Job 23:8-12
Job 23:8-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Si wò! bi emi ba lọ si iha ila-õrùn, on kò si nibẹ, ati si iwọ-õrùn ni, emi kò si roye rẹ̀: Niha ariwa bi o ba ṣiṣẹ nibẹ, emi kò ri i, o fi ara rẹ̀ pamọ niha gusu, ti emi kò le ri i. Ṣugbọn on mọ̀ ọ̀na ti emi ntọ̀, nigbati o ba dan mi wò, emi o jade bi wura. Ẹsẹ mi ti tẹle ipasẹ irin rẹ, ọ̀na rẹ̀ ni mo ti kiyesi, ti nkò si yà kuro. Bẹ̃ni emi kò pada sẹhin kuro ninu ofin ẹnu rẹ̀, emi si pa ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ mọ́ jù ofin inu mi lọ.
Job 23:8-12 Yoruba Bible (YCE)
“Wò ó! Mo lọ siwaju, kò sí níbẹ̀, mo pada sẹ́yìn, n kò gbúròó rẹ̀. Mo wo apá ọ̀tún, n kò rí i, mo wo apá òsì, kò sí níbẹ̀. Ṣugbọn ó mọ gbogbo ọ̀nà mi, ìgbà tí ó bá dán mi wò tán, n óo yege bíi wúrà. Mò ń tẹ̀lé e lẹ́yìn, mo súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, n kò tíì yipada kúrò ní ọ̀nà rẹ̀. N kò tíì yapa kúrò ninu àṣẹ tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde, mò ń pa wọ́n mọ́ ninu ọkàn mi.
Job 23:8-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Sì wò ó, bí èmi bá lọ sí iwájú, òun kò sí níbẹ̀, àti sí ẹ̀yìn, èmi kò sì rí òye rẹ̀: Ni apá òsì bí ó bá ṣiṣẹ́ níbẹ̀, èmi kò rí i, ó fi ara rẹ̀ pamọ́ ni apá ọ̀tún, tí èmi kò le è rí i. Ṣùgbọ́n òun mọ ọ̀nà tí èmi ń tọ̀, nígbà tí ó bá dán mí wò, èmi yóò jáde bí wúrà. Ẹsẹ̀ mí ti tẹ̀lé ipasẹ̀ ìrìn rẹ̀; ọ̀nà rẹ̀ ni mo ti kíyèsi, tí ń kò sì yà kúrò. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò padà sẹ́yìn kúrò nínú òfin ẹnu rẹ̀, èmi sì pa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ mọ́ ju oúnjẹ òòjọ́ lọ.