Job 23:1-10
Job 23:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni Jobu si dahùn wipe, Ani loni ni ọ̀ran mi korò; ọwọ mi si wuwo si ikerora mi. A! emi iba mọ̀ ibi ti emi iba wá Ọlọrun ri! ki emi ki o tọ̀ ọ lọ si ibujoko rẹ̀, Emi iba si tò ọran na niwaju rẹ̀, ẹnu mi iba si kún fun aroye. Emi iba si mọ̀ ọ̀rọ ti on iba fi da mi lohùn, oye ohun ti iba wi a si ye mi. Yio ha fi agbara nla ba mi wijọ bi? agbẹdọ̀! kiki on o si kiyesi mi: Nibẹ li olododo le iba a wijọ, bẹ̃li emi o si bọ́ li ọwọ onidajọ mi lailai. Si wò! bi emi ba lọ si iha ila-õrùn, on kò si nibẹ, ati si iwọ-õrùn ni, emi kò si roye rẹ̀: Niha ariwa bi o ba ṣiṣẹ nibẹ, emi kò ri i, o fi ara rẹ̀ pamọ niha gusu, ti emi kò le ri i. Ṣugbọn on mọ̀ ọ̀na ti emi ntọ̀, nigbati o ba dan mi wò, emi o jade bi wura.
Job 23:1-10 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni Jobu dáhùn pé, “Lónìí, ìráhùn mi tún kún fún ẹ̀dùn, ọwọ́ Ọlọrun ń le lára mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mò ń kérora. Áà! Ìbá jẹ́ pé mo mọ ibi tí mo ti lè rí i ni, ǹ bá lọ siwaju ìtẹ́ rẹ̀! Ǹ bá ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ̀, gbogbo ẹnu ni ǹ bá fi ṣàròyé. Ǹ bá gbọ́ èsì tí yóo fún mi, ati ọ̀rọ̀ tí yóo sọ fún mi. Ṣé yóo gbéjà kò mí pẹlu agbára ńlá rẹ̀? Rárá o, yóo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi. Ibẹ̀ ni olódodo yóo ti lè sọ ti ẹnu rẹ̀, yóo sì dá mi sílẹ̀ títí lae. “Wò ó! Mo lọ siwaju, kò sí níbẹ̀, mo pada sẹ́yìn, n kò gbúròó rẹ̀. Mo wo apá ọ̀tún, n kò rí i, mo wo apá òsì, kò sí níbẹ̀. Ṣugbọn ó mọ gbogbo ọ̀nà mi, ìgbà tí ó bá dán mi wò tán, n óo yege bíi wúrà.
Job 23:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìgbà náà ni Jobu sì dáhùn wí pé: “Àní lónìí ni ọ̀ràn mi korò; ọwọ́ mí sì wúwo sí ìkérora mi. Háà! èmi ìbá mọ ibi tí èmí ìbá wá Ọlọ́run rí, kí èmí kí ó tọ̀ ọ́ lọ sí ibùgbé rẹ̀! Èmi ìbá sì to ọ̀ràn náà níwájú rẹ̀, ẹnu mi ìbá sì kún fún àròyé. Èmi ìbá sì mọ ọ̀rọ̀ tí òun ìbá fi dá mi lóhùn; òye ohun tí ìbáwí a sì yé mi. Yóò ha fi agbára ńlá bá mi wíjọ́ bí? Àgbẹdọ̀, kìkì pé òun yóò sì kíyèsi mi. Níbẹ̀ ni olódodo le è bá a wíjọ́, níwájú rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì bọ́ ni ọwọ́ onídàájọ́ mi láéláé. “Sì wò ó, bí èmi bá lọ sí iwájú, òun kò sí níbẹ̀, àti sí ẹ̀yìn, èmi kò sì rí òye rẹ̀: Ni apá òsì bí ó bá ṣiṣẹ́ níbẹ̀, èmi kò rí i, ó fi ara rẹ̀ pamọ́ ni apá ọ̀tún, tí èmi kò le è rí i. Ṣùgbọ́n òun mọ ọ̀nà tí èmi ń tọ̀, nígbà tí ó bá dán mí wò, èmi yóò jáde bí wúrà.