ wọlé, tí wọ́n ti fi ojú sọ fún ara wọn ní ọ̀sán, wọn kò mọ̀ ìmọ́lẹ̀. Nítorí pé bí òru dúdú ní òwúrọ̀ fún gbogbo wọn; nítorí tí wọn sì mọ̀ ìbẹ̀rù òkùnkùn. “Ó yára lọ bí ẹni lójú omi; ìpín wọn ní ilé ayé ni a ó parun; òun kò rìn lọ mọ́ ní ọ̀nà ọgbà àjàrà. Gẹ́gẹ́ bi ọ̀dá àti òru ní í mú omi òjò-dídì yọ́, bẹ́ẹ̀ ní isà òkú í run àwọn tó dẹ́ṣẹ̀. Inú ìbímọ yóò gbàgbé rẹ̀, kòkòrò ní yóò máa fi adùn jẹun lára rẹ̀, a kì yóò rántí ènìyàn búburú mọ́; Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì ṣẹ ìwà búburú bí ẹní ṣẹ́ igi; Ẹni tí o hù ìwà búburú sí àgàn tí kò ṣe rere sí opó. Ọlọ́run fi ipá agbára rẹ̀ fa alágbára, bí wọ́n tilẹ̀ fìdímúlẹ̀, kò sí ìrètí ìyè fún wọn. Ọlọ́run sì fi àìléwu fún un, àti nínú èyí ni a ó sì tì i lẹ́yìn, ojú rẹ̀ sì wà ní ipa ọ̀nà wọn. A gbé wọn lékè nígbà díẹ̀, wọ́n kọjá lọ; a sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀; A sì mú wọn kúrò ní ọ̀nà bí àwọn ẹlòmíràn, a sì ké wọn kúrò bí orí síírí ọkà bàbà. “Ǹjẹ́, bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ nísinsin yìí, ta ni yóò mú mi ní èké, tí yóò sì sọ ọ̀rọ̀ mi di aláìníláárí?”